NURTW Ondo: Ọ̀pọ̀ èrò ní Akure fi ayọ́ hàn bí Aketi ṣe ni kí NURTW lọ sinmi
Ijọba to ni ki NURTW lọ sinmi ni Ondo mọ nakn ti wọn n ṣe- Wasiu Awakọ Owó Taxi ní ìpínlẹ̀ Ondo tí padà sí N50 látí N100 nítorí kò sí gbígba ''tíkẹ́ẹ̀tì'' NURTW mọ́
Awọn eniyan nipinlẹ Ondo ti fi idunnu wọn han lori lẹyin ti awọn awakọ din owo ọkọ ku kaakiri ipinlẹ naa.
Eyi ko ṣẹyin bi ijọba gomina Akeredolu ṣe fofin de ẹgbẹ awọn NURTW nipinlẹ naa.
Akọroyin BBC to kaakiri ilu Akure laarọ oni ni awọn awakọ Taxi ati awọn eniyan to n wọ inu ọkọ fi idunnu wọn han lori igbese ijọba naa.

''Owo ọkọ irinajo kekere to jẹ ọgrun naira tẹlẹ ti da aadọta naira laarọ oni''
''Amọ awọn agbegbe to jina naa ni wọn n gbe ni ọgọrin naira si ọgọrun un naira''
''Inu awọn awakọ taxi ati awọn ọlọkada dun nitori wọn ko san owo ''tikẹẹti'' mọ ni ilu Akure''
''Amọ, awọn awakọ ni garagi fi aidunnu wọn han nitori ibanujẹ lo jẹ fun wọn''

Ọkan ninu awọn awakọ to ba BBC sọrọ ni igbesẹ ijọba ti gba ounjẹ lẹnu awọn nitori ọpọlọpọ ni wọn n jẹ lara ẹgbẹ NURTW naa.
Bakan naa ni wọn sọ wi pe oṣeeṣẹ ki wahala ati iwa ọdaran posi ni igboro nigba ti ọpọ eniyan ko ba ri iṣẹ ṣe mọ.

Amọ, ijọba ni awọn ajọ NURTW ko pa owo wọle fun ijọba, eleyii to mu wọn gbe igbeṣẹ naa.

A ti wi pe awọn ẹgbẹ naa ma n gbe ijọba kalẹ fun awọn ẹlomiran, ti ijọba tuntun ba ti wọle ni ipinlẹ naa, eleyii ti o ma n mu ẹmi ọpọ eniyan lọ nitori rogbodiyan to ma n waye lasiko igbajọba lọwọ ara wọn
- Àwọn aṣòfin àgbà buwọ́lu orúkọ àwọn olórí ológun tuntun
- Ọ̀jọ̀gbọ́n Ijeoma ní òun kìí ṣe ọmọ Nàìjíríà mọ́, South Africa tó yàn dípò bá tún lé e jáde
- Abẹ́rẹ́ àjẹsára, Covid 19 ti balẹ̀ bàgẹ̀ sí orílẹ̀èdè Naijiria
- Iléeṣẹ́ ọmọ ogun ti fi akọ̀ròyìn BBC kan sí àtìmọ́lẹ́
- Mò ń bẹ Ọlọ́run pé kí ìdàgbàsókè Nàíjíríà ṣojú ẹ̀mí mi - Obasanjo