Níbo ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Chibok 96 tó kú wà lẹ́yìn ọdún mẹ́sàn-án?

Aworan Awọn ọmọbirin Chibok

Oríṣun àwòrán, Chibok Girls

O ti pe ọdun mẹsan loni ti ikọ Boko Haram ji awọn akẹkọọbinrin ile-ẹkọ ni Chibok, nipinlẹ Borno gbe lọ.

Bi agbaye ti n ṣe ayẹyẹ ọdun kẹsan-an ọdun ti wọn ji awọn ọmọbinrin Chibok naa gbe lọ, akẹkọọ mẹrindinlọgọrun-un (96) ninu ọrinlerugba o din mẹrin ( 276) ni wọn ko ri pada.

Oṣu Kẹrin Ọjọ kẹrinla ọdun 2014 ni awọn onijagidijagan Boko Haram ji awọn ọmọbirin naa gbe kuro ninu ile ẹkọ Government Girls Secondary School, Chibok, ti wọn si ko wọn sinu ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn gbe wa lọ sinu igbo Sambisa

Awọn ọmọbinrin mẹtadinlọgọta ni asiko naa ṣa asala nigba ti wọn fo jade ninu awọn ọkọ to n gbe wọn lọ.

Awọn to ṣeku ti wọn gbe lọ si inu igbo Sambisa ni awọn alakatakiti Boko Haram fi tipa tipa gbe wọn ni yawo,Awọn ọmọbirin ti pupọ ninu wọn jẹ Kristiani ni wọn fi agbara sọdi ẹlẹsin Islam.

Ijinigbe yii lọ jẹ iwa ijinigbe ẹgbẹ alakatakiti Boko Haram ti awọn oniroyin polongo julọ to mu ẹgbẹ alakatakiti naa di ohun ti agbaye sọrọ rẹ julọ.

Olori ikọ alakatakiti ọhun Abubakar Shekau lo filede wí pe ikọ Boko Haram lowa nidi iṣẹlẹ ijinigbe Chibok,lati gba ẹsan bí ijọba apapọ orilẹ-ede Naijiria ti fi awọn ọmọ ẹgbẹ naa si atimọle.

Awọn ọmọbirin Chibok ọhun ti ọpọ ninu wọn jẹ ọmọ to wa labẹ ọdun mejidinlogun ni wọn fẹ fun awọn jagunjagun alakatakiti Boko Haram tipatipa.

Aworan awọn ọmọbirin Chibok

Oríṣun àwòrán, chibok Girls

Ẹgbẹ alakatakiti ọhun ni o ti bẹrẹ lọdun mejila ṣaaju ki isẹlẹ ijinigbe Chibok to waye,Muhammed Yusuf ni o da ẹgbẹ ọhun silẹ. Ọdun 2003 ni iṣẹlẹ akọlu akọkọ ẹgbẹ naa,nigba ti wọn ṣe ikọlu si awọn ile iṣe ọlọpa ti wọn si tun ji ibon wọn lọ. Ẹgbẹ Boko Haram ni o tunmo si gbi gbogun ti iwe kika,ẹṣin Kristẹni ati oun to nisẹ pẹlu aṣa ile okeere. Lẹyin ti oludari ẹgbẹ naa bọ sì pampẹ awọn ọmọ ologun orilẹ-ede yii ni 2009 ti wọn si tun ṣeku paa,iṣẹlẹ naa lo mú ikọ alakatakiti ọhun gboro si. Laarin ọdun 2014 si 2015 ọpọlọpọ ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Borno,Yobe àti Adamawa lọ ti wa ni isakoso ẹgbẹ Boko Haram.

̀Iṣẹlẹ ijinigbe awọn akẹkọọ Chibok lọ di oun ti gbogbo agbaye sọ dorin wí pe "ẹda awọn ọmọbirin wa pada", eyi ti iyawo aarẹ Amẹrika Michelle Obama na sọrọ lori ee. Aarẹ Muhammadu Buhari lọdun 2015 ṣeleri lati ri wí pe awọn ọmọbirin Chibok pada silẹ wọn,ṣugbọn pẹlu ilakaka rẹ, awọn ọmọ ologun orilẹ-ede yii gba gbogbo awọn agbegbe to wa labẹ iṣakoso ẹgbẹ alakatakiti Boko Haram pada. Ọdun 2016 ni ọkan lara awọn ọmọbirin Chibok sa asala ti wọn si ri ninu Igbo kan pẹlu ọmọ lọwọ. O ni ọpọlọpọ ninu awọn ọmọbirin Chibok ni o si wa ni akata awọn alakatakiti ọhun,eyi lo mu ki ọpọ eeyan gbagbọ wí pe oseṣee ki awọn ọmọbirin Chibok pada silẹ layo. Bí gbogbo agbaye ti n ṣe iranti ọdun kẹsan-an iṣẹlẹ ijinigbe Chibok, ireti awọn riri awọn ọmọbirin Chibok to ṣi wa ni aha ẹgbẹ alakatakiti Boko Haram ni o ti n roko igbagbe.

Malam Hamza ọkan lara awọn to n pe fun itusilẹ awọn ọmọbirin Chibok ni, "ọpọlọpọ ninu awọn ọmọbirin yii ni wọn ti gbe lọ si agbegbe Odo Chad, ti ọpọ si tun ti bí ọmọ mẹta si mẹrin fawọn alakatakiti ọhun,eyi lo jẹ ko sọrọ fun wọn lati gba ominira". Hamza ni," o seṣee ki ọpọ wọn ti padanu ẹmi wọn nigba ti awọn akatakiti àti awọn ọmọ ẹgbẹ ologun orilẹ-ede gbena woju ara wọn". O ni o se ni laanu wi pe ijọba ko kọbi ara si bi awọn ọmọbirin Chibok to ṣeku yo ṣe ri ominira pada.