Imoyosola Adetoro: Àwọn èèyàn sọ fún ìyàwó mi pé mo ti jẹ́ẹ̀jẹ́ nínú awo pé ń kò ní bímọ

Àkọlé fídíò, Imoyosola Adetoro: Àwọn èèyàn sọ fún ìyàwó mi pé mo ti jẹ́ẹ̀jẹ́ nínú awo pé ń kò ní bímọ

Ilẹ aanu Oluwa kii su, bẹẹ ni ọrọ ri fun Imoyosola Adetoro ati aya rẹ, Tejumade lasiko ti Ọba oke da wọn lohun, ti wọn si bi ọmọ lẹyin idaduro ọdun mẹjọ.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Imoyosola salaye pe oun ko tiẹ mọ boya ki oun maa sunkun ni tabi maa rẹrin nigba ti oun gbọ pe iyawo oun bimọ saye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ọpọ eeyan lo ti sọ isọkusọ fun iyawo oun pe oun ko lee bimọ nitori oun ti da majẹmu ninu ẹgbẹ awo ti oun wa pe oun ko ni bimọ.

Imoyosola ni oun ati birikila to kọ ile oun lawọn jọ se igbeyawo ni ọjọ kannaa, ti onitọun si maa n pada ko ọms wa ba oun sere nile, eyi to maa n fa ironu fun oun.

Tejumade, tii se aya Imoyosola naa salaye pe ọpọ eeyan lo ti gba oun ni imọran lati na ẹsẹ sita lasiko ti oun n wa ọmọ amọ oun dupẹ pe oun ko se isekuse.

O ni oun maa n sa fun iya to bi oun lọmọ ni nitori pe ẹkun lo maa n sun nigba to ba fi oju kan oun nitoripe oun ko tii bimọ.

Awọn mejeeji wa gba awọn eeyan nimọran lati yee gba awọn to ba n woju Ọlọrun ni imọran buruku.