Ilé alájà mẹ́ta wó l'Ekoo, èèyàn méjì kú, mẹ́rìnlá farapa
![Aworan aw]on eezan to n sise nibi ile to wo](https://ichef.bbci.co.uk/ace/ws/640/cpsprodpb/8795/live/cbd41710-fa65-11ef-b610-ade17b0282d7.png.webp)
Oríṣun àwòrán, GettyImages
Ko din ni eeyan meji to padanu ẹmi nigba ti ile alaja mẹta kan dawo lọjọ karun-un, oṣu Kẹta ọdun 2025 yii, lojule 29, opopona Oriwu, Lekki, nipinlẹ Eko.
Ohun ti a gbọ ni pe yatọ si awọn to di oloogbe, eeyan mẹrinla mi-in tun farapa .
Awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ nibẹ ni wọn pe awọn to padanu ẹmi, ati pe ile naa dawo ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ.
Wọn gbe awọn oku naa jade laaago mẹjọ alẹ ku iṣẹju mẹẹẹdogun.
Ṣugbọn ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA, sọ pe eeyan mẹfa ni awọn doola ẹmi wọn labẹ ile ti wọn n kọ lọwọ ọhun.
Wọn fidi ẹ mulẹ pe eeyan meji ku loootọ
Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀?
Ọga agba fun LASEMA, Dokita Olufemi Oke-Osanyintolu, ṣalaye pe ohun to fa a ti ile alaja mẹta ti wọn n kọ lọwọ naa fi wo ko ti i ṣe ẹ tọka si pato.
"Ohun ti mo le sọ ni pe a gbe oku gende ọkunrin meji jade labẹ ile naa.
"Awọn gende ọkunrin mẹfa mi-in farapa pupọ, wọn si kọkọ fun wọn ni itọjuu pajawiri na ki wọn too gbe wọn lọ sileewosan ijọba to wa ni Marina.
"LASEMA ṣi wa lojuu iṣẹ, a n wa awọn eeyan to ṣee ṣe ki wọn ṣi wa labẹ ile naa."
Bẹẹ ni ọga awọn LASEMA, Femi Oke-Osanyintolu, wi.
Ọlọ́pàá Eko sọ̀rọ̀
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, fidi iṣẹlẹ ile to dawo yii mulẹ.
Hundeyin sọ pe bo ṣe ṣẹlẹ ni ileeṣẹ ọlọpaa ti ko awọn agbofinro lọ sibẹ lati mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an.
Hundeyin sọ pe, " Eeyan meji ku. Apapọ eeyan mẹrinla ni wọn ko lọ sileewosan ijọba ipinlẹ Eko fun itọju.
" Awọn oṣiṣẹ wa n ba iṣẹ lọ lori iṣẹlẹ yii, bẹẹ ni iṣẹ idoola ẹmi ṣi n lọ lọwọ."














