Peter Obi máa fojú ba ilé ẹjọ́ nítorí àwòrán ọmọ tó lò fi ṣe ìpolongo l'Eko- Ajàfẹ́tọ̀ọ́

Oríṣun àwòrán, Peter Obi
Eekan agbaṣaga kan, Wale Ojo-Lanre ti pe oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi lẹjọ fun lilo ọmọde jojolo fun ipolongo ibo rẹ nilu Eko.
Ọgbẹni Ojo-Lanre tọ ile ẹjọ gbẹbiro kan to wa lẹkun Ikẹja nilu Eko lọ nibẹ lo si ti pe Obi lẹjọ gẹgẹ bi “Ọmọ Naijiria rere ati ọrẹ abanigbọnyanu” fun ọmọde jojolo naa.
Awọn miran to so pọ mọ ẹjọ naa ni ẹgbẹ oṣelu Labour Party, arabinrin Queen to jẹ iya ọmọ naa, ijọba apapọ ati agbẹjọro agba fun orilẹede Naijiria.
Agbaṣaga naa n fẹ ki ile ẹjọ paṣẹ ki wọn san aadọta miliọnu naira gẹgẹ bi owo itanran fun titẹ ẹtọ ọmọde jojolo naa mọlẹ.
Gẹgẹ bi ọgbẹni Wale-Ojo Lanre ṣe sọ, ohun ti ko bofinmu ni, iwa ifini ṣe iṣe aitọ si ni pẹlu fun oludije ẹgbẹ oṣelu Labour lati l maa fi fido ọmọde jojolo naa si ori ayelujara loju opo Twitter rẹ gẹgẹbi o ṣe ṣe lọjọ keji ọṣu kẹwaa ọdun 2022 ti o si n pee ni “ọmọ akọmọna” ikọ ipolongo oun.
O ni iya ọmọde jojolo naa tẹ ofin to de ẹtọ ọmọde mọlẹ ti ọdun 1981 labẹ akoso ajọ iṣọkan agbaye mọlẹ
Bakan naa lo tun sọ pe o tako abala ikọkandinlọgbọn ati ikẹtalelọgbọn ofin ẹtọ ọmọde ni ipinlẹ Eko mọlẹ nipa mimu ọmọ naa lọ kopa nibi ipolongo oṣelu eyi to wa fun awọn to ti balaga ni igboro ilu Eko lọjọ kini oṣu kẹwaa ọdun 2022.

Oríṣun àwòrán, @Peter Obi
“A n fẹ ki ile ẹjọ pa aṣẹ pe ki olujẹjọ kini ati ikeji o pa atẹjade gbogbo to niiṣe pẹlu ọmọdebinrin jojolo yii ti wọn fi si oju opo Tweeter wọn atawọn oju opo ayelujara wọn miran rẹ.
“A tun nfẹ ki aṣẹ ile ẹjọ eyi to n kan an nipa fun olujẹjọ kẹrin ati ikarun un lati gba ọmọdebinrin naa kuro lọwọ olujẹjọ kẹta.”
Bakan naa lo ni oun yoo tun rọ ile ẹjọ lati paṣẹ pe ki olujẹjọ keji, iyẹn ẹgbẹ oṣelu Labour maṣe kopa ninu eto idibo ọdun 2023 pẹlu bi o fi aye gba lilo mọde jojolo fun ipolongo ibo rẹ.
O wa fi kun un pe ki ile ẹjọ kan an nipa fun ijọba apapọ ati agbẹjọro agbalorilẹede Naijiria lati gbe igbesẹ ipẹjọ dide lati lati fi panpẹ ofin mu Peter Obi, ẹgbẹ oṣelu Labour pẹlu iya ọmọ naa ki wọn si fi wọn jofin.
Ki lo fa ipẹjọ yii gan an?
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ni ọjọ kini oṣu kẹwaa ọdun 2022 ni aworan ọmọdebinrin jojolo kan lu ori ayelujara pa nibi iwọde ipolongo ibo ti awọn ololufẹ Peter Obi, oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour party kan ṣe nilu Eko.
Nigba to di ọjọ keji oṣu kẹwaa kan naa ni oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu LP naa tun fi fidio rẹ soju opo Twitter rẹ to si ni ọmọ naa ni yoo jẹ ọmọ akọmọna fun ipolongo oun.












