RCCG Virtual Convention: Kátàkárà mẹ́wàá tí yóò pàdánù àìsí ìpéjọpọ̀ ńlá RCCG lọ́dún yìí

Oríṣun àwòrán, RCCG
Awọn agba maa n sọ pe ọdọọdun laa rorogbo, ọdọọdun laa rawusa Ṣugbọn atawusa atorogbo, ko seyi taa ri ninu awọn eto kọọkan to maa n waye lọdọọdun o - "Coro" lo fa a.
Ọkan lara iru eto bẹẹ ni ipade adura nla ti ijọ Irapada, RCCG to maa n waye ni ipagọ nla wọn to wa mi Kilomita 36, opopona Eko si Ibadan lorilẹede Naijiria.
Òdú ni ipejọpọ nla ijọ Redeem Christian Church of God eyi ti ilumọọka ojiṣẹ Ọlọrun, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye n dari.
Bi eto yii ba ti bẹrẹ, awọn eeyan maa n peju pesẹ si ipagọ RCCG yii lojukoroju ni ṣugbọn asiko Covid-19 yii, ijọba ti kede pe ile ijọsin kankan ko gbudọ korajọ ti Pasitọ Adeboye naa si sọ fun awọn ọmọ ijọ pe ko ni si ipade adura nla ojukoroju lọdun yii afi lori amohunmaworan ati lori ayelujara.

Oríṣun àwòrán, RCCG
Lọdọọdun nigbakuugba ti eto yii ba n waye, ṣuaaa lẹ o ri ero afi bi omi ninu ilu nla ti wọn n pe ni Redeem Camp. Ọna kii gba ẹsẹ tori pe lati kaakiri agbaye lawọn eeyan ti maa n wa fun ipade adura naa.
Bẹẹ naa si ni awọn ontaja ti maa n foju sọna de asiko yii lati wọ́ owo lọle pẹlu oniruuru nkan ti wọn ba n ta.
Ẹwẹ, Coronavirus ti kọ oju gbogbo awọn ọlọja to maa n taja lasiko naa soorun alẹ bayii gẹgẹ bi ko ṣe ni si ipejọpọ ipade adura naa lojukoroju lọdun yii.
Yoo ya yin lẹnu iru awọn owo yii to kogba wọle lọsẹ kini, oṣu kẹjọ ọdun 2020:
Bọọsi/Ọkọ ofurufu
Ọlọkọ/Agbero: Wọle pẹlu ṣenji ẹ o, N1500 lọkọ, wọle pẹlu ṣenji ẹ o.

Ko si idunadura kankan lori iye owo tẹẹ maa wọ ọkọ lọ si ilu Mowe nibi ti ipagọ ijọ RCCG naa wa. Koda ọtọ ni ibi ti awọn mii n lọ ni Mowe ṣugbọn awọn ọlọkọ maa n saba lo ọla pe ipade adura yii wa ti wn si mọ pe ero pupọ ni yoo lọ ibẹ lati dede gbe owo le iye ti wọn n gbe ọkọ tẹlẹ ni iye to ba wu wọn. Ṣaaju ipade adura yii, o pọju rara aa ri iru ẹ ri, kii ju N350 lọ ti wọn maa n gbe e.
Pabanbari lasiko yii ni ti sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ to maa n waye paapaa lọjọ ti eto naa yoo pari tii ṣe ọjọ ẹti. Ẹni to ba ti bọ sọna lati bii ọwọ ọsan ti ko tete ji kuro nile yala latinu ilu Eko ni tabi lati bii Ibada ati ipinlẹ Ogun, ko si ani ani yoo ko sinu sunkẹrẹ fakẹrẹ lawọn oju popo to ba dari si Redemption Camp.
Bakan naa,ọrọ bii PortHarcourt-Lagos, Abia-Lagos, Kaduna-Lagos, lẹ o maa gbọ bẹẹ ba lọ si ibudokọ tẹẹ tun fẹ rinrinajo lọ si ipinlẹ miiran lorilẹede Naijiria, gbogbo awọn baalu lo ti maa n kun fọfọ tori awọn ọmọ ijọ Reedemu ti n tẹ gbogbo ọkọ leti wa si Eko.
Pọfu Pọọfu atawọn ipanu mii

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yoo ya yin lẹnu pe awọn nkan to ṣee wọn sẹnu lai fi akoko ṣofo maa n ta daadaa lasiko ipade adura yii. Awọn ounjẹ ti wọn fi iyẹfun ṣe bii Pọfu Pọọfu, Shin Shin, Bisiki Panbolabola atawọn jijẹ ati eso mii to ba wa lode.
Buka/ile ounjẹ igbalode/omi/ọti ẹlẹrindodo
Bẹẹ ba fẹ we ọwọ ounjẹ okele, jantirẹrẹ lawọn ile ounjẹ wa ni aaye ti wọn ya sọtọ fun itaja. Bo ba si jẹ awọn ounjẹ koya koya naa ni, ẹ o ba a nibẹ. Koda omi ati ọti ẹlẹrindodo kii ṣee ka, ibikibi lẹ ti le ri wọn ra.
Ẹgba ọwọ onirọba
Ara awọn nkan idamọ tẹẹ le fi mọ awọn to lọ fun ipade adura yii ni ẹgba ọwọ Wrist Band ti wọn maa n tẹ ọrọ adura, ọrọ bibeli tabi akori ipade adura naa si. O maa n ta wara wara gan ni to si jẹ na ati pa owo wọle gidi gan fun awọn to n ta a.
Iwe/Rẹkọọdu iwaasu Baba Adeboye ati orin Kristẹni
Ẹ o le ṣe kẹẹ ma ri awọn iwe ti Pasitọ Adeboye atawọn ojiṣẹ Ọlọrun miiran to fi mọ rẹkọọdu iwaasu tabi awn orin ẹmi ati ere agbelewo ẹsin Kristẹni lori igba kaakiri ayika ipagọ naa.
Fila/Atẹ ori awọn obinrin

Oríṣun àwòrán, RCCG
Kẹti kẹti lawọn obinrin maa n ya lọdọ awọn onifila tori ọpọlọpọ lo mọ pe awọn gbudo bo ori wọn lati gbadura. Amọ awọn mii kan ṣaa fẹ ra a lọle gẹgẹ bii t'Eko bọ fun ara wọn tabi ẹlomii.
Keke Alupupu
Ọna pataki kan lati rinrinajo kaakiri inu ipagọ ijọ Redeem ni kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta tabi awọn ọkọ kuukuku. Awọn oniṣowo mii to maa n pawo lasiko ipade adura yii ree gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe maa n dura lati wọ wọn lọ sibi ipejọpọ.
Banki/ẹrọ ilewọ ipọowo(POS)
Lati igba ti ipagọ naa ti n fẹ sii titi to ti di ilu nlaa Redemption City ni awọn alaṣẹ ijọ ti faaye gba ki awọn ileeṣ kọọkan wa maa ṣiṣẹ nib eyi ti yoo maye rọrun fun awọn olugbe ibẹ to bẹẹ ti wn ko ni nilo ati jade maa wa ohun ti wọn ba nilo kiri. Lara wọn ni Banki, NEPA, Ileewosan ati bẹẹ bẹẹ lọ eyi to si maa n wulo gidi gan lasiko ipade adura ọlọdọọdun.
Awọn to n ṣa ike rọba
Gbogbo ike omi ati ọti ẹlẹrindodo ti awọn eeyan ba mu kii ṣofo bẹẹ si ni kii dọti ilẹẹlẹ inu ipagọ. Lasiko gbogbo ipade adura to ba waye lẹ o ti ri awn to n rin yika lati ba a yin ko gbogbo ike omi ati ti ẹlẹrindodo ti ẹ ba mu ko da ẹ lee ma nilo lati dide laye yin lọ ju u nu bẹẹ ba duro diẹ.
Ẹlẹni/ibusun alagbeka
Nitoriipe ọpọlọpọ awọn mii lo maa n lọ alọsun. Awọn a tilẹ ti de sibẹ lati ọsẹ kan tabi ju bẹ lọ tori wọn ti maa n bẹrẹ awọn eto aṣaaju mii ko to di ọjọ aṣekagba. Fun idi eyi awọn eeyan maa n nilo ohun ti wn lee fi sun.
Gbogbo awọn oniṣowo yii atawọn mii ni ko ba ti maa wọ́'wó to ba ṣe pe ipade adura naa waye lojukoroju lonii ṣugbọn ori amohunmaworan ijọ naa ati lori ayelujara nikan lo ti n waye.














