Wo iye àwọn tí yòó jànfàní owó ìrànwọ́ ìdókòwò ₦110bn t'ìjọba fẹ́ ṣe fáwọn ọ̀dọ́

Aworan awọn ọdọ

Oríṣun àwòrán, C2HFOUNDATION

Ijọba apapọ orileede Naijiria ti sọ pe gbogbo eto lo ti to lati bẹrẹ eto iranwọ owo idokowo aadọfa biliọnu naira(N110bn) fun awọn ọdọ.

Owo yii ni ijọba sọ pe ohun fẹẹ fi ṣe iranwọ fun awọn ọdọ ti wọn ni iṣẹ tabi okoowo kereje, ṣugbọn ti wọn ko ni owo lati fi mu-un tẹsiwaju gẹgẹ bi wọn ti n fẹ.

Minisita fọrọ eto ilọsiwaju awọn ọdọ, Ọmọwe Jamila Bio Ibrahim lo sọ eyi di mimọ l’Ọjọbọ, ọsẹ yii niluu Abuja.

Nibẹ ni minisita naa ti sọ pe owo yii wa lara eto ijọba Aare Bọla Tinubu lati ṣe iranwọ fun awọn ọdọ labẹ agbekalẹ to pe ni owo iranwọ idokowo fawọn ọdọ.

Ibrahim sọ pe laipẹ lai jinna, eto owo pinpin naa yoo bẹrẹ.

Ọrọ yii lo si waye lẹyin ti akọwe ijọba Naijiria, Sẹnetọ George Akume sọ Aarẹ Tinubu ti mu ọrọ awọn ọdọ lọkunkundun.

Minisita sọ pe ileeṣẹ oun pẹlu ajọṣepọ banki okoowo agbaye ni wọn yoo ṣagbatẹru pinpin owo ọhun.

O ni orukọ ti awọn fẹẹ sọ eto ọhun ni ‘NextGen’ lati fi gbe okoowo awọn ọdọ dide nipa ẹyawo ati iranwọ lori okoowo wọn.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o ni afojusun awọn ileeṣẹ ijọba kan ni lati mu adinku ba airiṣẹ ṣe awọn, ki wọn si mu ilọsiwaju ba eto idagbasoke awọn ọdọ lati ba ẹgbẹ pe ninu imọ ijinlẹ lagbaye.

Minisita sọ pe “a ti buwọ lu idasilẹ eto iranwọ Aarẹ si awọn ọdọ nipa eto iṣẹ agbẹ ati ọgbin, ṣiṣe ati nini ipa ninu eto imọ ijinlẹ.

“A ti ri awọn146,998 ti wọn ti forukọsilẹ, ti a si fẹ kọ niṣẹ yala nipa iṣẹ ọwọ, eto igbalode, imọ tẹkinọlọji, iṣẹ agbẹ ati idaṣẹsilẹ.”

Bakan naa lo sọ pe awọn ti ṣe atunṣe lori owo iranwọ okoowo naa, ti awọn si ti jẹ ko tun gbooro si ju ti tẹlẹ lọ.

Ẹ maa ranti pe ninu oṣu kẹta, ọdun yii ni igbimọ amuṣẹṣe ijọba apapọ (FEC) buwọ lu biliọnu aadọfa naira lati mu eto National Youth Investment Fund (NYIF) dagbasoke ninu ilana ati eto ti wọn ni fun awọn ọdọ lọdun 2024.

“Fun idi eyi, igbimọ naa tun ti buwọ lu idasilẹ eto iranwọ aarẹ fun awọn ọdọ.”

O fidi rẹ mulẹ pe eto ọhun maa n ṣe daadaa lọpọ igba, paapaa bi iwadii ati ibeere ba n wa pẹlu aṣeyọri rere.

O fi kun ọrọ rẹ pe ẹgbẹrun mẹẹdogun okoowo ni eto ọhun yoo ro lagbara, idaji miliọnu awọn ọdọ ni wọn yoo ri iṣẹ taara, ti awọn ọdọ to le ni miliọnu meji yoo si iṣẹ lati maa fi pawọda, ti wọn yoo si maa ri owo.