Arsenal vs Burnley: Kí ló kàn fún Arsenal báyìí lẹ́yìn tí Burnley yẹ̀yẹ́ wọn mọ́lé ní Emirates?

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọkan lara adilemu fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Kieran Tierney ti sọ pe o yẹ kawọn ololufẹ ikọ agbabọọlu naa yẹyẹ wọn gẹgẹ bi wọn ti ṣe lẹyin ti Burnley lu wọn mọle pẹlu ami ayo kan sodo ninu idije Premier League lọjọ Aiku.
O buru debi wi pe balogun Arsenal, Pierre-Emerick Aubameyang gan an lo ṣeeṣi gba goolu kan ṣoṣo tiu Burnley fi bori wọlẹ Arsenal.
Ni bayii, Arsenal ti fidi rẹmi ninu meje ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹwaa ti wọn ti gba bayii.
- Àṣeyọrí Anthony Joshua fi hàn pé owó tí à ń ná lórí eré ìdarayá kò lọ lásán - Dapo Abiodun
- Ohun mẹ́wàá pàtàkì nípa Maradona àti ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ẹlẹ́sẹ̀ ayò Diego Costa rèé
- Lóòtọ́ ni mo yìnbọn níbi yánpọnyánrin tó wáyé ládúgbò mi-Seun Kuti
- Wo àwọn Ọba aládé méje tó jẹ́ obìnrin nílẹ̀ Yorùbá
- Mi ò le tòṣì láéláé! Ẹni tó bá ń bínú kàn ń bínú lásán ni- Oyedepo
- Wo àwọn ohun tí Amotekun kò ní le è ṣe mọ́ ní ìpínlẹ̀ Oyo...
Ẹgbẹrun meji ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal to wo ere bọọlu naa lo fi aidunnu wọn han sawọn agbabọọlu ati akọnimọọgba wọn, Mikel Arteta lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa.
Tierney sọ lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa pe igbiyanju awọn agbabọọlu Arsenal lori papa kudiẹ kaato.
Igba akọkọ ree ti Arsenal yoo fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrin lera lera nile wọn lati bii ọdun mọkanlelọgọta.
Pẹlu bi wọn ti bori ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrin ninu mejila ti wọn ti gba a, o ti pe ọdun marunlelogoji bayii ti ibẹrẹ saa bọọlu tuntun ti buru jai fun Arsenal bayii.

Oríṣun àwòrán, EPA
Goolu mẹwaa ti wọn gba sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mejila ti wọn ti gba ni saa bọọlu yii lo kere julọ fun Arsenal lati ọdun 1982.
Lati oṣu kejila ọdun 2019 ti Arteta ti di akọnimọọgba Arsenal, awọn agbabọọlu rẹ ti kaadi pupa mẹfa.
Iwa aibikita bẹẹ naa lo mi ki Granit Xhaka gba kaadi pupa ti wọn fi le danu ninu ifẹsẹwọnsẹ ọjọ Aiku lẹyin to fẹ fun agbabọọlu Burnley, Ashley Westwood lọrun.












