Ìdí rèé tí Jandor ṣe fi PDP sílẹ̀ àti ohun tó mú kó kùnà láti dojú Sanwo-Olu bolẹ̀ lásìkò ìbò gómìnà l‘Eko

Aworan Jandor

Oríṣun àwòrán, Olajide Adediran/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Oludije fun ipo gomina ẹgbẹ oṣelu PDP ninu eto idibo gomina ipinlẹ Eko lọdun 2023, Abdul-Azeez Adediran, ti ọpọ mọ si Jandor ti sọ pe oun o ba la Gomina Babajide Sanwo-Olu mọlẹ ninu eto ibo naa ṣugbọn iji ''Tsunami'' Peter Obi to n ja kiri nigba naa lo ja oun kulẹ.

Jandor sọrọ yii lori eto ileeṣẹ tẹlifisan Channels kan ti wọn n pe ni ''Politics Today'' lalẹ ana ọjọ Iṣẹgun.

Ṣaaju ni ibẹrẹ ọsẹ yii ni Jandor kede wi pe oun ti fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ.

''Nigba to n sọrọ lori eto naa, Jandor ni ''eto idibo gbogbogbo ọdun 2023

Jandor ni ayipada ba oju tawọn eeyan fi n wo eto idibo lẹyin ti Peter Obi oludije sipo aarẹ fẹgbẹ LP la Bola Tinubu mọlẹ wọle ibo aarẹ nipinlẹ Eko lọdun 2023.

Oludije sipo gomina ẹgbẹ oṣelu PDP ni eyi lo ṣakoba foun ati PDP ninu ibo gomina to waye nipinlẹ Eko lẹyin ọsẹ meloo kan ti ibo aarẹ ti kọkọ waye.

Ti ẹ o ba gbagbe, ajọ INEC kede Sanwo-Olu ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ Eko ọdun 2023.

Ajọ INEC kede pe ibo 762,134 ni Sanwo-Olu ri ti Gbadebo Rhodes-Vivour Oludije ẹgbẹ oṣelu LP to ṣe ipo keji ri ibo 312,329 nigba ti Ọgbẹni Adediran ṣe ipo kẹta pẹlu ibo 62,449.

Ninu ibo aarẹ to waye ṣaaju ibo gomina nipinlẹ Eko, Obi to jawe olubori ninu eto idibo naa ri ibo 582,454 nigba ti Tinubu tẹle e pẹlu ibo 572,606.

Atiku Abubakar to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP lo ṣe ipo kẹta pẹlu ibo 75,750.

Jandor ni ọrọ Obi ti ọpọ gbe sori lojiji lo ṣiṣẹ tako PDP ninu ibo gomina ọdun 2023 l'Eko.

Ọgbẹni Adediran ṣalaye wi pe ṣaaju eto idobo gbogbogbo ọdun 2023 ni PDP ti n ko ọpọ eeyan jọ ti APC ko si le figa gbaga pẹlu awọn.

O ni ọpọ eto ni oun lọ gẹgẹ bii oludije fun ipo gomina PDP ṣaaju eto idibo eyi ti Sanwo-Olu ko yọju sibẹ rara.

Jandor ni oun ati Sanwo-Olu lawọn jọ n fa a ki ibo aarẹ to de nibi ti Obi ti wọle eyi to si mu ayipada ba gbogbo nnkan ṣaaju ibo gomina nipinlẹ Eko.

Oludije sipo gomina PDP lọdun 2023 ṣalaye pe aṣeyori Obi ninu ibo aarẹ l'Eko lo jẹ ki ọpọ eeyan dibo fun ẹgbẹ oṣelu LP ninu ibo gomina eyi to ṣakoba fun PDP.

Idi ti mo fi kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP - Jandor

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Jandor ni PDP gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣelu ko ni igbagbọ ninu ara rẹ mọ latari aawọ to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa.

Nigba to n sọrọ lori eto ileeṣẹ tẹlifisan Channels kan ti wọn n pe ni ''Politics Today,'' Ọgbẹni Adediran sọ pe wahala to n ṣẹlẹ ninu PDP lati oke gan an lo mu oun fi ẹgbẹ naa silẹ.

Jandor ni fun bi oṣu meloo kan loun ronu lori igbesẹ yii ki oun to kede pe oun ti kuro ninu ẹgbẹ PDP.

O ni awọn aṣiwaju inu ẹgbẹ oṣelu PDP loke ati nipinlẹ Eko ja oun kulẹ pẹlu bo ni wọn ti n tako awọn ọmọ ẹgbẹ to n ṣiṣẹ fun ilọsiwaju ẹgbẹ.

Jandor lo eto ipolongo ibo rẹ lọdun 2023 bi apẹẹrẹ ọna tawọn agbaagba ẹgbẹ naa fi ja a kulẹ.

Oludije sipo gomina PDP nipinlẹ lọdun 2023 sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa kan lẹdi apo pọ mọ ẹgbẹ alatako lati kọju ija soun.

O ni ọpọ agba ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko ni wọn ri ipo toun wa gẹgẹ bi oludije sipo gomina bii nnkan to le ṣakoba fun wọn.

Jandor ranti bawọn janduku ṣe kọlu u lasiko ipolongo ibo ti awọn agbaagba ẹgbẹ ko si sọ ohun kan lori iṣẹlẹ naa.

Ọgbẹni Adediran fikun ọrọ rẹ pe Oloye Bode George to jẹ ọkan lara awọn aṣiwaju ẹgbẹ n ṣatilẹyin fun ẹlomiran lati ṣoju PDP gẹgẹ bii oludije sipo gomina fẹgbẹ PDP ninu ibo ọdun 2023.

Jandor ni oun ko tii le sọ ẹgbẹ oṣelu ti oun yoo darapọ bayii, o ni oun yoo maa kede rẹ lọjọ iwaju.