Wo arábìnrin tó ń pèsé àǹfàní ẹ̀kọ́ fún àwọn ọmọ tí kò lọ́ sí iléẹ̀kọ́ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà
Ni ọdun 2018 ni Omidan Prayer Nwagbaso gba lẹtọ fun isinruulu rẹ ni ipinlẹ Plateau lẹkun aringbungbun ariwa orilẹede Naijiria.
Nigba to de ibudo agunbanirọ rẹ lo rii pe pupọ awọn ọmọ to yẹ ko wa ni ile ẹkọ ni wọn n rin regberegbe kiri lai si ohun kan ti wọn n ṣe ni pato.
Ipinlẹ Plateau wa lara awọn ipinlẹ ti iṣẹlẹ ikọlu ija ọjọ pipẹ ati ikọlu awọn agbebọn ti gbilẹ julọ lorilẹede Naijiria.
Ọpọ igba ni wahala laarin awọn agbẹ ati awọn darandaran Fulani ti maa n waye lori iṣakoso awọn ohun elo pataki bii omi ati ilẹ oko.
Ọkẹ aimoye ẹmi lo ti ku ti omilẹgbẹ miran ko si ni ile lori wọn mọ, ti o si din anfani eto ẹkọ fun awọn ewe ku.
Kí ni akọsilẹ sọ nipa awọn ọmọ ti ko lọ si ile ẹkọ ni Naijiria
Orilẹede Naijiria lawọn ọmọde ti ko lanfani lati lọ si ile ẹkọ pọ si julọ lagbaye, gẹgẹ bi akọsilẹ kan ti aj amojuto awọn ewe lagbaye, UNICEF fi sita lọdun 2018.
Nnkan bii miliọnu mẹwaa abọ awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun marun un si mẹrinla ni ko si nile ẹkọ lorilẹede Naijiria.
Ilaji awọn ọmọde wọnyii lo si jẹ pe ẹkun ariwa orilẹede Naijiria ni wọn wa.
















