Wo ipa tí bí ikọ̀ Super Eagles ṣe kọ̀ láti gbáradì fún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn ọ́la, yóò ní lórí àṣèyọrí wọn

Oríṣun àwòrán, Sina Okeleji
Awọn agbabọọlu Super Eagles ti kọ lati ṣe igbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ wọn ti yoo waye pẹlu orilẹede Garbon lọla Ọjọbọ.
Ifẹsẹwọnṣe naa ṣe pataki fun Super Eagles nitori o le sọ boya wọn ṣi le kopa ninu idije ife ẹye agbaye 2026 World Cup.
A gbọ pe Aarẹ NFF ti balẹ si Morocco ti Super Eagles wa, o si ti ṣe ipade pẹlu awọn agbabọọlu naa, to fi mọ awọn oṣiṣẹ ikọ ọhun miran.
Wayi o, kii ṣe igba akọkọ ree ti ikọ Super Eagles yoo kọ lati kopa ninu igbaradi wọn latari idi kan tabi omiran.
Iwọnyii ni idi pataki ti ikọ Super Eagles fi kọ lati ṣe igbaradi fun ọkan lara awọn ifẹsẹwọnsẹ rẹ to ṣe pataki lasiko yii.
Eredi ti ikọ Super Eagles ṣe kọ lati kopa ninu igbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Gabon
Idi pataki ti awọn agbabọọlu Super Eagle ṣe gbe igbesẹ naa ko ṣẹyin awọn ajẹmọnu kan to yẹ ki NFF ti san fun wọn amọ to kuna lati san.
Iroyin ni awọn ajẹmọnun naa lo yẹ ki wọn gba fun kikopa ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ igbaradi AFCON 2025 ati 2026 World Cup.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ẹgbẹrun marundinlogun dọla lawọn agbabọọlu naa bere fun ifẹsẹwọnṣe meji to wa niwaju wọn, ti apapọ owo to yẹ ki wọn gba jẹ ẹgbẹrun lọna ọgbọn dọla amọ NFF ni ẹgbẹrun mẹwaa dọla pere loun yoo fun wọn, eyii ti ko tẹ wọn lọrun.
A tilẹ gbọ pe awọn oṣiṣe NFF kan sọ pe ẹgbẹrun marun dọla pere ti to wọn, to tunbọ fẹ rogbodiyan naa loju si.
Awọn agbabọọlu ọhun sọ pe awọn ko ni ṣe igbaradi kankan ayafi ti ajọ NFF ba yanju ọrọ ajẹmọnu naa.
Ẹnikan to ba awọn akọroyin sọrọ amọ ti ko fẹ fi orukọ ara rẹ lede ni awọn agbabọọlu naa sọ pe ijọba Cameroon, DR Congo, ati Gabon ti fikun ajẹmọnu awọn agbabọọlu wọn ti wọn ba bori ifẹwọnsẹ, Naijiria nikan ni ko tii ṣe afikun tirẹ.
Ọla Ọjọbọ lo yọ ki Super Eagles koju ẹgbẹ agbabọọlu Gabon ni papa iṣere Moulay Hassan, niluu Rabat, lorilẹede Morocco ki rogbodiyan naa to ṣuyọ.
Ki ni adari ikọ Super Egles sọ lori rogbodiyan yii?
Ẹwẹ, olori awọn agbagbọọlu naa, William Troost-Ekong sọ pe afojusun awọn ni lati kopa ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ nla to wa niwaju awọn.
Bo tilẹ jẹ Troost-Ekong fidi rẹ mulẹ rẹ pe aawọ wa laarin awọn agbabọọlu ọhun ati NFF.
Nigba to n sọrọ loju opo X rẹ, o ni "Ti a ba ti yanju ọrọ naa ẹnu wa ni ẹ ti maa kọkọ gbọ.
"Afojusun wa ko ju bi a ṣe maa kopa ninu awọn ifẹsẹwọn to ṣe pataki to wa niwau wa."
Iye igba ti agbọọlu Naijiria ti kọ lati ṣe igbaradi latari ajẹmọnu wọn ti ijọba ko san
2014: Lọdun 2014, awọn agbabọọlu Super Eagles kọ lati wọ bọọsi lati lọ ṣe igbaradi wọn lasiko ife ẹyẹ agbaye, 2014 World Cup nitori ajẹmọnu ti ijọba jẹ wọn. Iṣẹlẹ naa lo waye lẹyin ifẹwọnsẹ wọn pẹlu orilẹede Argentina.
2019: Lẹyin ti wọn lulẹ ninu idije 2019 Women's World Cup awọn agbabọọlu Naijiria obinrin (Super Falcons) kọ lati fi ile itura wọn silẹ lati fẹhonuhan pe ijọba gbọdọ san ajẹmọnu wọn fun wọn.
2022: Awọn agbabọọlu obinrin (Super Falcons) kọ lati ṣe igbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ ipo kẹta wọn ninu idije 2022 Women's Africa Cup of Nations (AWCON) ni Casablanca.
2025: Awọn agbabọọlu Super Egles kọ lati ṣe igbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Gabon ni Rabat, Morocco, nitori awọn ajẹmọnu ti ijọba jẹ wọn lati ọdun 2019.















