Àǹfàní wo ní fún aráàlú, bí Nàìjíríà bá dín iná mọ̀nàmọ́ná tó ń pèsè fáwọn orílẹ̀èdè mìíràn kù?

Awon waya ina

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ iná ní Nàìjíríà ìyẹn Nigerian Electricity Regulatory Commission, NERC ti pàṣẹ fún àwọn iléeṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná láti mú àdínkù bá iye iná tí Nàìjíríà ń fún àwọn orílẹ̀ èdè tó yi ká kù.

Láti ìgbà náà ni àwọn ènìyàn ti ń bèèrè pé ṣé ìgbésẹ̀ yìí yóò mú àlékún bá ìpèsè iná mọ̀nàmọ́ná fún àwọn ọmọ Nàìjíríà?

Nàìjíríà ń fún orílẹ̀ èdè Niger, Togo àti Benin ní iná mọ̀nàmọ́ná èyí tí NERC sọ pé ó ti pọ̀jù ju iye iná tó yẹ kí wọ́n máa fún orílẹ̀ èdè mìíràn.

NERC ní láti ọjọ́ Kìíní, oṣù Karùn-ún títí di oṣù Kẹwàá ọdún 2024, ìdá mẹ́fà nínú ìdá ọgọ́rùn-ún iná mọ̀nàmọ́ná tí àwọn iléeṣẹ́ náà ń pèsè ni kí wọ́n máa fún àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.

Ìgbésẹ̀ náà yóò mú àlékún bá ìpèsè iná mọ̀nàmọ́ná fún àwọn ènìyàn

Onímọ̀ nípa iná mọ̀nàmọ́ná ní Nàìjíríà, Sharfudeen Zubair Mahmoud ní ìgbésẹ̀ NERC láti mú àdínkù ba iye iná tí wọ́n ń fún àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà yóò mú àlékún bá iye iná tí àwọn ọmọ Nàìjíríà yóò máa rí lò.

Ó ní iye iná mọ̀nàmọ́ná tí Nàìjíríà ń fún àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà tẹ́lẹ̀ pọ̀ ju iye iná mọ̀nàmọ́ná tí Nàìjíríà ń rí lò tẹ́lẹ̀ lọ.

Ó ṣàlàyé pé bí àdínkù kò bá bá iye iná mọ̀nàmọ́ná tí Nàìjíríà ń fún àwọn orílẹ̀ èdè yìí, àwọn ọmọ Nàìjíríà náà ni yóò jìyà rẹ̀.

Sharfudeen ní kò dára bí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣe ń san owó ribiribi fún iná, tí wọ́n sì ń jìyà iná àmọ́ tí àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ń fún ní iná mọ̀nàmọ́ná ṣe ń gbádùn rẹ̀ jù wọ́n lọ.

Ó ní wọ́n gbọ́dọ̀ mú àdínkù bá iye iná tí wọ́n ń fún àwọn orílẹ̀ èdè náà kí Nàìjíríà fi gbádùn iná fún oṣù mẹ́fà.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ní láti ìgbà tí NERC ri kéde ìgbésẹ̀ tuntun wọn yìí ni àlékún ti bá iye wákàtí tí àwọn fi ń lo iná lójúmọ́.

Olùgbé ìlú Kano kan tó bá ikọ̀ ìròyìn BBC News Hausa sọ̀rọ̀ ní àyípadà ti wà lórí iye wákàtí tí àwọn fi ń ní iná mọ̀nàmọ́ná láti ọjọ́ Àbámẹ́ta àmọ́ òun kò mọ̀ bóyá ìgbésẹ̀ tuntun NERC yìí ló fà á.

Àwọn ìròyìn kan sọ pé láti ìgbà tí NERC ti pàṣẹ yìí, mẹ́gáwáàtì iná tí Nàìjíríà ń pèsè ti lékún láti 3,000 sí 4,700.

Kí ni ìdí tí Nàìjíríà fi dín iná mọ̀nàmọ́ná tó ń fún Togo, Niger àti Benin ku?

Oriko ipese ina

Oríṣun àwòrán, TCN

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Sharfudeen Zubair Mahmoud ní ìdí pàtàkì kan gbòógì tí Nàìjíríà fi pàṣẹ láti mú àdínkù ba iye iná tó ń fún àwọn orílẹ̀ èdè tó múlé tì í yìí kò ṣẹ̀yìn bí ijoba ṣe yọ ìrànwọ́ orí iná mọ̀nàmọ́ná.

Ó ní pẹ̀lú bí ìjọba ṣe ti yọ ìrànwọ́ orí iná mọ̀nàmọ́ná, ó túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn yóò máa san owó tó pọ̀ jù ti tẹ́lẹ̀ lọ fún iná ọba.

Ó ní àwọn iléeṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná gbọ́dọ̀ ri pé àwọn èèyàn ń jẹ ìgbádùn owó iná tí wọ́n ń san pẹ̀lú àlékún yìí.

Onímọ̀ yìí wòye pé ó pọn dandan fún àwọn iléeṣẹ́ tó ń pín iná láti ṣe àrídájú rẹ̀ pé àwọn oníbàárà jẹ àǹfàní owó tí wọ́n ń san àti pé èyí ló fà ìgbésẹ̀ NERC láti lé kún iná tí wọ́n ń fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Bákan náà ló wòye pé ooru àmújù tó ń bá gbogbo àgbáyé fínra lásìkò yìí ti jẹ́ kó pọn dandan fún àwọn iléeṣẹ́ tó ń pín iná náà láti túnbọ̀ mú àlékún bá iná tí wọ́n ń fún àwọn ènìyàn.

Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé nígbà tí oṣù mẹ́fà tí wọ́n fún àwọn orílẹ̀ èdè yìí bá máa fi pé, wọn yóò ti ṣe àgbéyẹ̀wò òfin tó de bí Nàìjíríà ṣe ń fún àwọn orílẹ̀ èdè náà ní iná láti ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ si.

Ipa wo ni àdínkù náà yóò mú bá àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí?

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpalára ni ìgbésẹ̀ Nàìjíríà yìí yóò mú bá àwọn orílẹ̀ èdè Togo, Niger àti Benin pàápàá lórí ìgbáyégbádùn wọn.

Bákan náà ni ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ni àwọn orílẹ̀ èdè náà yóò ní ìpalára.

Bí àpẹẹrẹ, ìdá àádọ́rin ọ̀pọ̀ ìlú ni kò ní iná mọ̀nàmọ́ná, tí wọ́n wà ní òkùnkùn birimù ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Benin nígbà tí àjọ ECOWAS fòfin dè wọ́n, tí Nàìjíríà kò fún wọn ní iná.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Nàìjíríà yóò máa fún wọn ní iná ìdá mẹ́fà, tí àwọn orílẹ̀ èdè náà sì ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti máa pèsè iná fúnra wọn, síbẹ̀, àwọn onímọ̀ ní ìpinnu Nàìjíríà yóò ní ipa tí kò dára lórí wọn.

Sharfudeen Zubair Mahmoud ní ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ni ipa náà yóò kan àmọ́ ó yẹ kí NERC ṣe àmójútó orílẹ̀ èdè tirẹ̀ náà ló fa ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé.

Àdéhùn láàárín Nàìjíríà àtàwọn orílẹ̀ èdè tó súnmọ lórí ìpèsè iná

Oriko ipese ina

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ṣe fi hàn, ní nǹkan bíi ọdún 1970 ni Nàìjíríà tọwọ́bọ àdéhùn pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè Niger, Togo àti Benin pé kí wọ́n má kọ̀ ọ́ omi adágún láti fi pèsè iná mọ̀nàmọ́ná nítorí à ti fi ààyè gba odò River Niger láti máa ibẹ̀ kọjá bó ṣe yẹ.

Ní ọdún 2020 ni ìjọba Buhari ṣe àtúngbéyẹ̀wò àdéhùn náà lójúnà àti dá ààbò bo àwọn iléeṣẹ́ iná Kainji, Shiroro àti Jebba.

Èyí ni kò jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè yìí lè máa pèsè iná fúnra wọn pẹ̀lú àdéhùn pé Nàìjíríà yóò máa fún wọn ní iná, tí wọn yóò sì máa fún wọn ní owó

Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Nàìjíríà tí ń kọminú lórí iye tí wọ́n jẹ àwọn orílẹ̀ èdè yìí látàrí pé àwọn èèyàn kò san owó iná.

Ní ọdún 2020, Mínísítà fọ́rọ̀ iná nígbà náà, Babatunde Fashola ní owó tí Nàìjíríà jẹ àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn lé ní $64,000.