Wo ilé ẹ̀kọ́ kan tó ń kọ́ àwọn ọkùnrin láti máa pín iṣẹ́ ilé ṣe pẹ̀lú ìyàwó wọn

Àkọlé fídíò, Wo ilé ẹ̀kọ́ kan tó ń kọ́ àwọn ọkùnrin láti máa pín iṣẹ́ ilé ṣe pẹ̀lú ìyàwó wọn
Wo ilé ẹ̀kọ́ kan tó ń kọ́ àwọn ọkùnrin láti máa pín iṣẹ́ ilé ṣe pẹ̀lú ìyàwó wọn

Ile ẹkọ kan ree ni Bogota lorilẹede Colombia ti wọn ti n kọ awọn ọkunrin bi wọn ṣe le di baba rere ati ọkọ to dara ninu ẹbi wọn.

Ile ẹkọ naa sọ pe kii sẹ gbogbo iṣẹ lo wa fun obinrin nikan.

Akẹkọọ kan nibẹ, Segundo Vargas sọ pe ‘’a ni lati pin gbogbo iṣẹ ko le jẹ ajọṣepọ to dara.’’

Ile ẹkọ Bogota ni afojusun awọn ni kawọn ọkunrin ni ipin ninu itọju ile pẹlu awọn iyawo wọn.

Vargas ni ‘’a n ṣe itọju ọmọ ni ilana ti n ko ni oye rẹ ri.’’

Oscar Sanchez toun naa jẹ akẹkọọ nibẹ sọ pe ‘’eeyan ni lati ni suuru pẹlu awọn ọmọdebinrin.

Bi bẹẹ kọọ, wọn ko ni jẹ ki o ya irun wọn.’’

Ile ẹkọ naa tun sọ pe awọn fẹ yi ero ọpọ eeyan to gbagbọ wi pe awọn ọkunrin nikan lo gbọdọ maa mu wọle pada.

Adari ile ẹkọ naa, Juan David Cortes ni eto ile ẹkọ n ṣe yoo din iṣẹ awọn obinrin ku.

Ẹgbẹẹgbẹrun ọkunrin lo ti kẹkọọ nibẹ.

Akẹkọọ kan tẹlẹri nile ẹkọ naa, Johan Lopez sọ pe ‘’lorilẹede Colombia atawọn ilu mii bii Bogota, idẹyẹsi eeyan nipa iṣẹda wọn wọpọ gidi.

Kii ṣe ohun to boju mu pe awọn eeyan kan lo le ṣe iṣẹ kan tori pe o jọ mọ iṣẹda wọn.

A n fun awọn obinrin ni iṣẹ ile to pọju ṣe, nigba ti awọn ọkunrin naa lagbara lati ṣe iṣẹ ọhun.

Mi o ni iyawo tabi ọmọ, amọ, ohun ti mo n ṣe ni lati fa oju awọn ologbo mọra.

Awọn ologbo yii dabi ọmọ fun mi.’’