Brighton vs Arsenal: Ọmọ Otedola bú sẹ́kún lẹ́yìn tí Brighton tún d'ẹrù ìyà lé Arsenal lórí

Oríṣun àwòrán, Instagram/cuppymusic
Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti ba ọpọlọpọ ololufẹ wọn ninu jẹ lẹyin ti Brighton ti ẹyin gbe ru wọn ninu idije liigi Premier League ti wọn gba lọjọ Abamẹta.
L'Ọjọru ni Arsenal kọkọ fi iya ṣide idije naa lẹyin ti Premier League bẹrẹ lẹyin isinmi ọlọjọ gbọọrọ nitori coronavirus.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Manchester City lo kọkọ ki bẹbdẹ si Arsenal ninu, ami ayo mẹta si odo ni wọn fi lu wọn bi aṣọ ofi.
Ọpọ awọn ololufẹ wọn lo ti n sọ pe o yẹ ki Arsenal le na Brighton nigba ti wọn ba pade.
Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ nigba ti Brighton fi pọnmọ kun pọnmọ pọnmọ ete awọn Gunners pẹlu ayo meji si ẹyọkan.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Koda aifakọyọ naa ti gbomi loju ọkan lara awọn ololufẹ Arsenal Florence Otedola ti ọpọ mọ si DJ Cuppy.
Cuppy fi sori oju opo Twitter ati Instagram rẹ pe oun ti jawee fun Arsenal lẹyin ọdun mẹfa to ti n tẹle ikọ agbabọọlu naa.
O ni oun ko tii mọ ẹgbẹ agbabọọlu tuntun ti oun yoo maa tẹ le bayii, ṣugbọn o ti tan laarin oun ati Arsenal.
Brighton vs Arsenal: Dákúdájí Arsenal tún paná pii lẹ́ẹ̀kan síi nílé Brighton
Ajẹkun iya ni ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal tun jẹ ninu idije Premier League lẹyin ti Brighton din dodo iya fun wọn ninu ifẹsẹwọnsẹ keji ti wọn gba lati igba ti Premier League ti bẹrẹ pada.
Manchester City lo kọkọ lu Gunners ni alubami lẹyin ti wọn lu wọn pẹlu goolu mẹta eyi ti Arsenal ko si lee ta putu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ lo ti kọkọ ro pe Arsenal yoo jẹri ara wọn lọjọ Abamẹta nigba ti wọn ba koju Brighton, ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ ninu ere bọọlu ọhun.
Manchester city kọ lẹ́tà ìyà, Arsenal ló tẹ́wọ́ gbàá ní Etihad
Iya o to 'ya afada pakun, ikun salọ ada tun sọnu ni ọrọ jẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal laṣalẹ ọjọru nigba ti wọn pada sori papa ni itẹsiwaju idije liigi premiership ilẹ Gẹẹsi ti wọn so rọ fun nnkan bii ọgọrun ọjọ nitori ajakalẹ arun coronavirus lagbaye.
Ikọ Manchester city ni Arsenal koju, goolu mẹta ti ko ṣee bomi la ni wọn si fi bori Arsenal.
Esi ifẹsẹwọnsẹ yii ko jẹ iyalẹnu fun ọpọ onwoye ere bọọẹu lagbaye, paapaa idije liigi Premiership.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amọṣa, ọrọ agbabọọlu ọwọ ẹyin fun Arsenal, iyẹn David Luiz ni ọpọlọpọ mu bs ẹnu lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa.
Yatọ si pe oun lo ṣokunfa meji ninu goolu mẹta ti Manchester city fi gbẹyẹ mọ Arsenal lọwọ, oun naa ni agbabọọlu Arsenal to gba kaadi pupa eyi to tums si pe rẹfiri ni ko wabigba kuro lori papa.
Ni ipele kini ifẹsẹwọnsẹ naa ni aṣiṣe David Luiz ti kọkọ ṣakoba fun Arsena nigba to fara gbe bọọlu to yẹ ko gba danu sọwọ Raheem Sterling agbabọọlu Manchester city ti tọun si kanra gba bọọlu naa sawọn.
Ni abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa lo tun ti fa aṣọ Riyadh Mahrez to jẹ agbabọọlu Mancity ti rẹfiri si fọn fere fun pẹnariti ti o si tun fun un ni kaadi pupa pe ko jade kuro lori papa.
Luiz kii ṣe ajeji si irufẹ awsn aṣiṣẹ epo n biyọ bayii to si ti mu ki ọpọlọpọ onwoye bọọlu o maa pe fun ori rẹ.
Pẹlu jijawe olubori yii, O tunmọ si pe ami mẹfa lo n dabu ẹgbẹ agbabọọẹu Liverpool bayii lojuna ati gba ife ẹyẹ Premiership ti saa yii.












