Abdullahi ọmọ ọdún 16 bẹ́ orí ọmọ ọdún mẹ́fà ní Kano

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Kano ti bẹrẹ iwadii lati tan imọlẹ si iku ọdọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹfa kan, Mohammed Saidu, ti iroyin ni ọkunrin Almajiri kan bẹ lori ni agbegbe Kanwa, nijọba ibilẹ Madobi.
Kọmisana ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kano, Usaini Gumel sọ fun ileeṣe iroyin News Agency of Nigeria pe ọmọ ọdun mẹrindinlogun, ti orukọ rẹ n jẹ Abdullahi, lo ṣekupa Saidu, ọmọ ọdun mẹfa, to si tun bẹ lori.
Gumel tẹsiwaju pe lati Zamfara ni Abdullahi ti wa, ti wọn si sadede ri ni abule Kanwa pẹlu ọbẹ to ni ẹjẹ lara lọwọ rẹ.
Ẹjẹ naa ni ọlọpaa furasi pe o jẹ ti eeyan.
Ọlọpaa tun fi di rẹ mulẹ pe awọn ṣawari ori oloogbe naa ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ kan to wa ni itosi lẹyin ọpọ iwadi.
O ni wọn mu afurasi naa lọ si ile olori ilu ti iṣẹlẹ ọhun ti waye lati dena de bi awọn araalu ṣe yabo afurasi naa lati ṣekupa a.
Sugbọn sibẹsibẹ, awọn araalu to n binu yawọ ile olori ilu, ti wọn si fi ọpọ iya jẹ afurasi naa.
Kọmiṣọna ọlọpaa naa ni “Nigba ti Ọlọpaa de, afurasi naa jẹwọ pe oun mọ nipa isẹlẹ naa, to si ni oun ju ori ọmọ naa sinu salanga kan to kọju si ile alakọbẹrẹ kan.”
Gumel ni ileeṣẹ ọlọpaa gbe afurasi naa lọ si Ile iwosan Kwankwaso Cottage fun itọju sugbọn o padanu ẹmi rẹ lasiko to n gba itọju lọwọ.
Wọn ti a gbe oku oloogbe naa lọ si ile iwosan fun ayẹwo sugbọn wọn pada gbe oku naa fun awọn mọlẹbi rẹ lati ṣe eto isinku.















