Kí ló fà á tí àwọn ọmọ Nàìjíríà kan tó ti jápa ṣì fi ń gba owó oṣù lápò ìjọba orilẹ̀èdè Nàìjíríà?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iṣọwọ awọn oṣiṣẹ tẹle ri kan labẹ ijọba orilẹ ede Naijiria lo ṣi n gba owo oṣu lọwọ ijọba ilẹ yii, bo tilẹ jẹ pe wọn ti bẹrẹ iṣẹ miran nilẹ okeere ti wọn japa lọ.
Iroyin naa kan Aarẹ ilẹ Naijiria, Bola Tinubu lara, bẹẹ lo pe fun igbesẹ to nipọn tako iwa naa lẹyẹ ọ ṣọka.
Aarẹ Tinubu sọ pe, “gbogbo awọn oṣiṣẹ to n gbọna ẹburu gba owo oṣu lo gbọdọ da owo naa pada kia.”
Ọdun meji sẹyin ni Sabitu Adams (ki i ṣe ojulowo orukọ rẹ), ti tẹkọ leti lọ silẹ okeere, o kọwe fi iṣẹ silẹ nile iṣẹ ijọba ilẹ Naijiria to wa tẹlẹ, ṣugbọn to n gba owo oṣu rẹ lọ.
Orilẹ ede United Kingdom lo ti n ṣiṣẹ bayii gẹgẹ bi awakọ aje igboro.
Adams sọ fun BBC pe ẹru ko ba oun lati padanu owo oṣu naa, bẹẹ lo ni ihalẹ lasan ni ọrọ ti Aarẹ Tinubu sọ.
Adams, ẹni ọdun mẹrindinlogoji naa tun sọ pe, “ko nira ti mo ba padanu iye owo ti ijọba ilẹ Naijiria n san fun mi loṣoosu, toripe ilọpo ni mo n pa gẹgebi awakọ aje igboro lọwọ lọwọ.”
Ṣugbọn ki lo fa a ti ko fi kede ni gbangba pe oun kuro nile iṣẹ ijọba ilẹ Naijiria?
Adams sọ pe, “ni tooto,n ko fi iṣẹ silẹ rara, mo mọọmọ kuro ni bonkẹlẹ tori ki n le pada sibẹ lẹyin ọdun diẹ loke okun.”

Oríṣun àwòrán, AFP
Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ ?
Igbagbọ ọpọ awọn eeyan ilẹ Naijiria ko fi bẹẹ mulẹ lori ati rọwọmu nilẹ baba wọn, nipasẹ akude to ba owo Naira.
Asa wiwa iṣẹ lọ si ilẹ okeere wọpọ laarin awọn ọdọ ilẹ Naijiria, eyi ti adape rẹ n jẹ “Japa”.
Aarẹ Tinubu sọ pe, “O ya mi lẹnu nigba ti olori awọn oṣiṣẹ kede pe ọgọọrọ ọmọ ilẹ Naijiria to n ṣiṣẹ loke okun ko ti i kowe fiṣẹ silẹ nibi, wọn ṣi n gba owo oṣu lapo ijọba Naijiria.
Tinubu ni wọn gbọdọ da gbogbo owo naa pada, ki iwadii si waye nipa awọn to wa nidi bi owo ọhun ti rọrun fun wọn lati gba.
O ni ijiya to nipọn yoo ba awọn to wa nidii owokowo ti wọn n san jade naa.
Ohun to foju han ni pe o ṣee ki ibaṣepọ to danmọran wa laarin awọn oṣiṣẹ naa ati ọga wọn, eyi to faaye gba a lati kuro nibi iṣẹ lọ silẹ okeere lai kọwe fiṣẹ silẹ nilẹ yii.
Iru owo oṣu ọhun ni wọn n pin laarin oṣiṣẹ naa ati alabojuto ẹka to wa.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ọrọ awọn ayederu oṣiṣẹ jẹ iṣoro kan gboogi ti orilẹ ede Naijiria n koju, bo tilẹ jẹ pe wọn tako igbeṣe naa, ṣugbọn ti ko fi bẹẹ mule daadaa.
Auwal Yakasai to ti fẹyinti gẹgẹ bi alabojuto inawo nile iṣẹ eleto iroyin nipinlẹ Kano, sọ fun BBC pe oun ti gbọ iru nnkan bayii ri pẹlu boun ṣe ti lo ọdun mejilelọgbọn lẹnu iṣẹ ọba.
Ọgbẹni Yakasai sọ pe, “emi ko ti i ri eeyan kan gbamu lọrun ọwọ rara, ṣugbọn mo mọ daju pe asa gbigba owo oṣu lẹyin kikuro nibi iṣẹ wa daadaa.”















