Gbas-gbos ní ìpínlẹ̀ Rivers, Ṣé àsìkò tó fún ìjóba láti kéde òfin ìlú òfararọ níbẹ̀ bí?

Fubara and Wike

Oríṣun àwòrán, Fubara/Wike

Lẹyin awuyewuye to n waye nipinlẹ Rivers latari ija agba meji laarin gomina Siminalayi Fubara ati gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Nyesomem Wike, ọpọ araalu lo ti n bere pe ki ijọba kede ofin ilu o fararọ.

Ṣugbọn ṣe ohun to n ṣẹlẹ ni Rivers to ki ijọba kede ilu o fararọ, ati pe ki ni ofin Naijiria gan sọ nipa kikede ilu o fararọ.

Eredi ree ti BBC Yoruba fi kan si amofin kan, Kanmi Ajibola, to tun jẹ aṣofin nipinlẹ Osun lati sọrọ lori ẹni to lagbara lati kede ilu o fararọ, ati pe ṣe ohun to n waye nipinlẹ Rivers ti to ki ijọba kede ilu fararọ.

Ki ni ofin sọ nipa kikede ilu o fararọ?

Abala 305 (3a,b) iwe ofin Naijiria ti wọn kọ lọdun 1999 lo sọrọ nipa kikede ilu o fararọ ati ẹni to lekede rẹ.

Ofin naa ni “Asiko kan ṣoṣo ni Aarẹ lagbara lati kede ilu o fararọ, igba naa ni: ti ogun ba n ja orilẹede, the orilẹede ba wa ninu ewu ogun lati orilẹede mii.”

Abala 305(3,c) sọ pe Aarẹ tun le kede ilu o fararọ ti rugudu ba bẹ silẹ ni orilẹede toba bẹ silẹ lawọn agbegbe ninu norillẹede bẹẹ to fi nilo ki ijọba gbe igbesẹ akin lori rẹ.

Ajibola ni “lakọkọ na, ki ijọba apapọ to le kede ilu o fararọ nipinlẹ kan, o ni lati jẹ pe iṣejọba ti daru mọ ijọba ipinlẹ naa lọwọ, ati pe rogbodiyan ti bẹ silẹ ni ilu naa, eyi ti yoo ṣakoba fun igbeaye ati dukia gbogbo eeyan tabi ọpọ eeyan to ngbe nibẹ.”

O ṣalaye pe labẹ ofin, Aarẹ lo le kede ilu o fararọ.

O sọ siwaju si pe irufẹ rukerudo bayii ko tii waye ni ipinlẹ Rivers, nitori naa, ko si eredi kankan alti fi ikede bẹẹ sita.

Ṣe asiko ti to fun ijọba apapọ lati kede ilu o fararọ nipinlẹ Rivers?

Agbẹjọro naa, to tun jẹ aṣofin sọ pe nnkan to n ṣẹlẹ nipinlẹ Rivers bayii ko tii le to ki ijọba apapọ kede ilu o fararọ nibẹ.

O ni “Wike gan ni eku ẹda to n da alaafia ipinlẹ Rivers ru, o si yẹ ki ijọba apapọ kilọ fun.”

“Ko tii si nnkan to n waye ni Rivers bayii to fi yẹ ki ijọba apapọ kede ilu o fararọ.”