Òfin owó orí tuntun bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Kínní ọdún 2026, èyí ni bí o ṣe lè gba nọ́mbà ìdánimọ̀ owó orí (Tax ID)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ohun kan to n ru ọpọ eeyan loju latigba ti ijọba apapọ ti n kede rẹ lorilẹede Naijiria yii ni ọrọ nipa nọmba owo ori tuntun, ati nọmba idanimọ owo ori ti a mọ si 'Tax Identification "
Ọpọ eeyan ni ọrọ nọmba yii ko ye, paapaa bijọba ṣe tun sọ pe o le ṣoro fun ẹni ti ko ba ni in lati le lo apo ikowosi rẹ, bẹrẹ lati ọjọ akọkọ ninu oṣu Kin-ni-ni ọdun 2026.
Bawọn kan ṣe n sọ pe NIN naa ni Tax ID, ni awọn miran n sọ pe wọn ko jọra wọn.
Awọn kan sọ pe ajọ to n ri si pipawo wọle labẹnu (FIRS), ti sọ pe NIN le siṣẹ ti Tax ID yoo ṣe, bẹẹ ni awọn kan ni ko ri bẹẹ.
Bẹẹ loju mọ to mọ lonii, owo ori sisan kan alakọwe, o kan olokoowo nla ati awọn oniṣẹ adani ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ṣugbọn ewo lewo gan-an ninu awọn ọrọ yii, bi ọjọ ti ijọba da ṣe ti wọle de wẹrẹ.
Alaye ajọ Nigerian Revenue Service (NRS) ati Joint Revenue Board (JRB)
Gẹgẹ bi alaye ti ajọ Nigerian Revenue Service (NRS) ati Joint Revenue Board (JRB) ṣe lati yanna-na ọrọ owo ori yii, ohun ti a mọ si Tax ID tabi idanimọ owo ori sisan, jẹ ohun kan ti awọn ajọ mejeeji yii n bojuto.
Ajọ mejeeji naa lo si n ṣe ọna bi eeyan yoo ṣe ni nọmba idanimọ owo ori.
Wọn ṣalaye pe bi eeyan ba ti ri nọmba idanimọ owo ori yii gba, nọmba yii kan naa ni yoo maa lo lọdọ ijọba apapọ, ipinlẹ ati ibilẹ.
NRS ati JRB ṣalaye pe eeyan ko nilo lati ṣe ẹda nọmba yii nigbakugba to ba fẹ lo o fun nnkan ijọba.
To ba jẹ pe ẹnikan ṣoṣo ni, nọmba idanimọ orilẹede ti a mọ si National Identification Number (NIN), ni wọn yoo maa lo lati gba Tax ID.
Fun okoowo ati ileeṣẹ, nọmba idanimọ owo ori tiwọn ni wọn ti so pọ mọ eyi ti wọn gba lasiko ti wọn fi orukọ ileeṣẹ tabi okoowo naa silẹ, eyi ti a mọ si CAC.
Ẹni to ba ti wa ni NIN tabi nọmba CAC, eyi ni wọn yoo lo lati gba nọmba idanimọ owo ori ti I ṣe Tax ID.
Oju opo wo ni eeyan yoo ti ri nọmba owo ori naa gba?
Lati gba nọmba owo ori sisan rẹ ti a mọ si Tax ID, oju opo ti ajọ NRS ati JRB ni ki eeyan lọ lori ayelujara ni: taxid.nrs.gov.ng.
Ati taxid.jrb.gov.ng.














