MSME free business registration: Oníṣẹ́ alàdáni, ẹ wo ọ̀nà láti jẹ ànfàní ìforúkọsílẹ ọ̀fẹ́ tí ìjọba gbékalẹ̀

Aworan ọdọ to mu fọọmu lọwọ

Oríṣun àwòrán, MSMES SURVIVAL FUND/TWITTER

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu anfani iforukọsilẹ ọfẹ fawọn to ba fẹ forukọ ileeṣẹ wọn silẹ pẹlu ileeṣẹ to n fontẹ lu orukọ ileeṣẹ ni Naijiria,CAC.

Bẹrẹ lati ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹwa ni anfani yi yoo fi ṣi silẹ fawọn onileeṣẹ kekeeke ati alabọde(Meduim Small and Micro Entrepreneurs (MSME) to to ẹgbẹrun lọna ojilenigba le mewaa (250,000).

Igbesẹ yi jẹ ọna kan gboogi ti ijọba lawọn fẹ fi ran onileeṣẹ kekeeke lati fidi ileeṣẹ wọn mulẹ lẹyin Covid-19.

Àkọlé fídíò, Kété tí wọ́n bá ti báa yín sùn tàn torí pé ẹ tóbi, ẹ gbà pé ìfẹ́ yẹn ti parí - Auntie Remi Ọlọ́yàn ńlá

Oluranlọwọ aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin ori ayelujara, Bashir Ahmad lo fi ọrọ yi soju opo Twitter.

O ni ajọ CAC yoo forukọ ileeṣẹ ẹgbẹrun mẹfa le ni ẹgbẹta lawọn ipinlẹ mẹrinlelọgbọn ni Naijiria.

Amọ ṣa ẹgbẹrun meje ati ẹẹdẹgbaarun le ni mẹfa (7,906) ni yoo jẹ anfaani yi ni Abuja.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ni Abuja ẹgbẹrun mẹsan o le ni mẹrinlelọgọrin,9,084 nigba ti Kano yoo si ni aaye fun ẹgbẹrun mẹjọ le ni irinwo eeyan (8400).

Bi o ṣe le forukọ silẹ jẹ ninu anfaani yi

Iforukọsilẹ ọfẹ yi yoo bẹrẹ lati ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹwa ọdun 2020.

Ohun to yẹ ko ṣe ree:

Àkọlé fídíò, Àjẹ́ ké lánàá, ọmọ kú lónìí ni ọ̀rọ̀ Tinubu àti ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Tollgate - Bode George