Ẹgbẹ́ àwọn Ìmáàmù Ogbomoso dá sí ìfaǹfà àárín Ìmáàmù àgbà àti Soun, ọ̀rọ̀ bá ibòmíràn yọ

Awuyewuye to n waye laaarin Soun ilu Ogbomoso ati Imaamu agba ilu naa tun ti gba ọna miiran yọ bi igbimọ awọn Alfa ilu naa se ti da si bayii.
Igbimo ẹgbẹ awọn Imaamu ati Alfa ti ilu Ogbomoso ti bu ẹnu atẹ lu ifanfa to n waye laaarin Imam agba ilu ọhun Alhaji Toliat Yusuf Ayilara ati Oba ilu naa, Oba Ghandi Olaoye.
Ẹgbẹ awọn Alfa ati Imaamu Ilu Ogbomoso labẹ isakoso Aarẹ musulumi ilẹ Ogbomoso, AbdulGaniyu Owodunni ninu ifọrọwerọ tí ẹgbẹ naa ṣe pẹlu awọn oniroyin ni gbagede Reacreation Club, lo ti ni, iwa ti Imaamu agba ilu Ogbomoso n hu mu ki aisọkan wa laarin awọn Musulumi ilu Ogbomoso.
Ninu ọrọ apilẹkọ ti Aarẹ musulumi ilu Ogbomoso ka lo ti ran Imam Toliat Yusuf leti wí pe ṣaaju ko to gba lawani gẹgẹ bi Imam agba ilu Ogbomosho ni awọn ẹbi Ayilara ti ń fapa janu wi pe kii ṣe ọmọ ile awọn, nitori naa ipo naa ko tọ si.
Ìlú ló ní mọ́ṣáláṣí, dẹ́kun bíba Ọba lórúkọ jẹ́ - Ààrẹ Mùsùlùmí Ogbomoso fèsì fún Imam àgbà

Oríṣun àwòrán, Others
AbdulGaniyu Owodunni ṣalaye siwaju sii wi pe, gẹgẹ bi Kabba àti Masjid Anabawy ni Mekka ati Meddina ṣe wa labẹ iṣakoso Ọba ilu Saudi naa ni masalasi apapọ ilẹ Ogbomoso wa labẹ isakoso aafin Soun ti ilu Ogbomoso.
O so pe Imam Toliat Yusuf towobọ iwe adehun pẹlu Soun lọjọ to gba lawani gẹgẹ bi Imam Agba ilu ọhun, tọ si ṣeleri lati tẹle ilana ati aṣẹ Soun to de ipo re.
Ninu ọrọ tirẹ, Pakoyi ti ilẹ Ogbomoso, Surajudeen Alimi rọ gbogbo awọn ile iṣe iroyin tó ń gbe ọrọ kubakungbe lori awuyewuye to n lọ lọwọ lati ṣe iwadii ni kikun ṣaaju ki wọn to tẹle ọbọ wọgbẹ.
Alimi ni iyalẹnu lọ jẹ wi ọpọ ẹgbẹ akọroyin ori ẹrọ ayelujara ni wọn ko ṣe iṣẹ wọn bo ṣe yẹ ti wọn n si n si ọpọlọpọ lọna pẹlu awọn iroyin ofegee ti wọn n gbe.
Pakoyi woye wi pe iti ọgẹdẹ ni ọrọ to ń ja nilẹ yii, sugbọn kaka ki Imam Toliat ṣe ohun to yẹ, nisẹ loun fẹsun kan Kabiyesi .
O ni ẹṣin Islam koro oju si ki eeyan ma tẹle adehun ti o ṣe, Alimi ni adehun to wa laarin Imam agba ati Ijokoo Soun ni Toliat Yusuf n tẹ mọlẹ bayii, ti ko si tẹle awọn iwaasu rẹ to pe fun mimu adehun ṣe.
Ti ẹ o ba gbagbe, awuyewuye to n waye laaarin Ṣọun Ogbomọṣọ ati Imaamu agba ilu naa, Sheikh Ayilara bẹrẹ nigba ti imaamu agba naa pe Ṣọun ati igbimọ Ṣọun Ogbomọṣọ lẹjọ lori igbesẹ to ni pe wọn n gbe lati yọ oun nipo.
Lara awọn to wa nibi ipade oniroyin naa ni, Bashorun tí ilẹ Ogbomoso Alimi Amole Shittu, Asoju awọn musulumi ilẹ Ogbomoso Mikhail Bello, Pakoyi ti ilẹ Ogbomoso, Suraju Alimi àti àwọn agba ẹgbẹ ẹṣin Islam Ogbomoso.

Oríṣun àwòrán, Others

Oríṣun àwòrán, Others
Ilé ẹjọ́ sọ̀rọ̀ lórí ìgbésẹ̀ Soun ti Ogbomoso láti yọ Ìmáàmù àgbà nípò

Oríṣun àwòrán, Imam Agba Ogbomoso/Facebook
Ile ẹjọ giga ti ipinlẹ Ọyọ ti paṣẹ ki Ọba Afolabi Ghandi Olaoye, Soun tilu Ogbomoso ati awọn ọmọ igbimọ rẹ lati jawọ ninu igbesẹ yiyọ Imaamu agba tilu naa, Sheikh Teliat Yunus Ayilara kuro nipo.
Tẹẹ ba gbagbe pe, lati bi ọjọ diẹ sẹyin ni awuyewuye ti n waye laarin awọn Ọba Ghandi ati Imaamu Ayilara, lori bi Ọba Alaye naa ti fẹsun kan Imaamu wi pe ko sọ fun oun ko to lọ si Hajj.
Eyi lo fa a ti igbimọ awọn ọdọ musulumi nilu Ogbomoso, fi kọ iwe ẹsun siwaju ile ẹjọ tako Ori ade ọhun ati ikọ afọbajẹ ti oloye Solagbade Otolorin lewaju fun, ki aṣẹ naa to jẹyọ lẹyin o rẹyin.
Ohun tí Ìmáàmù Ogbomoso sọ lórí ìwé ìfisùn tí Soun fi ránṣẹ́ sí i pé ó lọ sí Hajj láì sọ fún Kábíyèsí
Imaamu agba ilu Ogbomọṣọ, Sheikh Taliat Yunus Oluṣina Ayilara ti sọrọ lori iroyin to ni pe Kabiyesi Soun ti ilu Ogbomoso, Ọba Ghandi Ọlaoye, ti fi iwe ifisun ranṣẹ si i pe ko wa ṣalaye ara rẹ lori bi o ṣe rinrinajo lọ si Saudi Arabia fun Hajj lai gba aṣẹ lọwọ Kabiyesi naa.
Sheikh Ayilara sọ fun BBC Yoruba lori foonu wi pe ''gẹgẹ bi ẹni ti o mọ ofin ti ko si gbọdọ fi ọwọ pa ida ofin loju, gbogbo ọrọ to ba wa nile ẹjọ, ẹni to ba loye ko gbọdọ sọ nkankan lori rẹ.
Nitori naa, emi o ni ohun kankan lati sọ lori ọrọ yii titi ti ile ẹjọ yoo fi sọ ohun to yẹ lori rẹ.
Gbogbo ọrọ to ba wa laarin emi ati kabiyesi, aarin wa lo wa, kii ṣe ohun to kan ẹnikan.
Ko si ẹni to le sọ fun mi pe ohun ti emi ati kabiyesi jọ sọ niyii.
Ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, ọrọ wa nile ẹjọ, Ọlọrun yoo tọ ile ẹjọ sọna lati sọ ohun to dara.’’
Ọpọ iwe iroyin lo ti gbe awọn iroyin kan jade wi pe Imaamu Ayilara ti da Soun lohun pe kabiyesi ko laṣẹ lati sọ fun oun pe ki oun wa gbaṣẹ ki oun to le rinrin ajo lọ si Hajj.
Amọ, Sheikh Yunus sọ fun BBC Yoruba pe oun ko ni sọrọ tori ọrọ naa wa nile ẹjọ.
Ṣé lóòtọ́ ni Ṣọ̀ún Ogbomosho fún Ìmáàmù àgbà ìlú náà ní ìwé ìfisùn fún lílọ sí Hajj láì fi tó àfin létí?

Dukuu laarin Ṣọun ilu Ogbomọṣọ ati Imaamu agba ilu naa ko tii da eyi to n mura ati pari o.
Iroyin tuntun ti a n gbọ bayii ni peKabiyesi Ọba Ghandi Ọlaoye ti fi iwe ifisun ranṣẹ si Imaamu agba ilu Ogbomọṣọ, Sheikh Taliat Yunus Oluṣina Ayilara pe ko wa ṣalaye ara rẹ lori bi o ṣe rinrinajo lọ si Saudi Arabia fun Hajj lai gba aṣẹ lọwọ Kabiyesi naa.
Ọrọ o gun laarin Kabiyesi Ṣọun ilu Ogbomọṣọ ati Imaamu agba ilu naa lati asiko diẹ sẹyin.
Ninu iwe ifisun naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ ti eeyan laafin Ṣọun, ti ko fẹ ka darukọ oun, tun fidi rẹ mulẹ, lotitọ ni aafin ilu Ogbomọṣọ fi iwe ranṣẹ si Imaamu agba naa nitori igbesẹ rẹ ọhun tako adehun to wa nilẹ laarin awọn mejeji leyi ti Imaamu agba funra rẹ fọwọ si.
Iwe adehun kan waye ṣiwaju iyansipo Sheikh Ayilara ko to bọ sipo Imaamu agba ilu naa, pe nigbakugba ti o ba fẹ jade tabi rinrinajo kankan ti yoo gbe kuro ni ilu Ogbomọṣọ fun idi yoowu, titi kan awọn ojuṣe ẹsin bii Hajj, o gbọdọ fi to Ṣọun leti.
- Soun Ogbomosho: Ka nípa Sòún Ogbomosho to kọ owó #100 mílíọ̀nù tí ìjọba Makinde ní kó fí tún ààfin ṣé
- Mọ̀ síi nípa àwon Orí Adé Soun tí ìlú Ogbomọṣo tó ti jẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀....
- Lórí ọ̀rọ̀ Ìmáàmù Ogbomosho, àwọn kan ń yarí pé àwọn alágbara ló gbé e sípò, kìí ṣe ọmọ ìdílé t'óyè tọ́ sí
- Ifá kọ́ ló n yan gbogbo Ṣọun Ogbomoso torí náà...
Iwe ifisun naa, eyi ti akọwe aafin ilu Ogbomọṣọ, Ọgbẹni Toyin Ajamu, buwọlu tun yannana rẹ pe, nigba ti o n lọ si irin ajo naa, Immamu Agba naa tun funrarẹ yan ẹni ti yoo maa dele de e gẹgẹ bii adele Imaamu agba ilu Ogbomọṣọ, eyi ti Ṣọun ati igbimọ rẹ tun tọka si pe o tako adehun ti Imaamu agba naa ṣe ko to wọ ipo.
Ki lo fa dukuu laarin Ṣọun Ogbomọṣọ, ati Immamu Ayilara?

Wahala aarin Ṣọun Ogbomọṣọ ati Immamu agba Sheikh Ayilara bẹrẹ nigba ti imaamu agba naa pe Ṣọun ati igbimọ Ṣọun Ogbomọṣọ lẹjọ lori igbesẹ to ni pe wọn n gbe lati yọ oun nipo.
Oun ana lo fi Ayilara jẹ oye Imaamu agba lọdun 2021 ko to waja, eyi ti Imaamu agba naa si n sọ wi pe iyansipo oun ba ilakalẹ gbogbo ilana mu ni ibamu pẹlu ẹsin Islam, ti igbimọ onimimọ nipa ẹsin ni ilu Ogbomọṣọ si fọwọ si i.
Amọṣa ọrọ mii suyọ nigba ti Ọba Afọlabi Ghandi Ọlaoye jẹ gẹgẹ bii Ṣọun tuntun ni ilu Ogbomọṣọ lọdun 2023, to si fariga pẹlu bi Ayilara ṣi ṣe n di ipo mu gẹgẹ bii Imaamu agba ilu naa.
















