Ǹ jẹ́ o mọ iye ìgbà tí Super eagles àti Argentina ti pàdé?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ifẹsẹwọnsẹ idije ife ẹyẹ agbaye FIFA ti ọdun 2018 ni yoo jẹ igba kẹfa ti orilẹede Naijiria ati Argentina yoo maa waako ninu idije FIFA fun awọn agbalagba agbabọọlu lagbaye.
Ẹ jẹ ki a wo awọn ifẹsẹwọnsẹ iṣaaju ti awọn ikọ mejeeji yii ti pade
Argentina v Nigeria (2-1)
Ni ọdun 1994 ni ikọ Super Eagles orilẹede Naijiria ọkọ farahan ni idije ife ẹyẹ agbaye ti FIFA, ifẹsẹwọnsẹ keji ti wọn si gba nigba naa jẹ pẹlu ikọ Argentina, eleyi ti gbajugbaja agbabọọlu ni, Diego Maradona ko sodi gẹgẹ bii Balogun.
Lẹyin gbogbo ifagagbaga, Argentina fagba han Super Eagles pẹlu ami ayo meji si ẹyọ kan.
Clemence Westerhof ni olukọni Super eagles ni igba naa nigba ti Peter Rufai jẹ balogun ikọ Super eagles.
Super eagles lo kọkọ gba ayo wọle lati ẹsẹ Samson Siasia ki Claudio Canigia to gba goolu meji wọle pada fun Argentina.
Nigeria v Argentina (0-0)

Oríṣun àwòrán, 11v11.com
Ni ọjọ kẹwa oṣu kini, ọdun 1995 Super Eagles tun pade Argentina ninu idije FIFA Confederations Cup to waye ni ọdun naa, ọmi olodo-odo ni wọn gba nigba naa.
Papa iṣire King Fahd International Stadium ni Riyadh, orilẹede Saudi Arabia ni ifẹsẹwọnsẹ naa ti waye.
Ologbe Shuaibu Amọdu ni olukọni fun ikọ Super Eagles nigba naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Argentina v Nigeria, 02 June 2002 (1-0)
Nigba to di idije ife ẹyẹ agbaye FIFA ni ọdun 2002, ikọ mejeeji tun pade. Oloye Adegboye Onigbinde lo ṣe akọni ikọ Super eagles nigba naa lorilẹede South Korea ati Japan.
Okocha ni balogun ikọ Super Eagles ni asiko yii.
Gabriel Batistuta ni o gba goolu kan ṣoṣo ti Argentina fi gba ogo mọ Super Eagles lọwọ ni ọdun naa nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹtalelọgọta.
Argentina v Nigeria 12 June 2010 (1-0)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọdun 2010 ni ikọ Super eagles ati Argentina tun pade ara wọn ni idije ife ẹyẹ agbaye FIFA to waye lorilẹede South Africa.
Papa iṣire Ellis Park ni ilu Johannesburg ni ifẹsẹwọnsẹ naa ti waye.
Lars Lagerback ni olukọni fun Super eagles nigbati Diego Maradona jẹ olukọni ikọ Argentina.
Gabriel Heinze lo gba bọọlu si awọn Super eagles ni ọjọ naa ni iṣẹju kẹfa ifẹsẹwọnsẹ ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Nigeria v Argentina, 25 June 2014 (2-3)
Goolu meji ọtọọtọ lo waye laarin iṣẹju marun ti ifẹsẹwọnsẹ yii bẹrẹ ni papa iṣire Estadio Beira-Rio lorilẹede Brazil.
Ahmed Musa lo gba ayo meji wọle fun orilẹede Naijiria ni iṣẹju kẹrin ati ikẹtadinlaadọta.
Gbajugbaja agbabọọlu orilẹede Argentina ni, Lionel Messi gba goolu wọle ni iṣẹju kẹta, iṣẹju karuninlaadọta ki marcos Rojo to gba ikẹta wọle fun Argentina nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju aadọta.
Stephen Keshi ni olukọni ikọ Super Eagles ni ọdun naa.












