Argentina Transport Minister: Ọkọ̀ Mínísítà tàkìtì nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé lásìkò ìjì líle

Minisita Mario Meonilasiko ti wọn bura wọle sipo fun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iku omi lo n pomuwẹ,iku ogun lo n pa akikanju, iku oge si ni Yoruba ni a maa pa arẹwa.

Ni orileede Argentina iku to fẹ jọmọ awọn eyi taa sọ ṣaaju yi ṣebẹ pa Minisita feto irina,Mario Meoni, ti o padanu ẹmi rẹ ninu ijamba oju popo.

Iroyin to tẹwa lọwọ sọ pe o kagbako iku ninu ijamba ọkọ lọjọ Ẹti lẹyin abẹwo si ilu Rosario.

Gẹgẹ baa ṣe gbọ, lasiko iji lile kan ni ọkọ rẹ takiti ti o si ṣokunfa iku rẹ.

Atẹjade lati ileeṣẹ iroyin aarẹ nilẹ naa ni oun nikan lo wa ninu ọkọ nigba ti iṣẹlẹ yi waye.

Koda a gbọ pe o ṣẹṣẹ fi ọrọ si oju opo Twitter rẹ pe oun ṣabẹwo pẹlu aarẹ Alberto Fernandez si agbegbe Santa Fe.

Lasiko abẹwo yi, o ni awọn buwọlu iwe adehun lori ibudokọ ẹru ọkọ oju omi, reluwee ati awọn ohun amayedẹrun miran.

Iroyin iku rẹ ti mu ki awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ maa kẹdun iku rẹ ti ọpọ si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi eeyan daa.

Ọ 1965 ni wọn bi nilu Ascencion nibi towa pada ti jẹ oye Mayor laarin ọdun 2003 si 2015.

O fi iyawo ati ọmọ meji saye lọ.