Ẹ̀rọ ló gé mi lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tí mo fi di ọlọ́wọ́ kan tó ń fi Gángan yin Ọlọ́run - Ayomide Moses
Ayanmọ ko gbọ oogun, ori ni ẹlẹjọ, ohun ti Ọlọrun yoo si se, ko fi han ẹnikan.
Ayomide Moses ni awọn ẹya ara rẹ pe perepere nibẹrẹ aye rẹ amọ lẹyin to pari iwe mẹwa ni isẹlẹ nla sẹlẹ, eyi to mu ọwọ rẹ kan lọ.
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ nipa bi isẹlẹ manigbagbe naa se waye ati ohun to fa a, Ayomide sọ̀rọ̀, ilẹ kun.
Ayomide ni onkọrin, Akewi ati onilu ni oun, kii si se bi wọn se bi oun ree pẹlu ọwọ kan.
Bakan naa, o tun salaye bo se lọ se idanwo asewọle sile ẹkọ fasiti ni kete ti wọn ge ọwọ rẹ tan, awọn ohun to sẹlẹ lasiko to wa ni fasiti pẹlu imọran rẹ fawọn ọdọ to wa nipo bii tiẹ.

"Ileesẹ to n lọ ọra lati se eroja ni mo ti n sisẹ, isẹ mi ni ki n tan ẹrọ amọ irin lọ irin, to fi ge mi lọwọ"
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ayomide Moses ni ọjọ manigbagbe ni ọjọ Kinni, osu keje ọdun 2019 ninu itan igbesi aye oun.
"Gbogbo eeyan lo maa n gbadura fun ara wọn ninu osu tuntun awọn lọjọ yii gan ni ẹrọ ge mi lọwọ lẹnu isẹ.
Ileesẹ ti wọn ti n sọ aatan di ọrọ ni mo ti n sisẹ lẹyin ti mo jade iwe mẹwa, ti mo si n mura lati kọ idanwo asewọle sile ẹkọ fasiti.
Ileesẹ to n lọ ọra lati se eroja ni mo ti n sisẹ, isẹ mi ni ki n tan ẹrọ amọ irin lọ irin, to fi ge mi lọwọ.
Asiko ti irin ge mi lọwọ yii, mo ti n gbaradi lati lọ joko sedanwo asewọle sile ẹkọ fasiti Olabisi Onabanjo."
"Ó ku ọjọ́ méjìdínlọ́gbọ̀n kí ń kọ ìdánwò sí fásitì ni mo gé lọ́wọ́ àmọ́ mo yege ìdánwò náà"
Ayomide tẹsiwaju pe isoro naa ka oun laya, ti wọn si gbe oun lọ fun isẹ abẹ nibi ti wọn ti ge oun ni ọwọ.
"Mo ge ni ọwọ ni ọjọ kinni osu keje ọdun 2019, mo si maa kọ idanwo asewọle si fasiti ni ọjọ kejidinlọgbọn osu keje naa.
Eyi tumọ si pe ọjọ mejidinlọgbọn lo wa laarin ọjọ ti ẹrọ ge mi lọwọ ati ọjọ ti maa se idanwo asewẹle sile ẹkọ fasiti.
Ọpọ eeyan ro pe ko seese fun mi lẹyin ọjọ diẹ ti mo jade ni yara isẹ abẹ, lọ maa joko se idanwo asewọle si fasiti lai raye ka iwe.
Amọ mo lọ se idanwo naa, ti mo si yege, bẹẹ ni mo wọle ẹkọ siti naa pẹlu ọwọ kan soso.
Ẹka ti wọn ti n kọ nipa awọn ede Naijiria ati lagbaye ni mo wọle si, ti mo si tun yan ede Yoruba ni aayo.
Ọpọ awọn akẹkọọ akẹẹgbẹ fasiti naa, nigba ti wọn ri ipenija ọwọ ti mo ni, n sugba mi, fi ifẹ han mi, ti wọn ko si jẹ ki n mọ ala pe mo padanu ọwọ kan."

"Eera ilẹ̀ n yin Ọlọrun, ki wa lo de ti n ko ni maa fi ọwọ kansoso to ku yin Ọlọrun, lo mu ki n maa lu Gangan nile ijọsin"
Ayomide tẹsiwaju ninu ifọrọwerọ naa nipa bo se bẹrẹ si lu ilu Gangan pẹlu ọwọ kansoso to ku.
Ko si ẹda alaaye kankan to le sọ pe oun ni oun kọ mi bi wọn se n lu ilu.
Amọ mo mọ ilu drumset lu tẹlẹ, ti n ko si kọ bi wọn se n lu ilu Gangan tẹlẹ ki ijamba to de.
Amọ lẹyin ijamba naa, mo bẹrẹ si ni fi ilu Gangan dan ọwọ wo, ti ami ohun ti wọn tun kọ mi nile ẹkọ si ran mi lọwọ nidi ilu lilu naa.
Mo ro pe awọn eera to wa nilẹ n yin Ọlọrun, ki wa lo de ti n ko ni le maa lu ilu mọ tori pe mo ni ọwọ kan.
Idi ree ti mo se pinnu lati maa lu ilu Gangan nile ijọsin ati kaakiri, ki n le maa fi yin Ọlọrun logo."
Lẹyin eyi lo ni oun di akewi ati onkọrin pẹlu atilẹyin awọn ọrẹ oun bi o tilẹ jẹ pe o ni ko rọrun fun oun to n lo ọwọ meji tẹlẹ lati maa lo ọwọ kan.
"Mi o ki n se ọlẹ, ojoojumọ ni mo n sisẹ lati de oke, mo fẹ kawọn eeyan mọ pe ohun ti ọlọwọ meji le se, ọlọwọ kan naa le se"
Nigba to n gbe imọran rẹ kalẹ fawọn akanda ẹda to ni ipenija ara kan tabi omiran bii tirẹ, Ayomide Moses rọ wọn lati mase se imẹlẹ amọ ki wọn tẹ ipa mọ isẹ.
"Ẹ ma jẹ ki awa ti a ni ipenija ara ro pe a ko wulo tabi a ko le ja mọ nkankan tori Ọlọrun to da wa ni eto fun onikaluku.
Ẹ jẹ ka fi temi se arikọgbọn nitori ohun ti ọlọwọ meji le se, ọlọwọ kan naa le se.
Emi kii se ọlẹ, mo n sisẹ, bi o tilẹ jẹ pe ko rọrun, mo n sisẹ ni aarọ ati alẹ.
Mo fẹ de ibi giga, mo fẹ de oke, ki n le sọ fun araye pe ipenija mi ko di mi lọwọ lati moke."






