Àlàyé rèé lórí fọ́nrán fídíò tó ṣàfihàn ẹ̀kun omi lórí afárá Thirdmainland

- Author, Chiagozie Nwonwu
- Role, Senior Journalist WSL Disinformation Unit
A tun de pẹlu atupalẹ iroyin ofege to n ja rain lawujọ.
Lonii, a ṣe iwadii lori iroyin kan nipa ẹkun omi lori afara ThirdMainland nilu Eko.
Iroyin yi jẹyọ latara fido iṣẹju aaya mẹtala kan to gbode ti ẹka to n tọpinpin iroyin ofege BBC sọ pe eeyan kan pin loju opo Twitter ni ago mẹjọ kọja iṣẹju mẹẹdogun lalẹ ọjọ Kọkanlelogun oṣu Kẹwaa 2021.
Ninu fidio naa, eeyan naa ya fọnran yi lati inu ọkọ lori afara Thridmainland eyi to jẹ ko dabi pe ẹkun omi waye.
Ki wa lo de tawọn eeyan fi ṣalabapin fidok yi?
Ko sẹyin ipenija ẹkun omi ti awọn ipinlẹ Naijiria to wa leti bebe omi odo ọya n koju.
O to eeyan ẹgbẹta ti ẹkun omi yi ti mu ẹmi wọn lọ ti ọpọ dukia si ṣofo.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Adẹrinposonu nii Williams Uchemba naa fi ọrọ sita pẹlu fidio afra yi pe omi ọsa ti kun de ẹnu afara naa.
Bakan naa ni ọrọ ti eeyan kan fi ṣọwọ ni Facebook n fi ọwọ sọya pe aworan kan laipẹ yi fihan pe ''omi ọsa ti fẹ ẹ kunde eti afara naa''

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ọrọ ti awọn eeyan yi kọ ko fi ẹri kankan ṣọwọ tohun ti pe wọn n fẹsun kan pe omi ti fẹrẹ kan afara loke.
Ẹwẹ, iwadii taa ṣe fihan pe eti bebe afara ni isalẹ ni omi yi de.
Atupalẹ aworan yi taa tun ṣe fihan pe kii ṣe aworan to ṣẹṣẹ jade bi kii ṣe pe o ti jade tipẹ ninu iroyin kan lati ọdun 2020 to ni nkan ṣe pẹlu afara Third Mainland yi.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ikọ BBC to n ṣatupalẹ iroyin ẹlẹjẹ ṣabẹwo taa si rin kọja lori ati labẹ afara yi ti o si han si wa pe omi ko ti kọja isalẹ afara naa.
Awọn aworan taa fi si isalẹ yi jẹ eleyi taa ya ni ọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹwaa 2022 ni nkan bi ago mẹwaa owurọ.
O ṣafihan kedere bi afara naa ti ṣe ri.


Iroyin ẹlẹje yi ja ọpọ eeyan laya loju opo ayelujara ti wọn si bẹrẹ si ni paya lori ẹkun omi to n bọ.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Eons Intelligence
Kọmiṣana Ileeṣẹ ton risi ọrọ ayika nipinlẹ Eko Tunji Bello sọ pe ki awn eeyan apa kan ni Eko maa palẹmọ ẹkun omi toi si ni ki wọn kiyesara.
Ṣaaju ni ijọba kede pe ẹkun omi le waye paap fawọn ton gbe lẹgbẹ odo Ogun.
Awọn agbegbe yi kii ṣe alejo ẹkun omi lọdọọdun.












