Abisola Odebode: Ẹ wo àkàndá ẹ̀dá tó ń kọ́ àwọn àgùnbánirọ̀ l‘Osun ní ọ̀dà ṣíṣe lọ́fẹ̀ẹ́

Àkọlé fídíò, Abisola Odebode: Ẹ wo àkàndá ẹ̀dá tó ń kọ́ àwọn àgùnbánirọ̀ l‘Osun ní ọ̀dà ṣíṣe lọ́fẹ̀ẹ́

Ọpọ awọn akanda ẹda ni wọn ko bi ipo ti wọn wa mọ wọn lati ọrun wa.

Awọn akanda ẹda naa ni pupọ wọn di alaabọ ara lẹyin ti wọn de ile aye tan.

Ni igba miran, awọn eeyan maa n si ẹbi iru ipo ti awọn akanda naa wa ru iwa afọwọfa, amutọrunwa tabi isẹ aye.

Ọkan lara awọn akanda ẹda ti ipo to wa yii bọ si ọkan lara isọri mẹtẹẹta oke yii ni Abisola Odebode.

Lati oke si isalẹ ni Odebode ti jẹ akanda ẹda, ti apa ati ẹsẹ rẹ si rọ.

Bawo ni Odebode se di akanda ẹda?

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, akanda ẹda naa ni kii kuku se pe wọn bi oun mọ ipo naa ni.

Odebode ni awọn obi oun sọ fun oun pe oun rin lati ọmọ osu mẹwa titi di ọmọ ọdun mẹta, ki ipenija ẹsẹ to wọle tọ oun wa.

O ni ọdọ iya agba ni oun n gbe, ti wọn si sọ fun oun pe oun la ala kan nigba ti oun wa ni ọmọ ọdun mẹta, eyi ti oun rọ fun iya agba.

“Iya agba ni mo sọ fawọn nigba ti mo ji pe mo la ala pe agbebọ adiẹ kan n sa mi jẹ loju ooru.

Amọ nigba ti mo ji lọjọ keji, mo ti rọ lati ibadi de isalẹ, ti apa mi ti rọ, ti ẹsẹ naa si ti rọ..”

Lati igba yii ni Odebode ni oun ti di akanda ẹda, ti oun ko si le rin daadaa bi awọn eeyan aparapa mọ.

Mo fẹran lati maa kọ awọn eeyan lẹkọ ni mo se n kọ awọn agunbanirọ ba ti n se ọda:

Odebode, nigba to n salaye bo se di oludanilẹkọ ọda sise fawọn agunbanirọ nipinlẹ Osun, salaye pe oun fẹran lati maa kọ awọn eeyan lẹkọ.

Akanda ẹda naa, to kẹkọ jade ni ile ẹkọ fasiti Lautech ni ẹka imọ nipa ipese eroja ounjẹ salaye pe ọdọ iya agba ni oun wa, ti oun ti maa n kọ awọn akẹkọọ ni iwe.

“Mo maa n se lẹsinni ninu ile fawọn akẹkọọ girama ni ẹka imọ isiro, Physics ati Further maths.

Ki n maa kọ awọn eeyan lẹkọ wa ninu omi ati ẹjẹ ara mi ni, ọdun 2016 si ni mo dara pọ mọ NYSC Osun lati maa sedanilẹkọ ọda sise fawọn agunbanirọ.

Ọfẹ ni mo maa n kọ wọn nigba ti wọn ba n sinru ilu lọwọ amọ lẹyin isisnru ilu, mo maa n gba owo, ti wọn ba fẹ kọ isẹ naa doju ami.”

N ko fẹran ase sise, ni mo se yan isẹ sise laayo:

Odebode wa yan pe kii se ohun to bojumu fun akanda ẹda lati maa se agbe jẹun.

O ni tawọn obi ba fi ọna teeyan n gba sisẹ lati jẹun kọ ọmọ wọn to ba jẹ akanda ẹda, iru ẹni bẹẹ ko ni bọ sita maa se agbe jẹnu.

“Emi ko ri ara mi ẹni to yatọ si awọn eeyan youku nitori pe eeyan jẹ akanda ẹda, ko ni ko maa se agbe jẹun.

Bi mo ba gba isẹ ile kikun, funra mi ni maa se ọda ti maa fi kun ile naa, mo si ni ọpọ ọmọ isẹ to wa lọdọ mi.”

Odebode wa gba awọn akanda ẹda nimọran lati mase ri ara wọn bii alaabọ ara amọ ki wn yan isẹ ọwọ kan pato laayo.