Falz: Èmi kò ní sàtúnse fídíò tó sọ àsìse Nàíjíríà náà
Adarí àjọ ti ó ń rí sí ẹ̀tọ́ àwọn Musulumi (MURIC), Ọ̀jọ̀gbọn Ishaq Akintola, ti ṣalayé yéké-yéké nípa ohun tí ó fa gbèdéke ọjọ́ méje, ti àjọ́ náà fun olórin taka-sufe ọmọ Naijiria ni, Folarin Falana, tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Falz, lórí fìdíò rẹ̀, ‘This is Nigeria’, tí gbogbó ọmọ Naijíria ń sọ̀rọ̀ nipa.
Falz ti ní òun kò ní yọ fídíò orin náà tí ó fi gbogbo àléébù orílẹ̀èdè Naijiria han láfẹ́fẹ́.
Lẹ́yìn tí orin náà tí àwọn ènìyàn ti ń gbórín yìn fún jáde, ni MURIC bẹ́nu àtẹ́ lùú látàrí wípé, fídíò náà ṣàfihàn àwọn ọmọbinrin tí wọn ń jó orin Shaku-Shaku pẹlu hijab.

Oríṣun àwòrán, Falz/Youtube
Nígbà tí BBC kàn sí Falz, agbénusọ rẹ̀, Fẹ́misọ́rọ̀ Ajayi, ní wọ́n kàn ń pariwo olórin náà fún nkan tí ko kan ni, nítorí ó fi orin náà jíṣẹ́ ni o.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, MURIC ní, Falz gbọ́dọ̀ yọ orin náà láfẹ́fẹ́ nítórí ó lè dá ìjà sílẹ̀ ati pé èèbú ni orin náà jẹ́ fún àwọn ẹlẹ́sìn Islam.
Ajọ náà ní tí Falz bá kọ̀, wọn yóò gbe lọ ilé ẹjọ́.