Kí ló dé táwọn sọ́jà yabo àwọn òṣìṣẹ́ amúnáwá ní Ikeja, lù wọ́n lálùbami, tí wọn fi ń fo ògiri jáde lọ́ọ́fìsì?

Awn osisẹ IKEDC to n fo geeti jade kuro ni ọọfisi

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iroyin kan to gba ori ayelujara kan lo sọ pe awọn ọmọ ogun Naijiria ti yabo ileeṣẹ apinaka IKEDC to wa ni Ikeja nipinlẹ Eko laarọ Ọjọbọ.

Ni nnkan bii aago mẹjọ ku ogun iṣẹju ni a gbọ pe awọn sọja naa ya wọ olu ileeṣẹ apinaka IKEDC ti ko jina si ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko ni Ikeja.

Iroyin kan fidi rẹ mulẹ pe alubami lawọn sọja ọhun lu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ IKEDC atawọn eeyan ti wọn ba ni ọfiisi wọn.

A gbọ wi pe awọn ọlọpaa ti da si ọrọ naa, ṣugbọn obinrin sọja to dari awọn akẹgbẹ rẹ ko fẹ gba.

Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ niyii

Iwadii fi han wi pe ileeṣẹ ologun ofurufu Sam Ethnan Air Force Base to wa ni Ikeja, ti wa ninu okunkun birimu fun bi ọsẹ meji lẹyin ti ileeṣẹ IKEDC ja ina wọn tori aisan gbese ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ti wọn n jẹ ileeṣẹ naa.

Ileeṣẹ iroyin NAN sọ pe IKEDC ati ileeṣẹ ologun naa tọwọ bọ iwe adehun lati maa san ọgọta miliọnu naira loṣu, ki wọn le maa ri ina lo fun bi wakati mẹwaa si mejila lojumọ.

Amọ, ẹnikan ti ko fẹ ki wọn darukọ rẹ sọ fun ileeṣẹ apinaka IKEDC pe aisi ina mọnamọna ni ileeṣẹ ologun, ti n kọ awọn alaṣẹ ibẹ lominu lori ọrọ abo.

Ẹni naa sọ pe nnkan to n kọ awọn alaṣẹ ibudo ologun naa julọ ni awọn ile ti wọn ko nnkan ijagun si, ko gbọdọ gbona ju pẹlu bi ko ti si ina ni barike ologun naa bayii.

O ni iru iṣẹlẹ ibugbamu ado oloro to ṣẹlẹ ni barike ologun lọdun 2002 ni Ikeja, eyi to mu ọpọ ẹmi lọ, ko tun gbọdọ waye mọ.

Awọn ẹka eto ilera ati ẹka to n pese omi ni ileeṣẹ ologun naa ni aisi ina ti ṣakoba fun bayii.

Ẹni to ba ileeṣẹ iroyin NAN sọrọ naa ṣalaye pe, ileeṣẹ ologun ti san owo rọgun rọgun ninu owo to n jẹ IKEDC, amọ, ileeṣẹ apinaka ko tori eyi so ina ti wọn ja pada.

Ninu ọrọ tiẹ, adari ẹka to n ri si ibanisọrọ nile iṣẹ IKEDC, Kingsley Okotie, ni ileeṣẹ ologun naa kan sanwo fun ina isọri 'Band A' ti wọn lo ni.

Ọgbẹni Okotie ṣalaye pe ileeṣẹ ologun naa si n jẹ IKEDC lowo pẹlu ẹri to daju.