‘’Ẹ wo bí aláboyún tó ń rọbí lọ́wọ́ ṣ̣e gun Ràkúnmí fún wákàtí méje láti dé iléèwòsàn’’

Aworan

Oríṣun àwòrán, SADAM ALOLOFY/UNFPA

Awọn obinrin to n gbe ni agbegbe Mahweet ni Yemen ti sọ iriri wọn nipa aisi ileewosan ni agbegbe wọn.

Awọn alaboyun to sọ iriri wọn ni awọn n rin irinajo fun wakati mẹrin si meje lati le de ileewosan kan soso to w ani agbegbe naa.

Ileewosan Bani Saad nikan ni ileewosan to wa ni agbegbe naa ti ẹgbẹgbẹrun obinrin si n lo nibẹ

Arabinrin Mona to sọ iriri rẹ ni pe ọna meji pere ni eniyan le gba lati de ileewosan naa, nipa irin ẹsẹ tabi lilo rakunmi.

‘’Mo tilẹ gbadura ki Eledua gba ẹmi mi amọ ko da ẹmi ọmọ mi si’’

Aworan

Oríṣun àwòrán, SADAM ALOLOFY/UNFPA

O ni nigba ti oun bẹrẹ si ni rọbi, oun ko ni ọna miran lati de ilewosan yatọ si ori rakunmi.

Mona to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogun naa ni o rin irin kilomita ogoji lati de ile iwosan naa, ti yoo gba wakati mẹrin lati de ileewosan naa.

Gbogbo bi rakunmi naa se n rin ni inira naa pọsi fun mi

‘’Nitori ọna ti ko dara naa, wakati meje ni a lo ni oju ọna lati de ileewosan naa.’’

‘’Mo tilẹ gba dura ki n ku amọ ki ọmọ inu mi ye, ki inira naa le dinku.’’

Bakan naa ni Mona ni oun ko lee sọ bi oun se de ileewosan amọ ayọ lo jẹ fun oun lati ri ọmọ tuntun jojolo naa gbe jo.

Oun ati ọkọ rẹ sọ orukọ ọmọ naa ni Jarrah, lati fi gboriyin fun dokita to doola ẹmi rẹ.

Iwadii fihan pe ọna tooro lo de ileewosan naa, ti ogun laarin orilẹede Saudi ati Iran si ti mu ki ọna naa di inira fun awọn alaboyun.

Awọn obinrin,mọlẹbi ati awọn ojulumọ lo n se iranwọ fun awọn alaboyun naa lati de ileewosan.

Bẹẹ si ni dokita wọn ti gba wọn ni iyanju lati mase gbiyanju lati gbẹbi ara wọn ninu ile nitori o le wu pupọ ti ọpọlọpọ obinrin si ti gba ibẹ di ero orun.