BBC fojú ṣe mẹ́rin bí wọn ti ń ṣàtúnṣe wáyà ojú òpó ìtàkùn àgbáyé tó bá bàjẹ́ lábẹ́ òkun

Àkọlé fídíò, BBC fojú ṣe mẹ́rin bí wọn ti ń ṣàtúnṣe wáyà ojú òpó ìtàkùn àgbáyé tó bá bàjẹ́ lábẹ́ òkun
BBC fojú ṣe mẹ́rin bí wọn ti ń ṣàtúnṣe wáyà ojú òpó ìtàkùn àgbáyé tó bá bàjẹ́ lábẹ́ òkun

Awọn waya kan lo n gbe oju opo itakun agbaye nilẹ Afirika, abẹ okun si ni wọn ri awọn waya naa si, eyi to to ẹgbẹrun lọna aimọye ẹgbẹrun mita si oke eepẹ.

Amọ bi awọn waya naa se wa nilẹ ọgbun lọhun ninu okun, sibẹ n jẹ ẹ mọ pe o si seese kawọn waya naa bajẹ nibẹ?

Lọdun to kọja, eyiun ọdun 2024, ọpọ aimọye awọn waya yii lo bajẹ jake jado origun mẹrẹẹrin ilẹ Afirika eyi to se akoba nla fun isẹ ibaraẹnisọrọ, ile ifowopamọ atawọn okoowo miran.

Ileesẹ The Leon Thevenin, jẹ ileesẹ to kọsẹ mọsẹ nipa atunse awọn waya oju opo ayelujara yii.

Ojuse wọn si ni lati maa se atunse awọn waya itakun agbaye to ba bajẹ naa, ki wọn le e bẹrẹ isẹ pada bo se yẹ.

Ọna lati mọ bi ileesẹ yii se n sisẹ, paapaa atunse awọn waya to n gbe itakun agbaye wa fawọn eeyan nilẹ adulawọ, lo mu ki BBC dara pọ mọ wọn lasiko ti wọn fẹ se atunse waya to bajẹ ninu okun ilẹ Ghana.

Awọn kebu itakun agbaye lo wa ni isalẹ okun, wọn fuyẹ, ti wọn ba ge wọn, ọpọlọpọ orilẹede lo maa ja kuro lori ayelujara

N jẹ o mọ pe gbogbo igba to ba n fi atẹjiṣẹ ranṣẹ tabi to ba wa lori ayelujara,

awọn kebu kọọkan lo n jẹ ko ṣeeṣe.

Ṣugbọn awọn kebu wọnyii wa ni isalẹ okun, wọn si fuyẹ, ti wọn ba ge wọn, ọpọlọpọ orilẹede lo maa ja kuro lori ayelujara.

Yatọ sawọn orilẹede miiran, ti wọn se itakun ayarabiasa loriṣiriṣi lori ilẹ wọn, ilẹ Afirika gbẹkẹle awọn kebu wọnyii ninu okun fun ipese itakun agbaye tiwọn.

Awọn kebu naa lo so Afirika mọ awọn eeyan miran l'orilẹede agbaye lori ẹrọ ayarabiasa.

Foonu

"Ti nnkan ba ṣẹlẹ si awọn kebu abẹ okun naa, odidi orilẹede kan le padanu anfaani ati lo oju opo itakun agbaye"

Ni igba tawọn orilẹede kọọkan l'Afrika ni irufẹ kebu itakun agbaye yii, ti nnkan ba ṣẹlẹ si, odidi orilẹede kan le padanu anfaani ati lo oju opo itakun agbaye.

Ọkọ oju omi Leon Thevenin, jẹ ọkan lara awọn ọkọ oju mi to n tun awọn kebu naa ṣe.

Nigba to n ba BBC sọrọ, ọkan lara awọn osisẹ ileesẹ naa ni

"Awa eeyan lo maa n ṣokunfa gige awọn kebu wonyii.

Yala nigba ta ba n pa ẹja ninu okun ni tabi tawọn ọkọ oju omi wa gan paapaa gba n gun ori omi.

Ti ẹ ba wo ara kebu naa, ẹ o ri apẹẹrẹ pe nnkan ha ara rẹ ni."

"Ẹrọ ta n dari nibikan, ROV, ni a maa ran lọ sisalẹ okun, lati lọ ṣayẹwo kebu to bajẹ naa"

Osisẹ naa tẹsiwaju pe "Atunṣe awọn kebu naa bẹrẹ nipa lilo ẹrọ to n tanna wadi isẹlẹ ti wọn n pe ni 'probe'.

Ẹrọ naa lo wa lati ṣawari ibi ti kebu naa wa, ti a o si fi siginali ranṣẹ lati inu ọkọ oju omi yii si kebu naa.

Siginal yii maa gba inu kebu naa, ọkọ oju omi yoo si tẹlẹ siginali naa, titi ti a o fi de ibi ti a ko ni ri mọ.

Ẹrọ ta n dari nibikan, ROV, ni a maa ran lọ sisalẹ okun, lati lọ ṣayẹwo kebu to bajẹ naa.

A ge apa ibi to ba bajẹ, a si fi ranṣẹ s'ọkọ oju omi kan lati le tun ṣe."

"Ta ba ti tun ṣe tan, a o da kebu naa pada si isalẹ okun, gbogbo ayeluja a si pada si n ṣiṣẹ dede"

Ninu alaye rẹ siwaju, osisẹ naa ni "Ta ba fẹ tun kebu naa se daadaa, gbogbo waya inu

rẹ to tiirin ju irun eeyan lọ gbọdọ na gbọọrọ lai kako.

Ipele meji lo wa nibi fun atunse kebu naa, ta ba ti tun ṣe tan, a o da kebu naa pada si isalẹ okun, gbogbo ayeluja a si pada si n ṣiṣẹ dede.

Nitorinaa, igbakugba ti ikanni ifowopamọ rẹ tabi Whatsapp abi ayelujara rẹ gan ba dawọ iṣẹ duro, o seese ko jẹ ọkan lara awọn kebu wọnyii lo bajẹ."