UN figbe ta pé àwọn agbébọn ń fipá bá àwọn ọmọ ọdún kan lo pọ lásìkò ogun abẹ́lé ní Sudan

Oríṣun àwòrán, Unicef
- Author, Barbara Plett Usher in Port Sudan & Natasha Booty in London
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Ikilọ : Awọn alaye kan wa ninu iroyin yii ti awọn eeyan mi-in le ma nifẹẹ si.
Awọn ọmọ kekere ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun kan lọ ko moribọ ninu ibalopọ ipa to koju wọn lati ọwọ awọn ọkunrin to dihamọra ogun lasiko ti ogun abẹle n waye ni Sudan.
Ajọ Iṣọkan Agbaye, UN, lo fidi eyi mulẹ lati ọdọ ẹka wọn to n ri si ọrọ ọmọde; UNICEF.
Ohun kan ti wọn sọ pe o kari, to fẹrẹ ma si ẹni ti ko lugbadi rẹ lasiko ogun to fẹrẹ to ọdun meji naa ni ibalopọ ipa .
Akọsilẹ sọ pe wọn lo ibalopọ tulaasi naa bii nnkan ija ogun ni.
Ṣugbọn abọ iwadii UNICEF ni akọkọ ninu awọn to royin iṣẹlẹ naa, abọ iwadii wọn lo fidi ẹ mulẹ ju pe wọn ba awọn ọmọ kekere lo pọ gidi gan-an ni Sudan lasiko ogun abẹle to ja wọn.
Ida mẹta awọn ti wọn lugbadi ibalopọ ipa naa jẹ ọmọdekunrin, awọn ti wọn ko le sọ ohun to n ṣẹlẹ si wọn nitori bo ṣe ri, eyi ko si jẹ ki wọn le beere iranlọwọ ti wọn nilo lati bọ ninu agbako naa.
Ó ṣeé ṣe kí ìbálòpọ̀ ipá tó wáyé ju 221 tí àkọsílẹ̀ sọ lọ- UNICEF
Gẹgẹ bi ajọ UNICEF ṣe wi, wọn ni ibalopọ 221, iyẹn ọkan-le-ni -okoo-le ni-igba ni iye akọsile ibalopọ to ṣẹlẹ sawọn ọmọde naa lati ibẹrẹ ọdun 2024, ṣugbọn otitọ ibẹ bi wọn ṣe wi ni pe o ṣee ṣe ko pọ ju bẹẹ lọ.
Sudan jẹ orilẹede kan ti wọn ti ka ibalopọ si nnkan aṣiri ati ọ̀wọ̀ ti eeyan ko gbọdọ maa sọ nipa rẹ nita gbangba.
Oju abuku ti wọn yoo maa fi wo ẹni to ba sọ pe wọn ba oun sun ki i jẹ ki wọn ṣalaye ibalopọ agidi ti wọn ba koju.
Bakan naa si ni ibẹru awọn ologun naa tun maa pa ohun mọ wọn lẹnu pẹlu.
Abọ iwadii ajọ UNICEF lo tu aṣiri ohun ti oju ọpọ ọmọde ri lasiko ogun abẹle Sudan.
Ohun to jẹ iyalẹnu ju ninu aṣiri to tu naa ni pe mẹrindinlogun ninu awọn ti wọn ba lo pọ tipatipa ni ọjọ ori wọn ko tiẹ pe marun-un rara, bẹẹ si ni awọn ọmọ ọwọ́ mẹrin wa ninu wọn.
Bo tilẹ jẹ pe UNICEf ko tọka awọn to wa nidii ifipabanilopọ yii pato, awọn iwadii UN mi-in ti naka abuku si awọn ikọ alaabo ti wọn pe ni Rapid Support Forces (RSF). Wọn ni awọn ikọ RSF yii ni awọn eeyan mọ fun fifi ibalopọ ipa ba aye awọn eeyan jẹ, ti wọn maa n fi ilana yii dunkooko, ti wọn si fi n pa awọn eeyan lẹnu mọ.
Ṣugbọn ko sẹni ti yoo fi ọbẹ to nu jẹsu. RSF naa ti fesi pada, ikọ to n koju awọn ọmọ ogun Saudan naa sọ pe awọn ko ṣe ohun to jọ bẹẹ rara.
" Ibalopọ ipa ti a ti ṣe akọsilẹ rẹ ni Sudan lagbara gan-an"
Mohamed Chande Othman, Alaga to n ri si iwadii lọdọ UN lo sọ bẹẹ loṣu Kẹwaa to kọja, lasiko ti wọn gbe akọsilẹ iwadii wọn jade.
Ẹgbẹ International Human Rights Groups, ṣalaye pe awọn eeyan to wa ni Darfur, nibi ti RSF ti lagbara gan-an ni wọn maa n da oju sọ, wọn ni nitori pe awọn eeyan naa jẹ alawọ dudu, ti wọn ki i ṣe Araabu ni RSF ṣe tẹ oju wọn mọlẹ lasiko ogun naa, idi ti wọn fi n ṣe eyi si ni lati le wọn jade kuro ni Sudan patapata.
Bẹẹ si ni owo iranwọ ti UN n fun Sudan ti dinku jọjọ. Owo iranwọ ti America dinku laipẹ yii ni a gbọ pe yoo fa ọwọ aago aanu sẹyin fun awọn to nilo rẹ bayii.
''Bí wọ́n bá dá àwọn ọmọdé náà padà lẹ́yìn ìbálòpọ̀, wọn kì í mọ ohun tí wọ́n ń ṣe mọ́''
"Aago mẹsan-an alẹ ti kọja, ẹnikan ṣilẹkun, o mu ẹgba dani, o bẹrẹ si i ṣa awọn ọmọbinrin naa nikọọkan, o n ko wọn lọ si yara mi-in.
''Mo n gbọ ti ọmọdebinrin kan n ke, to n pariwo, wọn n fipa ba a lo pọ ni."
Obinrin kan toun naa ti la ibalopọ ipa yii kọja ri, ti a pe orukọ rẹ ni Omnia, lo ṣalaye bayii.
Inu yara kan ni wọn ti oun naa mọ pẹlu awọn ọmọbinrin ti awọn ọkunrin to dihamọra ogun naa fi wọn si .
"Ni gbogbo igba ti wọn ba ti fipa ba a lo pọ, ọmọbinrin yii yoo sunkun wọle wa pẹlu ẹjẹ ni gbogbo ara rẹ, ọmọ kekere gbaa ni.
''Idaji nikan ni wọn maa n yọnda awọn ọmọbinrin yii, bi wọn ba si de, ẹlẹgbẹẹ pe wọn ko mọ ohun ti wọn n ṣe mọ ni. Gbogbo wọn maa n sunkun ni, wọn yoo si maa sọrọ ti ko tiẹ ni i ye awa ti a n gbọ ọ.
''Laaarin ọjọ mọkadinlogun ti mo lo nibẹ, o to asiko kan to n ṣe mi bii pe ki n pa ara mi."
Latari ogun to ti sọ orilẹede Sudan di nnkan mi-in, o ṣoro fun wọn lati ri iranwọ, aabo ati aanu ti wọn nilo latọdọ awọn oṣiṣẹ to yẹ ko ṣaanu wọn.
Ọpọ eeyan to ti di alainilelori mọ nitori ogun yii, eyi si ti jẹ ki awọn ọmọde ati awọn obinrin wa ninu ewu ikọlu niluu naa.
Bi ẹ ba ri ọmọ ileewe obinrin mẹrin, mẹta ninu wọn ni ko si nileewe mọ.
UN lo sọ bẹẹ.
''Trump tó yọwọ́ ìraǹwọ́ náà nípa tiẹ̀''
Adinku iranwọ ti Aarẹ ilẹ America, Donald Trump, gunle fun awọn orileede agbaye ko daa fun Sudan naa.
Ọpọ awọn eeyan orilẹede yii ko ri itọju gba nileewosan mọ, wọn ko tilẹ ri ileewosan lọ nitori ọpọlọpọ ileewosan wọn ti di ahoro nitori ogun.
Iranwọ ti Trump si tun yọwọ rẹ yii le ṣakoba fun awọn ọmọde, nitori ko si aabo fun wọn mọ bo ṣe yẹ.
Ajọ UNICEF lo ti n pese aabo fun awọn ọmọde tẹlẹ, to n fun wọn ni itọju pajawiri nigba ti wọn ba nilo rẹ.
Gbogbo awọn ajafẹtọọto n gba ẹnu awọn eeyan sọrọ lo jẹ pe ori iranwọ ilẹ okeere yii ni wọn duro le, ọpọlọpọ ibi ti wọn ti n ri iranwọ tẹlẹ lo si ti di ibi igbagbe bayii.
BBC ri i gbọ pe lara awọn ibudo ajafẹtọọ ọmọniyan ti wọn pe orukọ ẹ ni "She Leads", ti ko-igbawọle bayii nigba ti owo iranwọ ko ti wa lati US mọ.
''Awọn ti wọn ti koju ibalopọ ipa latọwọ awọn ọkunrin to dihamọra yii ko tiẹ tun ni le jokoo ronu mọ, ohun gbogbo ti ba wọn.''
Sulaima Elkhalifa, ajafẹtọọ ọmọniyan ni Sudan lo sọ bẹẹ fun BBC.














