Kano Torture: Inúu gáréèjì ni àwọn ẹlẹ́yinjú àánú ti rí Ahmed tú sílẹ̀

Kano Torture: Inúu gáréèjì ni àwọn ẹlẹ́yinjú àánú ti rí Ahmed tú sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, oTHERS

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano ti fi idaniloju han pe ọdọmọkunrin kan ti wọn timọle fun odidi ọdun meje ninu ile pẹluu mọlẹbi rẹ ti gba itusilẹ bayii.

Iroyin taa gbọ ni wipe wọn ko jẹ ki arakunrin naa tẹ ita fun ọdun meje.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano, Haruna Kiwaya fi aridaju ọrọ naa han fun BBC lowurọ ọjọ ẹti.

Ìdè jáá! Ọmọkùnrin tí bàbá rẹ̀ tì mọ́lé bíi ẹlẹ́wọ̀n f'ọ́dún méje ní Kano gba ìtúsílẹ̀!

Oríṣun àwòrán, oTHERS

Fidio bi wọn ṣe tu ọmọkunrin naa silẹ gbode kan kaakiri ayelujara bii ina to n ran kiri.

Ninu fidio naa, a ri i bi awọn kan ṣe gbe e ti wọn gbe e sinu ọkọ ọlọpaa ti wọn si gbe e lọ nigba ti awọn toku taa ri ti wọn n ba a sọrọ n fihan pe inu wọn dun.

A ri i ọmọkunrin náà tó ti kegungun ti gbogbo egungun ara rẹ han sita.

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii ri idanilojuu ọjọ ori rẹ ṣugbọn awọn ohun ti a mọ ni pe o ṣeeṣe ko kere to ọmọ ogun ọdun.

Iṣẹlẹ yii waye lọjọ kan lẹyin ti awọn ọlọpaa lọ fi ẹsun kan baba ọmọ naa ni ilu Birnin Kebbi lọjọ aiku ọsẹ eyi ti iyawo rẹ sọ pe oun lo de e mọlẹ.

Ẹwẹ, Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Kano ti ni ki wọn gbe ọrọ naa lọ si ọfiisi awọn ọtẹlẹmuyẹ ipinlẹ (SCID) fun itẹsiwaju iwadii.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita lọjọ Ẹti lẹyin ti wọn sọ fun BBC pe ootọ lo ṣẹlẹ, wọn ni awọn ti gba ipe nipa ọrọ na ni ọjọbọ, ni nkan bi agogo mọkanla kọja iṣẹgun mẹẹdogun pe ọkunrin kan to n jẹ Aminu Farawa ti ọmọ rẹ ọkunrin mọle.

Ọmọ naa wa ninu gareeji ọkọ fun ọdun meje lai si ounjẹ kan saan tabi itọju fun ilera.

Kano Torture: Inúu gáréèjì ni àwọn ẹlẹ́yinjú àánú ti rí Ahmed tú sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, others

Atẹjade naa sọ pe nigba naa ni ikọ kan to n jẹ "Operation Puff-Ader toju bọ ọrọ naa.

"Wọn ri ọmọkunrin naa doola ti wọn si sare gbe e lọ si ile iwosan akọṣẹmọṣẹ Murtala Muhammed Kano Specialist Hospital". Nibayii, ọwọ ti tẹ baba rẹ gẹgẹ bi atẹjade ọhun ṣe sọ.

Àkọlé fídíò, Risikat Moromoke Azeez: Inú èmí àti Òbí mi dùn nígbà ti Risi bí ọmọ olójú búlù- Wasiu

Itọpinpin ti wọn ṣe ṣaaju fihan pe baba Ahmed sọ pe oun ko jẹbi ẹsun naa nígbà ti ti wọn ti dajọ ẹwọn ọdun mẹta fun un.

Kọmiṣana ọlọpaa Kano, Habu A. Sani ti wa paṣẹ pe ki wọn gbe ẹjọ naa re lọ si ọfiisi awọn ọtẹlẹmuyẹ.

Lẹta

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Àtẹjade ilé iṣẹ́ ọlọpàá rèé