Mi ò lórí ọkọ, mo lé lọ́gbọ̀n ọdún, kò sọ́kọ, kò sọ́mọ, mo fẹ́ ṣẹ́yún tí mo pàpà ní torí ẹni tó fún mi lóyún kò gbà á -Wasila Coded

Aworan Bimpe Akintunde (Wasila Coded)

Oríṣun àwòrán, Motherhood TV Show

Àkọlé àwòrán, Wasila Coded
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọkan ninu awọn oṣerebinrin lagboole tiata Yoruba ni Bimpe Akintunde tawọn eeyan mọ si Wasila Coded.

Ọjọ abooki obinrin naa si ti pẹ ninu iṣẹ naa, ọpọlọpọ sinima lo ti ṣe, bẹẹ lo si tun jẹ sọrọsọrọ to n gbohun safẹ lorii redio ati ẹka ayelujara.

Laipẹ yii ni Wasila Coded ṣalaye nipa irinajo aye rẹ, paapaa bo ṣe ti le lọgbọn ọdun ko too ri ọkunrin kan to fun un loyun.

Bimpe ṣalaye lori eto oṣere tiata ẹgbẹ rẹ, Debby Shokoya ti a mọ si 'Motherhood with Mummy K', pe oun fẹ ṣẹyun ọhun boun ṣe ti dagba to, nitori ọkunrin toun loyun naa fun ko gba a rara.

''Ko jọ pe a ṣaa yọ''kinni' nǹkan oṣù mi kuro, ti a fi n laṣepọ ni, àmọ́ ṣe ló di oyún"

Nigba to n dahun ibeere lori eto naa, Wasila Coded sọ pe:

''Fun odidi ọdun kan ko tun le, mo le ma si i ninu irinajo ifẹ kankan. Mi o lori ọkọ. Mo ti le lọgbọn ọdun ti mi o lọkọ debi ọmọ.

''Ẹni ti mo bimọ fun yii wa si Naijiria ni, a dẹ jọ sọrọ. Mo wa a lọ si Dubai lasiko ti mo n ṣe nnkan oṣu mi lọwọ.

''Ko jọ pe a ṣaa yọ''kinni' yẹn kuro ti a fi n laṣepọ ni, nitori niṣe lo n beere lọwọ mi pe igba wo ni mo maa too pari ẹ bayii.

''Mo pada si Naijiria lẹyin igba naa, bi mi o ṣe ri nnkan oṣu mi loṣu to yẹ ki n ri i niyẹn, mi o mọ pe mo ti loyun ni.

''Ṣugbọn mi o le bimọ yẹn nitori o wu emi naa ki n lọkọ ki n dẹ bimọ ni, ṣugbọn baba ọmọ mi loun ko fẹ oyun.

Ajọsẹpọ wa ko ti i pẹ rara ti mo fi loyun yẹn, a ko ti i mọ ara wa daadaa, igba keji ti a maa rira naa la ni ajọṣepọ to doyun yẹn.

''Mo lo ọlọ́kan-ò-jọ̀kan òògùn láti ṣẹ́yún, díẹ̀ ló kù kí n bá a lọ''

Wasila Coded

Oríṣun àwòrán, Motherhood TV Show

Gẹgẹ bo ṣe tẹsiwaju, Bimpe sọ pe oun bẹrẹ si i lo ọlọkan-o-jọkan oogun lati ri pe oyun naa walẹ, nigba ti ẹni to ni oyun naa kọ lati gba a.

''Gbogbo nnkan ni mo n mu pe koyun yẹn walẹ, mo mu ọti oriṣiiriṣii, mo tun bẹrẹ si i da ara mi laamu, gbogbo ibudo ere tiata ni mo bẹrẹ si lọ, ki oyun naa le ṣẹ, ṣugbọn ọmọ mi ṣaa fẹẹ wa saye ni, oyun ko ṣẹ.

''Ọjọ kan wa ti mo ṣubu lulẹ ninu yara otẹẹli mi loko ere, Ọlọrun ni ko pa mi lọjọ naa lẹyin nnkan ti mo lo ki oyun le walẹ.

''Ọmọ orukan ni mi, mi o niya ati baba mọ, ṣugbọn mo ni awọn eeyan to ṣugbaa mi, ti wọn ko jẹ ki n ṣẹyun naa.

''Oyun mi wa loṣu meji aabọ ni mo ri ẹjẹ lọjọ kan, iya agba ti a jọ n gbele ati awọn eeyan mi-in ṣaa sọ pe wahala ti mo n ṣe ti pọju, pe ki n sinmi.

''Bi wọn ṣe ni ki n sinmi niyẹn, oṣu karun-un ni mo too bẹrẹ iṣẹ pada.''

''Ẹni tí mo bímọ fún kò bèèrè mi ní gbogbo oṣù mẹ́sàn-án tí mo fi lóyún''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni itẹsiwaju ọrọ rẹ, Wasila Coded sọ pe ọkunrin to fun oun loyun naa ko beere oun wo rara fun gbogbo oṣu mẹsan-an toun fi loyun.

O ni awọn eeyan tiẹ tun pe e wọn ba a sọrọ, niṣe lo sọ pe oun ko fẹ oyun, pe koun lọọ ṣẹ ẹ.

''Lọjọ ti mo bimọ, bi mo ṣe bi i tan ti mo ni ki wọn gbe e fun mi bayii ni ọmọ mi laju, afi bii pe o gbọ ohun ti mo sọ.

''Bi mo ṣe gbe e niyẹn ti mo n ke, mo si bẹrẹ si i ki I loriki iya mi.

''Mo ri iya mi ninu ọmọ mi, Ayomiku Asabi.

''Ọjọ kẹsan-an ti mo bimọ ni mo ti bẹrẹ si i wẹ fun un funra mi, nigba ti n ko lẹni kan.

''Ọmọ mi ti pe ọdun mẹsan-an bayii, ọmọ to gbọn ju ọjọ ori rẹ lọ ni.

''Olowo o rọmọ ra. Pẹlu ohun to ṣẹlẹ si mi nigba yẹn, ka ni ọjọ ori mi ko ju bii ọdun mejilelogun lọ, mi o ba ṣẹyun yẹn ni.

Ṣugbọn amọran mi fun awọn obinrin asiko yii ni pe ki wọn mase ṣẹyun o.

''Ti o ba bimọ rẹ tan, kọju mọ ohunkohun ti o ba fẹẹ ṣe laye rẹ, ọmọ bibi ko da ọ duro lati ma tẹsiwaju.

''Ọmọ mi ati ọkọ ti mo pada fẹ fẹran ara wọn daadaa, wọn jọ maa n ṣe bii baba atọmọ ni.

''Koda, ọmọ mi ti ni ka foun laburo ki ọjọọbi ọdun kẹwaa oun too pe, ifẹ wa laaarin wọn gan-an.''