Ògbóǹtagì adẹ́rìn-ínpòṣónú Mr Ibu wọ káà ilẹ̀ sùn lónìí

Oríṣun àwòrán, RealMrIbu/Instagram
Oni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹfa ọdun 2024 yii ni ilumọọka oṣere tiata nii, John Okafor tọ pọ eeyan mọ si Mr Ibu wọ kaa ilẹ sun.
Ilu Eziokwe Amuri, towa nijọba ibilẹ Nkanu nipinlẹ Enugu, ilu abinibi ọkunrin ọhun ni eto naa ti waye.
Sunday Okafor aburo oloogbe naa ṣalaye i pe, “ẹbi pinnu lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun akọni wọn to dagbere faye, lori bi iku rẹ ti fi apẹẹrẹ ifẹ, idunnu ati igbe aye to ni itumọ lelẹ fun mọlẹbi”.
Ọjọ keji oṣu kẹta ọdun 2024, ni iroyin iku oṣere naa jade, lẹyin ti aisan kan eyi ti ohun fun ra rẹ sapejuwe bi aisan abaadi ba a finra.
Alaye ree lori aisan to ṣe Mr ibu to fi jade laye
Ninu ọkan lara awọn fọnran to fi lede lori itakun ayelujara rẹ loṣu kewa ọdun 2023, ni oṣere to doloogbe naa ti n rawọ ẹbẹ si awọn ololufe rẹ lati maa fadura ran oun lọwọ.
Lori akete aisan naa ni oloogbe ọhun ti ṣalaye pe, “bi mo ṣe n baa yin sọrọ yi, mo wa ni ile iwosan, bẹẹ ni awọn dokita sọ pe ọna kan ṣoṣo to le ko mi yọ ni ki wọn ge ẹsẹ mi mejeeji kuro”.
Mr Ibu sọ fun awọn ololufẹ rẹ lati ba a ke pe Ọlorun, tori oun ko fẹ ki wọn ge ẹsẹ oun rara.
Bakan naa, ọmọbinrin to gbatọ, Jasmine Okafor, kesi awọn eeyan ilu ati awọn onile iṣẹ nla fun iranwọ lati lọ toju baba oun nilẹ okeere.
Jasmine sọ pe, “lati nkan bi ọsẹ meji ni baba mi ti dubulẹ aisan, a si gbe e lọ sile iwosan.”
O ni gbogbo ipa ni awọn ti sa lati ṣe itọju rẹ lati inu apo ara wọn, ṣugbọn ti eto ilera oloogbe naa ko gbe pẹẹli rara.


Jasmine fikun ọrọ rẹ pe, “ile iwosan aladani to lorukọ nilu Eko lawa, igbiyanju wa ni lati gbe e kuro nibe lọ si ibomii, nitori bi ko ti si ayipada fun nibẹ.
Oloogbe Okafor lo je wi pe, ikede to ṣe loṣu kẹwaa lojẹ igba keji ti yoo kede ailera rẹ faraye, lori bo ti ṣaaju ṣe bẹẹ lọsu kẹta ọdun 2022, to ti sọ pe majele ounjẹ n ba oun faa.
Ẹsẹ Mr. Ibu mejeeji di gige lẹyin iṣẹ abẹ meje ọtọọtọ to la kọja, nigbati ikede ailera rẹ pe oṣu kan.
Ọpọ awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria da owo jọ lati ṣeranwọ fun oṣere to doloogbe naa, ko lee fi sẹtọju ara rẹ.
Ṣugbọn oṣere naa pada jẹ ipe ẹlẹda rẹ lọjọ keji oṣu kẹta ọdun 2024.
Loṣu kẹwaa ọdun 1961, wọn bi Okafor, o jẹ oṣere tiata, adẹrinpoṣonu, adari ayẹyẹ, o jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Enugu, lapa gusu ila oorun ilẹ Naijiria.
Mr Ibu kopa ninu ọpọlọpọ sinima agbelewo nilẹ Najiria ati loke okun
Agbegbe Sapele ni oloogbe naa ti lo ibẹrẹ igbe aye rẹ, nibi to ti ṣiṣẹ lati ran ara rẹ lọsi ile ẹkọ ati lati seranwọ fun ẹbi rẹ.
Oṣere tiata to doloogbe naa, jẹ akọnimọọgba bọọlu afẹsẹgba, onija karate ati ẹṣẹ jija ko to bẹrẹ sini ṣere sinima.
Awọn eeyan ilu gba tiẹ nipa bo ti maa fi oju rẹ pa eeyan lẹrin.
Ijo ati awada ṣiṣe rọ ọ lọrun.
Mr. ibu ṣe igbeyawo nigba meji ọtọọtọ, bẹẹ ni Ọlọrun fi awọn ọmọ kẹẹ nipasẹ igbayawo mejeeji.















