Ọdún márùn-ún lẹ́yìn àjàkálẹ̀ Corona: Ẹ̀kọ́ mẹ́rin tó kọ́ wa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Isabel Caro
- Role, BBC World Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Ọdun marun-un ti pe bayii lẹyin ti ajọ Ilera Agbaye, 'World Health Organization' (WHO), kede pe aarun Corona ti a mọ si Covid-19 ti bẹ silẹ.
Ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta ọdun 2020 ni ikede naa waye.
Ijọba gbe igbesẹ agbara nigba naa, wọn paṣẹ pe ki eeyan 2.6 billion jokoo sile, ki ẹnikẹni ma jade mọ, wọn si ṣe bẹẹ lo ilana yii lati ya awọn eeyan sọtọ.
Kokoro Corona bí arun mi-in to to 777 million, o si le ni eeyan miliọnu meje to padanu ẹmi lati ara arun naa gẹgẹ bi ajọ WHO ṣe sọ.
Ajọ Iṣọkan Agbaye si ti sọ pe iku to waye lati ara Corona bayii ti wọ miliọnu mẹẹẹdogun.
Bo si tilẹ jẹ pe ọpọ aburu ni wọn ka silẹ pe Corona da silẹ kari aye, ṣugbọn awọn amoye ṣe atupalẹ awọn ẹkọ daadaa kan to jade lati ara arun to kari aye naa.
Elke Van Hoof, onimọ nipa idaamu ọkan to si tun jẹ Ọjọgbọn to ṣiṣẹ ni Vrije University Brussels, Belgium, ṣalaye pe bi wọn ṣe fofin de awon eeyan lati jokoo sile nigba naa ni idanwo to tobi ju ninu itan .
Èyí ni ẹ̀kọ́ mẹ́rin láti ara ààrùn Corona:

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìdàgbàsókè lẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀rọ
Oṣu mẹsan-an lo gba awọn onimọ ijinlẹ lati ṣe oogun keji to kapa Corona (Sars-Cov-2 virus). Imọ ẹrọ ni wọn si fi ṣe eyi, o si ṣe iranlọwọ fun abẹrẹ ajẹsara kaakiri agbaye.
Lilo ohun ti a mọ si RNA naa ṣiṣẹ pupọ, ṣugbọn itọju Covid 19 kọja lilo eyi.
Iya agba, Margaret Keenan, ẹni aadọrun-un ọdun lo kọkọ gba abẹrẹ ajẹsara to wa lati ara itọju imọ ẹrọ.
Ọjọ kẹjọ, oṣu Kejila ọdun 2020 lo gba abẹrẹ naa.
Awọn onimọ ijinlẹ to ṣe awari iwosan naa, Katalin Karikó ati Drew Weissman, gba ami idalọla ninu iṣẹ iṣegun oyinbo lọdun-un 2023.
Dokita Margaret Harris, onimọ ilera pẹlu ajọ WHO, ṣapejuwe irinajo lati ri iwosan fun Corona bii nnkan ire to ṣee fi le iran diran lọwọ.
" A ri idagbasoke gidi lẹka imọ ẹrọ."
Dr Harris lo sọ bẹẹ fun BBC.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìgbà ọ̀tun fún ẹ̀kọ́
Iṣoro nla lo jẹ fun awọn akẹkọọ nigba ti wọn ti ileewe pa kaakiri agbaye.
Awọn mi ko le tẹsiwaju ninu ẹkọ wọn mọ paapaa latari ohun to ṣẹlẹ naa.
Ileewe alakọọbẹrẹ ati girama ti ko le ṣilẹkun lasiko naa si jẹ oju ọgbẹ to buru jai, gẹgẹ bi Mercedes Mateo, olori ẹka ẹkọ ni Inter-American Development Bank (IDB),ṣe sọ.
Ṣugbọn pẹlu ifasẹyin yii, Mateo ri anfaani kan to ṣe. " Ifasẹyin naa mu ka le ronu ọna mi-in nipa ilana ikọni"
Mateo lo sọ bẹẹ fun BBC.
"Lasiko Corona lo ye wa pe ẹka ẹkọ nikan ni ko fi bẹẹ lo ilana ẹrọ igbalode, ṣugbọn Corona jẹ ka wa ọna abayọ lori ayelujara"
O ni eyi lo jẹ kawọn mọ pe dandan kọ ni ki eeyan de yara ikawe ko too kọ ẹkọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìlànà iṣẹ́ yípadà
Ọpọ eeyan lo padanu iṣẹ wọn lasiko Corona, o si tun mu awọn ọdọ kan ronu ohun ti wọn le ṣe funra wọn. O tan iṣoro airiṣẹ ṣe lagbaaye lapa kan.
''Ọkan lara awọn ẹkọ ti ajakalẹ arun naa kọ gbogbo aye ni pe o ṣe pataki lati bojuto ọna atijẹ ati iṣẹ awọn eeyan lasiko ti arun ba bẹ silẹ.
Awọn ilana tuntun to yọju lati mu iṣẹ duro ṣe iranwọ pupọ lasiko naa, o kapa ifasẹyin ti ko ba waye lẹnu iṣẹ.''
Gerson Martínez, onimọ nipa ọrọ aje nileeṣẹ International Labour Organization (ILO) ni Latin America ati Caribbean lo sọ bẹẹ.
O ni oun ko ṣiyemeji lorii pe awọn ọgbọn tawọn eeyan lo lati fi ṣiṣẹ lasiko Corona, ran ọrọ aje lọwọ lati pada sipo daadaa.
Awọn orilẹede bii Ireland ati France tilẹ ti gbe ofin kalẹ lori ọna ti eeyan le maa gba ṣiṣẹ lai si idaamu.
Mímú ìlera ọpọlọ ní kókó
Bi Corona ṣe bẹ silẹ mu ọpọ eeyan ronu nipa ilera ọpọlọ, ọkan ati gbogbo ara.
Ki i ṣe nipa ara wọn nikan, bi ko ṣe nipa awọn eeyan yooku naa to yi wọn ka.
Awọn ajọ bii WHO ati Pan American Health Organization (PAHO), ṣiṣẹ iwadii to jinlẹ lori awọn ohun to fa a tawọn eeyan fi n ko aya soke ti wọn si n pa ara wọn lẹyin ti ajakalẹ arun bẹ silẹ.
Dokita nipa irori ati awọn ohun to le ko ipaya ba eeyan, Laura Rojas-Marcos, sọ pe ''Ajakalẹ arun naa ṣe akoba fun irori ati bawọn eeyan ṣe n ranti nnkan, ṣugbọn bo ṣe ko idaamu ba wọn naa lo tun jẹ ẹkọ fun wọn."
O ni o jẹ ko ye gbogbo aye pe o ṣe pataki lati tọju ilera ọpọlọ, ko si ye wọn pe inu ara lọpọlọ naa wa.
Iwadii kan ti BBC ṣagbatẹru, rẹ to waye ni 2022 lati GlobeScan, ri i pe ida mẹta awọn eeyan kaakiri awọn orilẹede ni wọn wa lalaafia lẹyin ajakalẹ arun naa, ju asiko to n ja ran-in lọ.
Pupọ ninu wọn ṣalaye pe awọn ni asiko to pọ si i lati lo pẹlu awọn ẹbi awọn, awọn ri aaye fun ara adugbo ati fun ohun gbogbo to jẹ ti Iṣẹda.
Eyi ni ipa to daa lori ilera wọn, bi iwadii ṣe fidi ẹ mulẹ lẹyin arun naa.
Ajakalẹ arun yii tun mu kawọn eeyan le ni ifarada, o si mu wọn ni aanu ọmọlakeji loju.
Gẹgẹ bi Rojas-Marco ṣe wi, o ni nnkan to maa n wa lookan aya awọn eeyan ju lasiko iṣoro ni bi wọn yoo ṣe ran ara wọn lọwọ lasiko iṣọro ti wọn yoo fi jọ ṣẹgun.













