Lójú mi ni àwọn agbébọn ti ṣekúpa Bàbá mi - Teni Apata

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/TENI ati BOOMPLAY
Gbajugbaja olorin Takasufe, Teniola Apata ti sọrọ lori bi awọn agbebọn ṣe ṣekupa Baba rẹ, Simeon Apata, ajagun fẹyinti ni isoju awọn ọmọ ati mọlẹ.
Ọgagun Apata ni awọn agbebọn ṣekupa lọjọ kẹjọ kẹjọ, oṣu kinni ọdun 1995 niluu Eko.
Teni salaye pe ọmọ ọdun meji ni oun lasiko ti isẹlẹ naa waye ni yara palọ ni ile wọn.
O ni ọpọlọpọ nnkan ti isẹlẹ ti fa si oun lara, to si ṣe akoba nla fun igbe aye rẹ.
TenI sọrọ lasiko to n ba Temisan Ahwieh sọrọ lori eto ayelujara kan.
“Eeyan to ko gba igbakugba ni Baba mi, ologun ni, to si tun ni ile ẹkọ; Apata Memorial High School, to si tun ma ran awọn eeyan lọwọ.
“Ọmọde to padanu Baba rẹ ni ibẹrẹ aye rẹ ṣe ọpọlọpọ akoba fun mi. Ẹ mọ , wọn ṣekupa Baba mi loju gbogbo awa ọmọ ni. Ọmọ ọdun meji ni mi lasiko naa,
“Isẹlẹ naa ko jẹ ki n ni anfani lati ni ipa Baba. Eyi ni ko jẹ ki fi gbogbo ara tan eeyan nitori awọn agbebọn didi wa si ile wa lati ṣekuopa Baba mi.
Tani Simeon Apata?

Oríṣun àwòrán, BOOMPLAY
Ọmọ bibi ipinlẹ Ekiti ni Ọgagun Simeon Olaosebikan Apata lati Ilejemeje niluu Iye-Ekiti.
O jẹ Baba fun gbajugbaja olorin takasufe, Teniola ati Niniola Apata
Oun ni oludasilẹ ile ẹkọ Apata Memorial High School silẹ lọdun 1980.
Awọn agbebọn kan yabo ile Apata lọjọ kẹjọ oṣu kinni ọdun 1995, ti wọn si ṣekupa .
Isẹlẹ lo ba ọpọlọpọ ninu jẹ paapa nipinlẹ Eko.












