Ó tẹ́ wa lọ̀rùn ká kú sódò, ju ká di ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ lọ - Àwọn ọkùnrin Congo

- Author, Nomsa Maseko
- Role, BBC News, Rugombo
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Ni ti Jordan Bita, ọkunrin ẹni ọdun marundinlọgbọn to jẹ ọmọ orilẹede Congo, o tẹ ẹ lọrun lati wẹ̀ ko si ri sinu okun agbami nibi to ti n sa lọ, ju ko darapọ mọ awọn ọmọ ogun ọlọtẹ to n fipa mu wọn wọsẹ ologun lorilẹede naa lọ.
Apo kan bii apo idalẹsi lo rọra ko awọn nnkan ini rẹ si, o si wẹ agbami okun Rusizi kọja si Burundi.
Odo ti Jordan Bita wẹ kọja yii ni aala ati ẹnu ibode laaarin DR Congo ati Burundi.
Jordan nikan kọ lo n sa kiri bayii, pupọ ninu awọn ọkunrin orilẹede Congo ati idile wọn ni wọn ko le duro niluu wọn mọ, latari ogun to n peleke si i ni DR Congo.
Alaye ti awọn eeyan ṣe fun BBC lori iṣẹ naa ni pe awọn ọmọ ogun ọlọtẹ (M23 fighters) n fipa mu awọn ọkunrin lati darapọ mọ ikọ ologun.
Ninu ogun naa ni wọn ti gba ilu Goma ati Bukavu ni nnkan bii ọsẹ marun-un sẹyin.
"Mo ṣaa gbiyanju, mo raye sa lọ, nitori igbo ni mo la kọja dipo oju ọna ki n too rọlu agbami"
'' Awọn ọmọ ogun M23 to kun gbogbo ilu ti wọn si n fipa mu wa lati darapọ mọ wọn lati maa ba ijọba ja lo jẹ ka maa sa kiri. "
Jordan lo ṣalaye fun BBC bẹẹ lẹyin to wẹ odo naa ja sodikeji ni Burundi.
Awọn ikọ ologun Burundi n mojuto eti okun Cibitoke, nibi ti awọn eeyan Congo n gba sa lọ.
O ti to eeyan ẹgbẹrun lọna aadọrin (70,000) ti wọn ti sa lọ si Congo bayii.
'Ó kéré tán, ogún èèyàn ló bá omi lọ lọ́sẹ̀ tó kọjá'

Gẹgẹ bi alaye awọn eeyan to n gbiyanju lati sa lọ naa, o kere tan, ogun eeyan ni omi gbe lọ lọsẹ to kọja lasiko ti wọn n wẹ lati sa wọ Burundi.
300m, iyẹn ọọdunrun ni wọn pe bi odo ọhun ṣe gun to, o si jin ni iwọn 984.
Yatọ si ti ogun eeyan ti iroyin sọ pe wọn ku somi yii, ọpọ iṣẹlẹ bi eyi ni wọn lo tun ṣẹlẹ ti ẹnikan ko gbọ nipa rẹ.
Ṣugbọn sibẹ naa, awọn eeyan ṣi n sa kiri nitori wọn ko fẹẹ darapọ mọ ikọ ologun M23.
Nigba ti BBC n ba ọgbẹni Sebakungu, ọkan lara awọn to n sa kiri naa sọrọ lọwọ, ikọ ologun Burundi paṣẹ fun wọn lati kuro ni agbegbe naa, nitori awọn M23 wa lodikeji odo.
Ko pẹ sigba naa ni ikọ BBC ri awọn ọmọ ogun ọlọtẹ naa ti wọn n yan bii ologun lọọkan, ti wọn si n da awọn ọmọ Congo to ba fẹẹ sọda si Burundi pada.
Idaamu ati ewu ti awọn to n sa lọ yii n koju ko kere rara.
Ọjọ mẹwaa sẹyin ni obinrin kan, Clarice Kacindi, padanu ọmọ rẹ obinrin,ọmọ ọdun mẹta nigba ti wọn sọda odo Rusizi.
"Ọkan ninu awọn ọmọ mi sun si ori ìko, mo si mu awọn mẹta mi-in si ẹgbẹ mi.
"Awọn eeyan mi-in naa wa nibẹ ti wọn sun sori ìko naa, nigba ti a de ilaji agbami, iko ti wọn sun le ge si meji, omi si gbe ọmọ mi lọ. "
" M23 n mu aye le fun wa gan-an, wọn gbọdọ fopin si ogun yii. Bi mo ba tiẹ fẹẹ pada sile, o di dandan fun mi bayii lati ṣeṣẹ bẹre aye mi lati pada ni, gbogbo ohun ti a fi silẹ pata ni wọn ti ji ko lọ."
Obinrin naa lo ṣalaye fun BBC bẹẹ ni papa iṣere Rugombo.
'Inú àtíbàbà rẹpẹtẹ làwọn èèyàn ń sùn sí'

Atibaba to to ẹgbẹrun ni wọn ti kọ bii ibugbe ni Burundi fun awọn to n sa kiri ni.
Abẹ rẹ ni wọn n gbe ti wọn si n reti abajade iwe ti yoo fun wọn lanfaani lati le duro siluu naa bii ẹni ti ofin fọwọ si gbigbe rẹ nibẹ.
Eeyan marundinlọgbọn (25) le wa labẹ atibaba kan ṣoṣo, bẹẹ ni ọpọ awọn eeyan mi-in si n sun nita gbayau.
Ounjẹ ẹẹkan ṣoṣo ni wọn n fun wọn lojumọ.
Nigba ti baale ile kan, Ọgbẹni Bita, de si Burundi lati ori omi, ikọ ọmọ ogun ilu naa yẹ apo to gbe dani wo yekeyeke.
Wọn n ṣe eyi nitori wọn ko faaye gba ki eeyan mu nnkan ija tabi ọṣẹ́ kankan wọle .
Leyin eyi lo gbe apo naa ru sori, o si bẹrẹ si i pọn oke kan ti yoo tọ ko too de abẹ atibaba ti awọn mọlẹbi rẹ to ti ko lọ tẹlẹ wa.
Eyi to sunmọ ju ninu ile atibaba yii lo jẹ maili meje.
Ounjẹ ni Bita n gbe lọ fun awọn ẹbi rẹ, awọn bii iyẹfun agbado ti wọn ti lọ, ẹpa ati ẹwa.
Bẹẹ naa ni baale ile mi-in, Amani Sebakungu, toun naa ṣẹṣẹ wẹ agbami Rusizi de to si ti rẹ ẹ, sọ pe: "Bi eeyan ba wa ninu odo yẹn, afi ki eeyan gba kamu, ko si maa ro o pe boun ba ku tabi ye, o ṣẹlẹ naa niyẹn. Ṣugbọn b'Oluwa ti fẹ, mo la agbami kọja laaye."
''Kò dẹrùn fún Burundi tó ń gba àlejò rẹpẹtẹ yìí''
Latilẹ wa ni Burundi ti jẹ ọrẹ fun DR Congo, nitori ọta to wa laaarin Burundi ati Rwanda si ni.
Fun ọdun pipẹ ni Rwanda ati Burundi ti jẹ ọta ọrun-o-gbẹbọ, ẹsun ti awọn mejeeji fi n kan ara wọn ni pe ilu kan fẹẹ gbajọba ilu keji.
Ṣugbọn bi wọn ṣe mu Congo mọra ti awọn eeyan ibẹ si n ya wọ Burundi yii, nnkan ko rọgbọ fawọn naa rara.
"Nnkan le fun Burundi, eyi ni igba akọkọ lati bii ogun ọdun sẹyin ti wọn yoo gba awọn atipo to pọ to yii.
A ni lati ran orilẹede yii lọwọ lati maa gbalejo awọn to n ṣe atipo yii, ka le baa fun wọn ni igbe-aye-irọrun, bẹẹ naa si ni a gbọdọ maa ro ti awọn ti wọn tun ṣin n bọ waa darapọ mọ wa"
Oṣiṣẹ ajọ UN kan, Brigitte Mukanga-Eno,lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.













