Wo orúkọ̀ èèyàn 17, tó fi mọ́ Simon Ekpa, tíjọba kéde pé wọn ń gbé owó kalẹ̀ fún ìgbésùnmọ̀mí

Aworan Simon Ekpa ati awọn agbesunmọmi

Oríṣun àwòrán, @AbumNwaChineke, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba apapọ ti kede pe adari ẹgbẹ IPOB to n ja fun ominira orilẹede Biafra, Simon Ekpa, atawọn mẹrindinlogun mii n ṣatilẹyin owo fawọn agbesunmọmi ni Naijiria.

Bakan naa ni ijọba tun ti gbẹse le akaunti owo Ekpa atawọn mẹrindinlogun yooku.

Ti ẹ o ba gbagbe, Ekpa ti dero ẹwọn ri tẹlẹ lorilẹede Finland lori ẹsun ṣiṣẹpọ pẹlu awọn agbesunmọmi.

Ẹgbẹ agbesunmọmi tuntun, Lakurawa naa wa lara awọn ẹgbẹ ti ijọba apapọ kede pe awọn ti fofin de ni Naijiria.

Lanaa Ọjọbọ ni igbimọ to n ri si ifiya jẹ arufin ni Naijiria ṣe kede awọn mẹtadinlogun naa eyi ti wọn lo wa ni ibamu pẹlu ẹka 54 ofin to tako igbesunmọmi ti ọdun 2022.

Wọnyii ni orukọ awọn eeyan mẹtadinlogun atawọn ẹgbẹ ti ijọba gbẹsẹ le akaunti wọn lori ẹsun igbesunmọmi

  • Simon Ekpa Njoku
  • Godstime Promise Iyare
  • Francis Chukwuedo Mmaduabuchi
  • John Anayo Onwumere
  • Chikwuka Godwin Eze
  • Edwin Augustine Chukwuedo
  • Chinwendu Joy Owoh
  • Ginika Jane Orji
  • Awo Uchechukwu
  • Mercy Ebere Ifeoma Ali
  • Ohagwu Nneka Juliana
  • Eze Chibuike Okpoto
  • Nwaobi Henry Chimezie
  • Ogomu Peace Kewe
  • Igwe Ka Ala Enterprises
  • Seficuvi Global Company
  • Lakurawa

Abala ofin kẹrinlelaadọta tọdun 2022 to tako igbesunmọmi sọ pe igbimọ to n fiya jẹ awọn arufin lagbara lati kede ati lati gbẹsẹ le gbogbo owo, dukia ati ohun ini awọn eeyan ati ẹgbẹ to ba lọwọ ninu igbesunmọmi.

Eyi lo jẹ ki ijọba kede wi pe oun ti gbẹsẹ le gbogbo owo ati dukia Ekpa, awọn mẹẹdogun mii ati ẹgbẹ Lakurawa lai fọta pe.

Bakan naa ni ijọba tun ti gbẹsẹ le akaunti wọn gbogbo awọn eeyan yii ati ẹgbẹ Lakurawa.

Ẹwẹ, loṣu Kẹta ọdun 2024 ni ileeṣẹ ologun kede pe awọn n wa Ekpa atawọn mẹrindinlọgọrun un mii lori ẹsun igbesunmọmi ati idunkoko lati yapa kuro lara orilẹede Naijiria.

Lẹyin naa ni awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Finland kede ninu oṣu Kọkanla ọdun 2024 pe Ekpa lọwọ ninu iwa ipa sawọn araalu, ijọba ati oniruuru iwa ọdaran mi nilẹ Igbo ni Naijiria nigba ti oun funra rẹ si wa lorilẹede Finland.

Ekpa atawọn eeyan ti ijọba kede yii ni lati sọ fun igbimọ to n ri si ifiya jẹ awọn arufin nipa dukia, owo tabi akaunti wọn ti ijọba ti gbẹsẹ le.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ti igbimọ naa fi lede sẹ ṣalaye, Aarẹ Bola Tinubu buwọlu awọn oruko yii lẹyin ti agbẹjọro agba ati minisita eto idajọ, Lateef Fagbemi, (SAN) gbe e lọ siwaju rẹ.

Ta a ni Simon Ekpa ti ijọba gbẹsẹ le akaunti ati dukia rẹ?

Ọmọ bibi ijọba ibilẹ Ohaukwu nipinlẹ Ebonyi ni Simon Ekpa ti wọn si bi ni Ọjọ kọkanlelogun, ọsu kẹta odun 1985.

O jẹ ọmọ ọba Nwangbo ni Ngbo ati Lolo Nwangbo.

Orilẹede Finland ni Simon n gbe nibi to ti n saaju ipe fun ominira fun Biafra, to si sọ fun awọn ẹẹya igbo lorilẹede Naijiria lati kopa ninu eto idibo ti ijọba apapọ ba kuna lati tu Nnamdi Kanu silẹ.

Simon, lori opo ayelujara Twitter rẹ sapejuwa ara rẹ gẹgẹ bi ajafẹtọ ọmọniyan, oludasilẹ, agbẹjọrọ, oloṣelu, agbẹnusọ Biafria ati bẹbẹlọ.

O kede ọjọ marun un lati ọjọ kẹtalelogun titi di ọjọ kẹjidinlọgbọn gẹgẹ bi ọjọ konilegbele rẹ, to si ti da rukerudo silẹ ni apa guusu ila oorun naa.

Ibẹrẹ Simon Ekpa

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹyin to pari ile girama, o gbera lọ fasiti Aberystwyth nibi to ti gba imọ Master ninu ofin.

O tẹsiwaju lọ ABMS Education ni Switzerland nibi to gba oye PhD ofin okowo.

Nigba to wa ni ewe, Simon Ekpa jẹ elere idaraya fifo, to si ni okiki laarin awọn akẹgbẹ rẹ.

O figba kan soju orilẹede Naijiria nibi idije ilẹ Africa. Lọdun 2003 ni idije awọn ọjọwẹwẹ elere idaraya ni ilẹ Afrika, Simon gba ami ẹyẹ fadaka ni ere fifo.

Gbogbo nnkan lọ daada fun Simon, sugbọn o farapa, to si fi orukun ṣeṣe, eyi ti ko gba laaye layi tẹsiwaju ninu ere idaraya.

O gbera lọ si orilẹede Finland ni ọdun 2007 fun itọju ati iṣẹ abẹ fun orunkun rẹ.

Nibẹ ni Simon ni ri igbesi ayeye tuntun, bẹrẹ iṣẹ agbẹjọro, to si bẹrẹ mọlẹbi.

Lẹyin to pinnu to duro si ilu Lahti, Simon kọ ede Finland, ti wọn si tun fun ni iwe igbelyu, to si tun kopa ninu iṣẹ ologun.

O darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu NCP ni orilẹede Finland, to si kopa ninu eto iidbo lọdun 2022.

Lati ọdun 2012 ni Simon Ekpa ti n se oṣelu loorekore.

O da ileeṣẹ Ekpa &Co to n ri si ileeṣẹ to ṣamojuto ofin irinajo.