Àwọn agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́ fásitì mẹ́sàn án gbé ní Kogi

Oríṣun àwòrán, confluence university of science and technology
Awọn agbebọn kan ti ji akẹkọọ mẹsan an gbe ni ipinlẹ Kogi.
Ijọba ipinlẹ Kogi ti fi idi ijinigbe naa mulẹ to si ni awọ akẹkọọ fasiti kan ni ipinlẹ naa lawọn ti wọn ji gbe.
Amọṣa awọn onwoye n sọ wi pe o ṣeeṣe ki iye awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe ju mẹsan lọ.
Iroyin sọ pe awọn agbebọn naa ya wọ fasiti imọ ẹrọ Confluence University of Science and Technology to wa ni Osara- Okene ni nnkan bii aajin oru ọjọbọ.
Lẹyin ti wọn de fasiti naa, ni wọn bẹrẹ si nii wọ yara awọn akẹkọọ naa lẹyọ kọọkan ti wọn si n yinbọn soke ni kikankikan.
Iroyin sọ peawọn akẹkọọ ile ẹkọ giga fasiti naa n gbaradi fun idanwo lọwọ lasiko ti awọn ajinigbe naa fi de loru.
“Ẹgbẹlẹgbẹ awọn oninuure ti wọn mọ awọn igbo to wa lagbegbe naa bi ẹyinkule ọwọ wọn ni wọn ti kun awọn agbofinro lọwọ lati ṣawari awọn akẹkọọ naa.” Gẹgẹ bi atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ naa, Kingsley Fanwo fi sita ṣe sọ.
Bi a ko ba ni gbagbe o, ijọba ipinlẹ Kaduna ṣẹṣẹ kede ni pe awọn fẹ ko awọn akẹkọọ bi ọọdunrun lọ si ile ẹkọ miran nitori idunkuku awọn agbebọn ni ipinlẹ naa nibi ti awọn ajinigbe ti ji ọpọlọpọ akẹkọọ lawọn akoko kan sẹyin














