Ẹgbẹ́ òṣèlú Ààrẹ South Africa ń fìdí rẹmi nínú ètò ìdìbò fún ìgbà àkọ́kọ́ ní láàrín ọgbọ̀n ọdún

 Cyril Ramaphosa i

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ọkan Aarẹ South Africa, Cyril Ramaphosa ko balẹ mọ bayii lẹyin ti awọn esi ibo gbogbogbo to n wọle n fi han pe o ṣeṣe ki ẹgbẹ oṣelu rẹ, ANC lulẹ ninu idibo naa.

Ni bayii ti gbogbo esi ibo naa fẹ ẹ wọle tan, ṣe ẹgbẹ ANC n fidi rẹmi, koda iye ibo to ni kere ju eyii to ni ninu ibo ti wọn di kọja.

Esi ibo yii ni igba akọkọ ti ẹgbẹ ANC yoo lulẹ ninu ibo gbogbogbo laarin ọgbọn ọdun sẹyin.

Ti gbogbo esi naa ba wọle ti ANC ko si ni iye ibo to yẹ ko ni, o n tumọ si pe ẹgbẹ naa yoo ba ẹgbẹ mii pin iṣejọba.

Ṣaaju ni awọn onimọ nipa eto oṣelu ti kọkọ sọ pe ida marundinlaadọta ibo naa ni ẹgbẹ ọhun yoo ko amọ awọn esi to n jade n fi han ida ogoji oludibo pere lo dibo wọn fun ANC.

Ninu ibo to kọja, esi fi han pe ida oludibo 58% lo dibo fun ANC.

Lati ọdun 1994 ti wọn ti n dibo ijọba awarawa ni South Africa eyii to gbe Nelson Mandela sipo Aarẹ, iye ibo ti ẹgbẹ naa maa n ni ki n din ni ida aadọta.

Amọ laarin ọdun diẹ lawọn eeyan orilẹ-ede naa ti bẹrẹ si n jawọ lẹyin ọgbẹ ọhun latari iwa ajẹbanu, iwa ọdaran to n peleke si ati ainiṣelọwọ awọn ọdọ.

Obinrin kan to kọ lati dibo fun ANC fun igba akọkọ lati ọgbọn ọdun sọ fun BBC pe ẹgbẹ DA loun n dibo fun bayii, igbesẹ naa ko si ṣẹyin ọwọnggo nnkan ati bi ina ijọba ko ṣe ṣe dede.

O ni “esi ibo yii ko tẹ mi lọrun, mo fẹ ki ẹgbẹ naa kuro lori oye, ki a fun ẹlomiran laaye.”

Ẹwẹ, iroyin to n tẹ BBC lọwọ sọ pe aago mẹfa irọlẹ ọjọ Aiku ni esi apapọ ibo naa yoo jade.