Wo bí o ṣe lè gba nọ́mbà ìdánimọ̀ owó orí, TIN rẹ láì dàmú jìnnà
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Nọmba idanimọ fun owo ori, TIN jẹ numba idanimọ fun amojuto eto sisan owo ori labẹ ofin owo ori tuntun ti ijọba Naijiria bẹrẹ lọjọ kinni oṣu kinni ọdun 2026.
Ọpọ eeyan ni ọrọ nọmba yii ko ye, paapaa bijọba ṣe tun sọ pe o le ṣoro fun ẹni ti ko ba ni in lati le lo apo ikowosi rẹ, bẹrẹ lati ọjọ akọkọ ninu oṣu Kin-ni-ni ọdun 2026.
Gẹgẹ bi alaye ti ajọ Nigerian Revenue Service (NRS) ati Joint Revenue Board (JRB) ṣe lati yanna-na ọrọ owo ori yii, ohun ti a mọ si Tax ID tabi idanimọ owo ori sisan, jẹ ohun kan ti awọn ajọ mejeeji yii n bojuto.
Ajọ mejeeji naa lo si n ṣe ọna bi eeyan yoo ṣe ni nọmba idanimọ owo ori.
Alaye bi o ṣe le ri nọmba naa gba wa ninu fidio oke yii.
- Òfin owó orí tuntun bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Kínní ọdún 2026, èyí ni bí o ṣe lè gba nọ́mbà ìdánimọ̀ owó orí (Tax ID)
- Àlàyé rèé lórí bí nọ́mbà NIN àti ìwé ẹ̀rí CAC ṣe le rọ́pò nọmbà owó orí rẹ lọ́dún tuntun
- Èyí ni owó orí 50 tí ìjọba Tinubu ní kí aráàlú má san mọ́ láti ọdún 2026.
- Wo ìdí tí Tinubu fi buwọ́lu àfikún15% owó orí epo bẹntiroolu àti disu











