Ewu wo ló wà nínú kí ìgbésẹ̀ tí ìjọba fẹ́ gbé máa lu síta kó tó kéde rẹ̀?

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu

Lẹnu ọjọ mẹta yii lawọn oniruru iwe kan bẹrẹ si n jade, eyii ti yoo sọ nipa awọn igbesẹ ti ijkọba fẹ gbe ko to kede rẹ.

Pupọ ninu awọn igbesẹ yii ni ijọba maa n sọ pada sọ pe ko ri bẹẹ tabi ko sọ pe kii ṣe igbesẹ ti oun fẹ gbe.

Apẹrẹ irufẹ awọn iwe bẹe ni iwe kan to sọ pe ijọba fẹ yọ owo ori lori awọn ounjẹ atawọn oogun ti wọn n ko wọle latri oke okun, eyii ti ijọba apapọ ti sọ pe ko ri bẹẹ.

Ẹwẹ, ki ṣe igba akọkọ ree ti awọn iwe nipa igbesẹ ti ijọba fẹ gbe yoo jade.

Fun apẹrẹ, ni ibẹrẹ ọdun yii, iwe kan lu sita ninu eyii ti George Akume, to jẹ akọwe ijọba apapọ ti n bere owo ti iye rẹ to biliọnu kan naira fun igbimọ to n jiroro lori ọrọ owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.

Ninu oṣẹ yii naa ni iwe kan lu sita ninu eyii ti ijọba ti fopin si owo ori lori awọn ounjẹ kan ti wọn n ko wọle lati ilẹ okeere, awọn oogun atawọn nnkan mii.

Lana ode yii ni iroyin tun gbode pe ijọba ti buwọlu N105,000 gẹgẹ bii owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ lẹyin iyanṣẹlodi ẹgbẹ oṣiṣẹ, NLC ati TUC.

Ko pẹ ti iroyin ọhun gbode kan ti ijọba kede pe ahesọ lasan ni iroyin ọhun, ati pe ko ti ọdọ oun wa.

Irufẹ ipa wo ni nnkan bayii yoo ni lara ijọba?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wayi o, ọpọ eeyan lo gbagbọ pe akoba ni yoo jẹ fun ijọba apapọ ti wọn iwe aṣiri nipa igbesẹ to fẹ gbe ba n lu sita bẹẹ.

Eredi ree ti BBC Yoruba fi kan si amofin agba Kayode Ajulọ, lati tan imọlẹ si ipa ti irufẹ igbesẹ bẹẹ yoo ni lara ijọba.

Ajulọ sọ pe ko ni ṣe irufẹ iwe ti araalu ba gbe jade nipa igbesẹ ti ijọba n gbe, irufẹ iwe bẹẹ ko lẹsẹ nilẹ niwọn igba ijọba ba ti ni ko ti ọdọ oun wa.

Agba amofin ọhun sọ siwaju si pe ọrọ ti ijọba ba sọ nipa irufẹ iwe bẹẹ ni ofin kin lẹyin, nitori naa ko le ni ipalara kankan fun ijọba tabi iṣejọba laarin ilu.

O ni “iwe ti ijọba ba pe ni tirẹ lo jẹ tirẹ, eyii to ba sọ pe ko ti ọdọ oun jade wa, bẹẹ gan lo ri, kii ṣe ọrọ to yẹ ki a maa gba gbii ẹni gba igba ọti.

“Nnkankan wa ti wọn pe ni ‘propper custody,’ ti o ba mu iwe to jẹ ti ijọba gan jade amọ ti ko ti proper custody yii wa, ko ṣe itẹwọgba.

“Ko si ipa kankan ti yoo ni ju eyii ti awọn kọlọrọsi to n gbe irufẹ iwe bẹẹ jade n fẹ ko ni lọ, amọ ko si ipa kankan ti yoo ni lara ijọba.

Ajulọ pari ọrọ rẹ pe “Ki o to le sọ pe iwe kankan wa lati ọwọ ijọba o ni lati jẹ ojulowo, eyii ti wọn n pe ni ‘certified true copy’.