Ìjọba fáwọn olùgbé ilé àkọ́patì Ikoyi Tower l'Eko lọ́jọ́ méjì láti kúrò níbẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ̀ọ́...

Aworan Ikoyi Tower

Oríṣun àwòrán, Tokunbo/Wahab/X

Ijọba ipinlẹ Eko ti fun gbogbo awọn to n gbe ninu ile akọpati Ikoyi Tower ni gbedeke ọjọ meji lati kuro nibẹ.

Kọmiṣọna fọrọ eto ayika ati ọrọ omi nipinlẹ naa, Tokunbọ Wahab lo sọ eyi di mimọ lasiko to ṣe abẹwo si agbegbe naa, nibi ti awọn eeyan n sun si lai gba aṣẹ.

Ọpọ awọn eeyan to wa nipinlẹ Eko, ṣugbọn ti wọn ko ni ibi ti wọn ko ni ile la a gbọ pe wọn n gbe lawọn ile ati ileeṣẹ ijọba ti wọn ti pa ti tipẹ, to fi mọ abẹ afara kaakiri.

Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni ijọba ipinlẹ Eko ṣawari yara mẹrindinlaadọrun ti awọn kan sọ di ile wọn labẹ afara Osborne to wa ni Ikoyi, nibi ti wọn ti n san obitibiti owo lọdọọdun.

Wahab ṣalaye loju opo ayelujara X rẹ pe awọn tun lọ ṣayẹwo boya awọn ti wọn le kuro ni abẹ afara Osborne naa ko pada sibẹ, lẹyin ti wọn ti ko gbogbo ẹru wọn kuro nibẹ.

O ni awọn ko kofiri wi pe awọn eeyan naa tun pada sibẹ lati maa gbe.

Siwaju sii lo ni awọn tẹsiwaju lọ si ileeṣẹ ijọba ti Ikoyi Tower, eyi ti ijọba ti pati fun igba diẹ, lati mọ ohun to n ṣẹlẹ, to si lo jẹ iyalẹnu wi pe ọpọ awọn eeyan lo ti sọ ibẹ si ile wọn.

Eyi lo sọ pe o n ṣe akoba fun eto aabo ipinlẹ Eko, ati pe niṣe ni wọn n da iwa itiju ati iwa ibajẹ silẹ nipinlẹ Eko.

Wahab fi kun ọrọ rẹ pe ọpọ eeyan ti wọn ko le ṣe akọsilẹ wọn tan, ṣugbọn to ni wọn le ni ọgọrun-un kan ni wọn n gbe ni Ikoyi Tower yii, eyi to ni ko bojumu rara.

“A ti fun wọn ni gbedeke wakati mejidinlaadọta lati kuro ni agbegbe naa.” Wọnyi lohun ti Wahab sọ.

Sibẹ, o tun jẹ ko di mimọ pe awọn tun ṣakiyesi adagun omi kan ninu koto to wa lagbegbe Ebutte Ẹlẹfun – Adeniji Adele ni Lagos Island.

O sọ siwaju pe awọn tun ri awọn to kọ ile ati ṣọọbu sibi ti ko tọ, to si ni wọn tun n yọ bulọọku nibẹ lati fi ṣiṣẹ aje lara fẹnsi ile-ẹkọ girama ti Ebutte Ẹlẹfun.

Ni afikun, o ni awọn ti paṣẹ fun gbogbo awọn to n ṣiṣẹ aje yii lati kuro nibẹ, nitori pe ibi ti ko tọna ni.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post