Ọ̀gá tẹ́lẹ̀ fún iléeṣẹ́ arìnrìnàjò tí ayé ń kígbe pé Boko Haram pa, ilé ìtura ló kú sí l'Abuja - Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, David Parradang/ Facebook
Lọjọ kẹta, oṣu Kẹta ọdun 2025 yii, okiki kan pe ọga pata tẹlẹ fun ileeṣẹ to n ri si iwọle-ijade awọn arinrinajo ni Naijiria, (immigration) iyẹn David Parradang ti bọ sọwọ ajinigbe, wọn si ti pa a.
Bi iroyin iku naa ṣe gbode ni awọn kan ti n gbe e kiri.
Eyi lo n lọ lọwọ ti ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria l'Abuja, fi tan imọlẹ si iku Oloogbe naa lọjọ keji iṣẹlẹ yii.
Eyi ni ohun ti ọlọpaa sọ pe o ṣẹlẹ gan-an.
"A rí òkú Parradang ní yàra òtẹ́ẹ̀lì tó gbà, lẹ̀yìn tí àlejò obìnrin tó wá á kí i lọ tán"
Gẹgẹ bi atẹjade to ti ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria wa ṣe wi, wọn ni Oloogbe Parradang gba yara otẹẹli kan to wa lagbegbe Area 3 Junction, lọjọ Iṣegun, ọjọ kẹta, oṣu Kẹta ọdun 2025.
Aago mejila ọsan ọjọ naa lo wa ọkọ ayọkẹlẹ mẹsidiisi rẹ de otẹẹli naa, ẹgbẹrun mejilelogun naira (22,000) ni wọn lo san fun yara ọhun.
Atẹjade ti Alukoro ọlọpaa fun ilu Abuja, Josephine Adeh, buwọ lu, tẹsiwaju pe ko pẹ ti Parradang wọ yara rẹ ni alejo obinrin kan wa a ki i.
'' Ko pẹ to wọle si yara rẹ lo ni ki oṣiṣẹ otẹẹli naa ba oun mu alejo obinrin to n beere oun wa si yara.
''Alejo obinrin naa kuro ni otẹẹli yii ni nnkan bii aago mẹrin ọsan ọjọ naa.
Ọgbẹni Parradang ko jade ni yara naa lẹyin ti obinrin yii lọ tan.
''Nigba to di nnkan bii aago mẹrin idaji ọjọ keji, ọrẹ rẹ kan to jẹ ṣoja tọpasẹ rẹ de otẹẹli naa lati beere alaafia rẹ.
Ọrẹ naa pẹlu oṣiṣẹ to n gba alejo lotẹẹli ni wọn jọ lọ si yara Parradang, nibẹ ni wọn si ti ba a to ti ku sori aga to jokoo si.''
Bẹẹ ni atẹjade awọn ọlọpaa niluu Abuja ṣalaye nipa iku naa.
Wọn ni iroyin ofege ni eyi to n sọ pe awọn kan lo ji Oloogbe Parradang gbe ti wọn si pa a, ki ẹnikẹni ma ṣe gba iroyin naa gbọ.
Agọ ọlọpaa Durumi ti wọn kọkọ fi iṣẹlẹ naa to leti gbe igbesẹ nipa bi wọn ko ṣe faaye gba irin ti ko nidii lagbegbe iṣẹlẹ yii.
Wọn ya fọto ohun ti wọn ri, wọn si mu awọn ẹri ti wọn nilo lọ.
Bakan naa ni wọn gbe oku Oloogbe David Parradang lọ si ọsibitu ijọba apapọ to wa l'Abuja, lati ṣe eto gbogbo to yẹ.
Awọn oṣiṣẹ otẹẹli naa si n ran ọlọpaa lọwọ ninu iwadii wọn.
Ta a ni Oloogbe David Parradang?

Oríṣun àwòrán, David Parradang/ Facebook
Ọmọ ipinlẹ Pleateau ni Oloogbe David Shikfu Parradang.
Oloogbe David Shikfu Parradang jẹ oṣiṣẹ ijọba to fẹyinti gẹgẹ bi ọga lẹyin to ti lo ju ọgbọn ọdun lọ nileeṣẹ to n ri si iwọle-ijade awọn arinrinajo ni Naijiria.
O ṣiṣẹ ni awọn ipinlẹ bii Kano, Eko, Enugu, Kwara ati Abuja, bẹẹ lo si ti rin irinajo lọ silẹ okeere kaakiri lati kọ ẹkọ si i.
Ni 2014, Oloogbe Parradang lo dari eto igbani-siṣẹ nileeṣẹ arinrinajo ilẹ wa, nibi ti eeyan to le ni ogun ti tẹra wọn pa.
Ọkan lara awọn to gba oye idanilọla nla lorilẹede yii ni Parradang, nitori o gba oye OFR ti i ṣe Officer of the Order of the Federal Republic.
Parradang ko jokoo lasan lẹyin to fẹyinti lẹnu iṣẹ ijọba, o gbiyanju oṣelu, o si du ipo sẹnetọ ati gomina nipinlẹ Pleateau ni 2023, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ọlọjọ de si i l'Abuja, wọn ri oku rẹ nibi to jokoo si lori aga ile itura .














