Ìjọba ìpínlẹ̀ Borno ya ọjọ́ Ajé ọ̀sẹ̀ yìí sọ́tọ̀ fún ààwẹ̀ àti àdúà gbígbà

Oríṣun àwòrán, @Mohamme17292289
Ki alaafia le jọba lẹyin aibalẹ ọkan to gbalẹ kan lorilẹede yii, ijọba ipinlẹ Borno ti ya ọjọ Aje, ọjọ Kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025 sọtọ fun aawẹ gbigba ati adua ṣiṣe.
Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum, lo kede eyi lọjọ Abamẹta, lori eto kan lori amohunmaworan Channels.
Gomina Babagana sọ pe aawẹ gbigba ati adua naa ko kan ti ẹsin ti awọn eeyan ipinlẹ oun ba n ṣe, bi ko ṣe pe ki kaluku pawọpọ lati gba a.
Gẹgẹ bo ṣe wi:
" Mo fi asiko yii kede Mọnde, ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kọkanla ọdun 2025 bii ọjọ aawẹ gbigba ati adua ṣiṣe kaakiri ipinlẹ Borno, fun idapada alaafia ni Borno ati gbogbo orilẹede yii lapapọ.
"Lọjọ yii, mo pe gbogbo olugbe Borno, ẹsin yowu ti wọn le maa ṣe, lati darapọ mọ adua yii fun alaafia ipinlẹ ati orilẹede wa.
"Ẹ jẹ ka jọ fi ara jin fun ṣiṣe adua deede, ka si maa wa aanu Oluwa."
Gomina Zulum ni oun ki i ṣe gomina lasan ni Borno, ọmọ orilẹede Naijiria to nifẹ ilu yii ni oun naa.
O gboriyin fun awọn eeyan Borno fun ifarajin wọn lati bii ọdun mẹẹẹdogun ti awọn agbesunmọmi ti n ṣoro nipinlẹ naa.
"Pẹlu aṣẹ Oluwa, a bori awọn asiko ipọnju ti awọn agbesunmọmi fi n yọ wa lẹnu, nipa diduro ni iṣọkan.
" A ko fi ti ẹya, esin tabi ẹka ọtọọtọ ṣe. A ti awọn ọmọ ogun wa lẹyin lati koju awọn ọta to fẹ da ipinlẹ wa, Ariwa- Ila-Oorun ati gbogbo Naijiria ru."
Gomina Zulum, ẹni ti ikọ agbesunmọmi ti dọdẹ ẹmi rẹ ri ninu ikọlu, sọ pe iyatọ ti wa ni Borno ju bi nnkan ṣe wa tẹlẹ lọ.
O ni awọn agbẹ tilẹ ni anfaani lati ṣe ọgbin awọn nnkan oko to le gbe wọn fun ọdun kan tabi meji, ti ere oko ọdun yii naa si ti gbe ọwọ ire.
Bo si tilẹ jẹ pe Babagana Zulum naa loun gba pe ikọlu n waye lọtun-un losi, ọ rọ awọn eeyan Borno lati duro ṣinṣin bii iṣe wọn.
"Iduro ṣinṣin ati ifarajin yii n jẹ orisun agbara fun mi ati fun ijọba mi. Gẹgẹ bi iran eeyan to ni igbagbọ, a gbagbọ pe a tun gbọdọ fi adura kun ilana aabo wa."
O fi kun un pe ijọba oun yoo tẹsiwaju lati maa ran awọn oṣiṣẹ eleto aabo lọwọ, pẹlu awọn fijilante, ajọsọ yoo si maa waye nibi to ba yẹ lai gbabọde fun araalu.
Ẹ o ranti pe idaamu gbode lọsẹ to kọja yii ni Naijiria, bi awọn agbebọn ṣe pa olori ogun kan, Ọgagun Musa Uba, ti wọn ji akẹkọọbinrin mẹẹẹdọgbọn gbe ni Kebbi, ọọdunrun le mẹẹẹdogun (315) ni Niger, ti wọn si tun pa eeyan mẹta ni ṣọọṣi Eruku, ipinlẹ Kwara, ti wọn ko ọpọ wọgbo lọ.














