Agbègbè méjì dojú ogun kọra wọn, ẹ̀mí bọ́, ọ̀pọ̀ dúkìá ṣòfò, ìjọba kéde òfin kónílé-gbélé

Oríṣun àwòrán, ANADOLU AJANSI
Ijọba ipinlẹ Adamawa ti kede ofin konile-gbele oniwakati mẹrinlelogun (24 hours) bayii nijọba ibilẹ Lamurde, latari ikọlu tuntun to tun ṣẹṣẹ ṣẹlẹ lagbegbe naa.
Tẹ o ba gbagbe, ṣaaju ni ikọlu to jọ mọ ẹlẹyamẹya ti n waye lawọn agbegbe naa, to si fa rogbodiyan to pọ.
Ikọlu eyi to ṣẹṣẹ waye lọjọ Aiku yii, ṣẹlẹ lai ti pe ọsẹ kan ti Gomina ipinlẹ Adamawa, Umaru Fintiri, ṣepade aabo pẹlu awọn olori agbegbe ibi ti wọn ti n ba ara wọn ja naa.
Ilu Bachama ni ikọlu tuntun yii ti waye bayii, awọn eeyan ilu Chobo ti wọn jọ mule ti ara wọn ni wọn si ni o kọlu wọn.
Ṣaaju ni awọn agbegbe mejeeji yii ti kọlu ara wọn ni nnkan bii oṣu diẹ sẹyin, nigba naa ni wọn dana sun ile pẹlu ọpọlọpọ dukia.
Eyi lo mu Gomina Fintiri ṣabẹwo si awọn ilu naa nigba naa, to si rọ wọn lati yee ṣigun sira wọn.
Ìkọlù tuntun wáyé lọ́jọ́ Àìkú, wọ́n dijamọra bii ẹni n jagun
Gẹgẹ bi awọn eeyan agbegbe ti ikọlu yii ti waye ṣe wi, ọjọ Aiku, ọjọ keje, oṣu Kejila ọdun 2025 ni wọn tun da oju ija kọ ara wọn lẹẹkan si i.
Awọn eeyan to dihamọra ogun pupọ ni a gbọ pe wọn yabo awọn agbegbe bii Waduku, Rigange, Tingo atawọn miran to mule ti wọn.
Awọn o ṣoju mi koro sọ pe idihamọra ogun awọn to gbe ija wa naa le pupọ.
Wọn ni awọn nnkan ogun igbalode to ju ti awọn ṣọja to wa niluu naa lati pẹtu si aawọ lọ ni wọn gbe wa.
Wọn fi kun un pe ọpọ araalu lo bẹrẹ si i wa aabo funra wọn lasiko ti iro ibọn n dun lakọlako naa.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ, Adamawa, Morris Dankwambo, sọ pe oun ti ko awọn ikọ alaabo lọ si awọn agbegbe naa lati mu alaafia pada.
O rọ awọn araalu lati gba alaafia laaye, ki wọn si yago fun awọn ohun to ba tun le da rogbodiyan silẹ.














