EFCC uncovers Diezani's loot: Wo iye owó gbọbọi tí EFCC tún ní Diezani jí kó

Oríṣun àwòrán, WOLE EMMANUEL
Ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ni Naijiria, EFCC tun ti tu aṣiri mii sita nipa awọn owo ati nkan ini ti minisita fun ọrọ epo rọbi nigba kan ri, Diezani Allison-Madueke ko pamọ nigba aye rẹ.
Eyi ti wọn ṣẹṣẹ tun gbe jade yii ni wọn ni wọn ri ninu asuwọn owo rẹ ni ile ifowopamọ Fidelity.
Ni bayii, Ọlọpaa ti fi ofin mu oludari agba kan tẹlẹri ni ile ifowopamọ ọhun, Nnamdi Okonkwo lori ẹsun naa.
Bakan naa, Okonkwo to jẹ alaga ile ifowopamọ First Bank Holding atawọn ti ọrọ yii ta ba ti foju wina ofin lori iye owo $153million ati $115million.
Nigba to jẹ pe ajọ EFCC lo ri $153 million gba pada, ẹsun eyi to ni ṣe pẹlu $115million to kan ajọ eleto idibo, INEC lori ọrọ gbigba abẹtẹlẹ naa ti wa niwaju oniruuru ile ẹjọ bayii.
Lọwọlọwọ, Okonkwo ati Charles Onyedibe ti wa ni ahamọ ajọ EFCC lori ibi ti iye owo $72.8m rá sí.















