Wo ọ̀nà tí ìjọba fẹ́ẹ̀ gbà láti pín 50,000 Naira fún ìdílé 100,000 fún oṣù mẹ́ta

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ bola Tinubu ti buwọlu eto kan ti wọn fi sọri atunṣe Naijiria, ati ipese iranlọwọ fun ẹbi kọọkan ni Naijiria.
Eyi waye nibi ipade igbimọ alaṣẹ l’Ọjọbọ, niluu Abuja.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun aarẹ, Ajuri Ngelale fi sita, afojusun eto naa ni lati mu idagbasoke ba iṣẹ agbẹ, ro ọrọ aje l’agbara, ati lati mu itura kiakia ba ile kọọkan ni Naijiria.
O ni ilana ti ijọba apapọ yoo gbe eto naa gba ni ipese owo ati awọn nnkan amayedẹrun jakejado awọn ẹkun idibo to wa.
“Lara koko gboogi to wa ninu alakalẹ eto naa ni pe ijọba bu ọwọ lu fifun ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un ile, ni ẹgbẹrun lọna aadọta Naira loṣooṣu.
Oṣu mẹta gbako si ni wọn o fi gba owo naa.
Yatọ si eyi, Ngelale tun sọ pe N155Bn ni ijọba ti ya sọtọ fun rira ati pipin ounjẹ kaakiri Naijiria, lati le koju ọwọ ounjẹ.
Bakan naa lo tun ṣalaye pe ijọba yoo ṣe oju ọna ọkọ lati ilu Badagry nipinlẹ Eko, lọ si sokoto.
Oju ọna naa ti yoo gba ipinlẹ meje kọja ni wọn ni yoo mu idagbasoke ba iṣẹ agbẹ, nitori pe awọn ipinlẹ to wa ni oju ọna naa, lo n pese ounjẹ ju ni Naijiria.
Bi eto naa yoo sẹ lọ
Ninu eto yii, biliọnu marun-un ni ipinlẹ kọọkan yoo gba, to fi mọ ilu Abuja.
Apapọ gbogbo owo naa si jẹ N555Bn fun oṣu mẹta.
Lara rẹ, N155Bn ni wọn o fi ra oriṣiriṣi ounjẹ ti wọn yoo pin fun awọn eeyan jakejado Naijiria.
Awọn nnkan mii ti wn o tun sé ninu eto naa ni:
Ijọba apapọ yoo fun ipinlẹ kọọkan ni biliọnu mẹwaa Naira lati ra awọn bọọsi to n lo afẹfẹ gaasi fun ẹdinwo irinajo f'ara ilu.
Aarẹ Tinubu tun buwọlu owo lati pari oju ọna reluwe Port Harcourt si Maiduguri - eyi to so ipinl Rivers, Abia, Enugu, Benue, Nasarawa, Plateau, Bauchi, Gombe, Yobe ati borno, papọ.
Ọna tabi amuyẹ ti ijọba yoo lo lati pin awọn nnkan amayedẹrun yii ko tii jẹ mimọ.
Amọ igba akọkọ kọ niyii ti iru igbesẹ iranlọwọ fun araalu n waye.
Lọdun 2023, ti ijọba kede pe oun yoo pin ẹgbẹrun mẹjọ Naira fun miliọnu mejila eeyan, akọsilẹ araalu to wa lọwọ ijọba ni wọn lo.
O si ṣeeṣe ko jẹ oun naa ni wọn o tun lo lasiko yii.
Ṣaaju ni ijọba ti gbe iru igbesẹ yii ninu oṣu Keji, ọdun 2024.
Awọn oniṣowo ni wọn pin owo naa fun, lati fi din inira ọrọ aje ku.
Laipẹ yii ni ijọba apapọ orileede Naijiria kede awọn ọna abayọ mẹta ti yoo mu adinku ba iṣoro ti awọn araalu n koju lasiko yii.
Lara awọn ọna abayọ akọkọ ni pinpin ounjẹ tirela nla ẹgbẹrun mejilelogoji (42,000tons) lati inu ile iko ounjẹ pamọ si ti ileeṣẹ to n ri sọrọ iṣẹ agbẹ ati ọgbin, eyi ti yoo mu igbe aye dẹrun fun araalu.
Lẹyin eyi ni ijọba tun sọ pe awọn yoo ba awọn ileeṣẹ to n ṣe irẹsi kaakiri Naijiria sọrọ lati sọ asọyepọ nipa pipese ẹgbẹrun lọna ọgọta tirela (60,000tons) irẹsi lati ta kaakiri orileede yii.
Igbesẹ ẹlẹẹkẹta ni lati bẹrẹ sii ko ounjẹ wọle si Naijiria lati ilẹ okeere, eyi ti yoo mu idẹrun ba igbayegbadun araalu.












