Mọ̀ nípa capsaicin, èròjà inú ata ródò, ṣọ̀mbọ̀, àtàwọn nǹkan tó máa ń fa sára

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oúnjẹ Ramen noodles ni wọ́n ti fòfin dè ní àwọn orílẹ̀ èdè kan ní ilẹ̀ Yúróòpù nítorí pé wọ́n ní àpọ̀jù “capsaicin” èròjà inú ata kan.
Láìpẹ́ yìí ni iléeṣẹ́ South Korea tó ń pèsè ramen noodles gba orí ayélujára nígbà tí iléeṣẹ́ tó ń rí sí ìpèsè oúnjẹ ní Denmark ní kí wọ́n kó àwọn oúnjẹ náà kúrò lọ́jà nítorí wọ́n kò dára fún àgọ́ ara.
Ìròyìn míì tó tún gba orí ayélujára ni ọmọdé kan tó ní ìpèníjà ìlera tó sì pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà lẹ́yìn tó kópa nínú ìdíje oúnjẹ aláta.
Capsaicin, tó jẹ́ èròjà tó máa ń mú ata ta, ni wọ́n ló fa ohun tó ń fa ìkọnilóminú yìí.
Èròjà capsaicin yìí wà nínú ata rodo, ṣọ̀mbọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ṣé lóòótọ́ ni jíjẹ àpọ̀jù capsaicin le ṣekúpa èèyàn?
Kí ni capsaicin?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Capsaicin jẹ́ èròjà inú ata, tó máa ń jẹ́ kí ata ta lẹ́nu tí a bá jẹ wọ́n. Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà capsaicinoids ni capsaicin jẹ́. Bí ẹ̀yà capsaicinoids ni wọ́n ti ṣàwárí rẹ̀ nínú ata àmọ́ èyí tó mú jùlọ ni capsaicin.
Àjọ tó ń rí sí ìpèsè oúnjẹ ní orílẹ̀ èdè United Kingdom kò fàyè gba àwọn ilé oúnjẹ láti máa fi capsaicin lásàn sínú oúnjẹ nítorí pé kò dára àmọ́ kò sí òdiwọ̀n sí iye tó lè wà nínú oúnjẹ nígbà tó bá jẹ́ pé látara ata ni ó ti ń jáde.
Kí ni àwọn nǹkan tí jíjẹ capsaicin le fà sára?
Denmark kọ́ ni orílẹ̀ èdè àkọ́kọ́ tí yóò ṣèkìlọ̀ lórí jíjẹ àpọ̀jù capsaicin, àjọ tó ń mójútó eewu ní Germany, BfR náà ti ṣèkìlọ̀ lórí jíjẹ capsaicin lápọjù.
Capsaicinoids máa ń fa àwọn ìnira kan tó sì máa ń jí ẹ̀yà ara tó wà fún gbígba ìnira TRPV sílẹ̀.
Ìwádìí fi hàn pé jíjẹ àpọ̀jù capsaicinoids le ṣokùnfà àyà dídùn, ìgbẹ́ gbuuru, ọkàn rínrìn, kí inú máa dun èèyàn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Bákan náà ló le mú èèyàn máa làágùn, òyì ojú àmọ́ kò ì tíì sí ìwádìí tó fìdí iye capsaicinoids pàtó tí èèyàn nílò láti jẹ kó tó bẹ̀rẹ̀ sí ní rí àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí.
Agbẹnusọ BfR ní nítorí bí ẹ̀yà ara èèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́ yàtọ̀, tó sì jẹ́ pé bí èèyàn ṣe lè gba ìrora yàtọ̀ síra jẹ́ kó ṣòro láti lè sọ pé iye capsaicinoids báyìí ló pọ̀ jù fún ẹni tó bá ní ìpèníjà ní àgọ́ ara láti jẹ.
“Ẹ̀wẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan tí ìwádìí ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀, ìwọ̀n mílígíráàmù 0.5 sí 1 capsaicinoids le fa ìrora kékeré bíi àyà títa àti kí inú máa dun èèyàn.
“Tí èèyàn bá jẹ tó ìwọ̀n mílígíráàmù 170 capsaicinoids le ní ipa tó lágbára, tó sì lè mú kí èèyàn di èrò ilé ìwòsàn. A ní èèyàn tó wà balẹ̀ sílé ìwòsàn lẹ́yìn tó jẹ capsaicinoids mílígíráàmù 600,” BfR sọ.
Àmọ́ jíjẹ capsaicin nìkan kò lè dá kó ìrora bá ara.
Ọ̀jọ̀gbọ́n ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìṣègùn òyìnbó ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì, Bond University, orílẹ̀ èdè Australia, Christian Moro ní capsaicin le fa ìrora láàárín ìgbà díẹ̀ àti pé tí díẹ̀ bá kó sí ojú èèyàn, ó lè fa ìnira fún ojú, tí èèyàn bá jẹ ẹ́, ó le fa ikọ́ fún ọjọ́ pípẹ́ tó sì lè fa “asthma”.
Ṣé àwọn àmì capsaicin léwu fún ìlera?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
BfR ní àpọ̀jù capsaicin le fa májèlé fáwọn ọmọdé àmọ́ iye tí wan lè jẹ tó máa fi jẹ́ májèlé yìí kò ì tíì di mímọ̀.
Àwọn ìwádìí kan ní capsaicin tó wà lára èèyàn ni iye rẹ̀ wà láàárin mílígíráàmù 500 sí 5000 àmọ́ kò sí ìwádìí tó ní àpọ̀jù capsaicin lára èèyàn gẹ́gẹ́ bí Moro ṣe sọ.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn oúnjẹ àti nǹkan mimu mìíràn, bí ara ṣe lè gba ta yàtọ̀ síra wọn, iye capsaicintí èèyàn kan le sọ pé ó ta púpọ̀ le má ta tó fún ẹlòmíràn.
Ó ṣeéṣe lati sọ pé jíjẹ capsaicin lápọ̀jù le má lè ṣekúpa èèyàn nítorí ó dìgbà tí èèyàn bá ti ń jẹ àpọ̀jù capsaicin ní fún ọ̀pọ̀ ìgbà dójú wí pé ó ń gbọ̀n, bì tàbí dákú ló tó lè di pé ó pa èèyàn.
Ẹni tí kìí bá sábà jẹ ata tàbí ọmọdé le ní ìrora tó bá jẹ́ àpọ̀jù capsaicin ju ẹni tó bá máa ń jẹ ata lọ.
Bákan náà ni ẹni tí ikùn rẹ̀ kò bá lè gba àpọ̀jù ata le ṣeéṣe kó ní ìrora tó bá ata tí capsaicin pọ̀ nínú rẹ̀ ju ẹni tí inú rẹ̀ bá gba ohunkóhun lọ.
Àwọn àǹfàní ìlera tó wà nínú ata
Láti igbá ayérayé ni wọ́n ti máa ń lo ata fún ètò ìlera kan tàbí òmíràn, bákan náà ni ìmọ̀ ìṣègùn ìgbàlódé náà ní ìwúlò tí wọ́n ń fi capsaicin fún.
Ata wà lára àwọn èròjà tí wọ́n máa ń lò láti fi pèsè àwọn ògùn kan, bíi ògùn ara ríro, ẹ̀fọ́rí àti psoriasis.
Capsaicin wà lára àwọn èròjà táwọn oní ìwádìí ní ó dára láti pèsè ìdènà jẹjẹrẹ inú.
Moro ṣàlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé capsaicin ní àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tirẹ̀ síbẹ̀ ó ní àwọn àǹfàní tí jíjẹ rẹ̀ máa ń mú bá ara tí èèyàn bá ń jẹ ẹ́ ní gbogbo ìgbà.
Ìwádìí ní jíjẹ capsaicin ní ìwọ̀túnwọ̀nsì le dènà àìsàn ẹ̀jẹ̀ rúru àti ara sísan lásanjù.
Bí ìgbàgbọ́ ṣe wà pé jíjẹ ata le fa ọgbẹ́ inú, ẹ̀rí wà pé capsaicin le wúlò láti dènà àti tọ́jú ọgbẹ́ inú.
Moro tún fi kun pé jíjẹ ata le mu àdínkù bá bí èèyàn yóò ṣe jẹ iyọ̀, tó sì dára ní jíjẹ ju iyọ̀ lọ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló ń kọminú lórí àwọn ìrora tí jíjẹ ata máa ń mú bá èèyàn bíi àyà títa, àwọn ẹ̀rí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó dára láti máa jẹ́ kí èròjà capsaicin wà nínú oúnjẹ tí èèyàn bá fẹ́ jẹ.














