Afurasí tó máa ń jí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ nílé ìjọsìn kó sí gbaga ọlọ́pàá Ekiti

Sunday Abutu

Oríṣun àwòrán, Sunday Abutu

Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti tẹ ọkunrin kan to maa n ji ẹrọ ibanisọrọ ninu ṣọọṣi lasiko ijọsin.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin.

Abutu sọ pe ọwọ tẹ afurasri naa lẹyin to ti ji foonu meje ọtọtọ ninu ijọ Christ Apostolic Church kan niluu Ayegbaju-Ekiti.

Ọlọpaa ni “afurasi naa lọ sile ijọsin ọhun, o dibọn bii ọkan lara awọn olujọsin lati ṣọ awọn olujọsin naa daadaa ko to ji foonu meje lasiko ti wọn n kọ orin iyin.

“Afurasi ọhun jẹwọ ninu ifọrọwanilẹnuwo pe o ti ṣe diẹ ti oun ti n ṣọṣẹ lagbegbe Oye ati Ayegbaju-Ekiti, ile ijọsin si loun maa kọlu.

“O jẹwọ siwaju si pe oun ti ji ọpọlọpọ ẹrọ ibanisọrọ nile ijọsin Redeemed Christian Church of God ati New Reality Christian Center, niluu Oye-Ekiti yii kan naa.”

Iwadii ọlọpaa fi han pe ilu Eko ni afurasi naa maa n fi awọn ẹrọ ilewọ to ba ji ranṣẹ si nibi ti ọrẹ rẹ kan yoo ti lu awọn foonu naa ni gbanjo, ti yoo si fi owo rẹ ranṣẹ pada si lori ayelujara.

Ẹwẹ, ọlọpaa ti gba awọn foonu meje to ji gbẹyin lọwọ rẹ, wọn si ti kesi awọn to ni awọn foonu naa ki wọn wa gba a.

Abutu pari atẹjade rẹ pe afurasi naa yoo foju bale ẹjọ laipẹ lẹyin ti wọn ba ti pari iwadii lori ẹsin ti wọn fi kan an.