Makinde buwọ́lu ìwé òfin to sọ Emmanuel Alayande College of Education di Fáṣítì ní ìpínlẹ̀ Oyo 

Aworan

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Gomina Ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde tí buwọlu iwe ofin ti awọn ile gbìnmọ aṣofin ipinlẹ Oyo fi n bere fun pe ki wọn sọ ile ẹkọni nipa iṣẹ olùkọ: Emmanuel Alayande College of Education di Fasiti ni Ipinlẹ Oyo.

Makinde buwọlu abadofin lọjọ Aje ọsẹ yii.

Saaju ile gbìnmọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti sọ aba naa ọhun dii ofin.

Nigba ti Gomina sọrọ, o salaye pe igbesẹ naa yoo ilọsiwaju ba eto ẹkọ nipinlẹ naa, tí yoo fun awọn akẹkọọ ni ọpọlọpọ anfani.

O tẹsiwaju pe akitiyan ijọba ipinlẹ Oyo ni lati ri pe fasiti tuntun ọhun jẹ ọkan lara fasiti to da julọ lorilẹede Naijiria.

"Eyi tun ohun tuntun nínu ìtan eto ẹkọ ipinlẹ Oyo. Eto ẹkọ jẹ ọkan lara awọn ti a ṣe ileri fun awọn eeyan ipinlẹ Oyo.

"Ile ẹkọ naa yoo ni anfani lati fun awọn akẹkọọ ni ìwe ẹri ti fasiti bayii, ti a ko sini lati gbogbo ileri tí a ṣe fun eeyan wa, wá sí ìmusẹ.

"Erongba wa ni lati sọ fasiti tuntun yí di ọkan lara fasiti to da julọ lorilẹede Naijiria."